Sọ́jà méje wọ gàù lórí ẹ̀sùn olè jíjà ní ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Google
Ile iṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti fi panpẹ ọba mu awọn afurasi ole to to mejidinlaadọrun, eleyii ti sọja meje wa ninu wọn.
Adari ile isẹ to n gbogun ti iwa ọdaran ni ipinlẹ Eko, Kọmisọnna Zubairu Muazu sọ wi pe ile isẹ naa ri awọn ọdaran yii mu laarun osu diẹ sẹyin.
Muazu ni awọn soja meje naa ti orukọ wọn ati ọjọ ori wọn jẹ;Ndidi Oluchukwu, 30; Owolabi Adeyemo ,42; David Olufemi, 47; Iseyin Samuel Isreal, 41; Emeka Ibeh, 29, Samuel Anochime, 36, ati Ebedot Stephen, 27 ni wọn mu fun ole jija ati fifipa gba ọkọ ayokẹlẹ lọwọ awọn eniyan.
Ninu wọn ni awọn ẹlẹgbẹ okunkun nipinlẹ Eko, ti wọn si dupẹ lọwọ awọn ara agbeegbe naa to ta wọn lolobo nipa awọn asemase to n waye ni agbeegbe naa.
Ọga ọlọpaa naa wa parọwa si awọn ara ilu lati tunbọ ma a ran wọn lọwọ si, nitori awọn ile isẹ eto aabo lorilẹede Naijiria n sisẹ takuntakun lati ri wi pe aabo to daju ati eyi to peye wa ni ipinlẹ Eko lasiko ọdun Keresi ati ọdun tuntun to n kanlẹkun.









