Boko Haram: Ilé iṣẹ́ ọmọogun kò sọ fún mi pé ọkọ mi kú fún ọdún kan- Iyawo soja

Obinrin to sunkun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Boko Haram:Ilé iṣẹ́ ọmọogun kò sọ fún mi pé ọkọmi kú fún ọdún kan- Iyawo soja

Ilé àwọn Abdulaziz Musa to jẹ ọmọogun orilẹ̀ede Naijíríà ro pẹlu ọfọ ní àisùn ọdún tuntun ti gbogbo ènìyàn n dúnnu láti wọ ọdun 2020 ní ilu Ilorin.

Ní ọjọ́ yìí gan ni ilé iṣẹ́ ọmọogun Naijiria lọ túfọ fún ẹbí Abdulaziz ẹni ọdun márundinlogojì ti àwọn ọmọ ikọ̀ Boko Haram pa ní ìpínlẹ̀ Borno.

Ìròyìn sọ pé Musa to ni Nọmba idanimọ ọmọogun 14NA/71/1222 wà ni ẹ̀ka ìpèsè àti ìrìnà fún ilé iṣẹ́ ọmọogun Naijiria.

Sááju ni ìròyìn ti sọ pé àwọn ẹbi ko tii ri Musa bá sọ̀rọ̀ láti inú oṣù kejìlá ọdun 2018, eyi ti o sì ti da ìyàwó àti ọmọ ọdun mẹrin ti wọ́n ni láàmú.

Ikọlù to ṣẹ̀lẹ̀ si àwọn soja ni Metele ninu oṣù kọkànlá ọdún 2018 níbi ti ọ̀pọ̀ sójà ti padánù ẹ̀mi wọ́n tun mu ki ẹbi rẹ má ni ìfọ̀kànbalẹ̀, síbẹ̀ ilé iṣẹ́ ọmọogun ko bùn ẹbi gbọ́.

Ilé iṣẹ́ ọmọogun ni irọ́ ni pé ọmọogun to to ọgọ́run kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé ènìyàn mẹ́tàlélógun péré lo bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rin.

Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun ilé iṣẹ́ ọmọogun Naijiria Tukur Buratai fi àtẹjáde kan sita ti ọmọogun Sani Usman si buwọlù ú pé sójà mejila ku ni Kukawa, Ngshe, Kareto àti Gajiram ti gbogbo rẹ̀ wà ni ìpínlẹ̀ Borno nigbati àwọn ọmọogun ko sọ́wọ́ Boko Haram ọjọ keji si ọjọ kẹtàdinlogun oṣù kọkanlá ọdun 2018.

Iyàwo Musa Sherifat ni ọjọ́ keji ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáye ni òun pé láti bèrè lọ́wọ́ ọkọ òun pe ṣe àláfia lo wà, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbìyànju òun pàbó ló jásí.

O ní kóda àwọn ẹbi tun ránṣẹ́ si àwọn ọgálọ́ga soja, wọ́n si sọ fún àwọn pé aláfíà lo wà.

O ní inú oṣù kejila ọdun 2018 ni òun ba ọkọ òun sọ̀rọ̀ kéyin. Ní ọ̀pọ ìgbà orí àtẹjisẹ́ WhatsApp ni òun ti maa ba a sọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n láti ìgbà náà òun kò lé ba a sọ̀rọ̀ mọ. O ní àwọn pe àwọn ọ̀gá rẹ̀ síbẹ̀ wọ́n ni kò sí wàhálà kankan, pe ti wàhálà ba wà àwọn yóò ti jẹ ki ẹbi mọ ti wọ́n yóò si ti kàn si wọ́n láti Abuja.

" Ọjọ kọkanlélọ́gbọ̀n oṣù kejila ọdún 2019 ni wọ́n kàn si àburo rẹ̀ to jẹ orukọ to fi sílẹ̀ pé òun ló súnmọ òun jù (Next of Kin) pe ó ti kú, wi pe o kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ to wáye nínú oṣù kọkànlá ọdun 2018."

Musa to jẹ́ ọmọ ilọrin ni ìpínlẹ̀ Kwara wọ iṣẹ́ ọmọogun Naijiria lọdun 2014 lẹ́yin ọdun kan to gbé ìyàwó ti ìyàwó si ti wà nínú oyun lásìkò to lọ fun ìgbáradi.

Agẹnusọ ọmọogun Naijiria ti ikọ iroyin kan si Sagir Musa seleri pe oun yóo fesi lẹyin atẹjisẹ pe ki o sọ iha àwọn ọmọ ogun sùgbọn ko tii fèsì di àsìkò yìí.