Oba Oniru: Léyìn ayẹyẹ ọjọ ibí ọdún méjìlélọgọrìn Ọba Oniru jade láyé

Oríṣun àwòrán, @others
Erin wo! ajanaku sun bi oke.....Oba Oniru re ibi agba n re.
Oba Idowu Abiodun Oniru ti Iru ni ipinlẹ Eko ni guusu Naijiria lo ti dagbere fun aye pe o digboṣe.
Ipinlẹ Eko ni Oba Oniru ku si lẹyin aisan ranpẹ lọmọ ọdun mejilelọgọrin.
- Àkójọpọ̀ àwòrán láti ibi igbẹ́jọ́ Omoyele Sowore l'Abuja
- Kíni Prince Harry, Meghan aya rẹ́ àti ọmọ wá ṣé ní Áfríkà?
- Òní lòní ń jẹ́ fún Omoyele Sowore láti fojú bá Ilé ẹjọ́ gíga
- Messi fi Ronaldo, Van Dijk ṣe àkàsọ̀ dé ògo agbábọ́ọ̀lù tó pegedé jùlọ lágbayé
- Ẹ wo ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ nípa gbajúgbajà òṣèré tíátà Yoruba Tóyìn Afọlayan
Wo igbesi aye Oba Idowu Abiodun Oniru:
A bi Abiodun Oniru ni ọjọ Kẹfa, oṣu kẹsan an, ọdun 1937.
Oun ni ikejila ninu ọmọ mẹẹdogun ti Oba Yesufu Oniru bi.
Oba Yesufu Oniru to ku lọmọ ọgọfa ọdun, iyẹn lọdun 1984 ni baba Oba Idowu Oniru, eyi fihan pe ile alade ni a bii si lọdun 1937.
Oba Idowu Oniru lọ sile iwe alakọbẹrẹ ti St. David ati Ararọmi Baptist.
O lọ sile iwe girama ti Eko Boys High School ni Lagos Island nipinlẹ Eko ni guusu Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @others
Ojọ kẹfa, oṣu kẹsan an ọdun yii ni Oba Oniru sami ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ laimọ pe ọlọjọ ti n kan ilẹkun.
Lọdun 1965 ni Oba Idowu Abiodun Oniru kuro ni Naijiria lọ ka ẹkọ nipa imọ ẹrọ ikọle ati ọna ni British Institute of Engineering Technology ni Slough ni ilu Oba.
Lọdun 1968 lo pada wa sile wa darapọ mọ okowo baba rẹ, Oba Yesufu Oniru.
Awọn aya Oba, ọmọ, ọmọ ọmọ, atawọn ẹbi, ara ati ojulumọ ni wọn n ṣe ilede lẹyin Oba.
Lọdun 1995 ni Oba Idowu Oniru gori apere awọn baba nla rẹ ni ipinlẹ Eko.
Lẹyin ọpọlọpọ igbẹjọ nile ẹjọ pẹlu awọn ile ọla to ku ti wọn jọ n du oye.
Lasiko ijọba Oba Idowu Oniru ni adugbo aladagbe Oniru di ilumọọka nipinlẹ Eko ati ni agbegbe rẹ gẹgẹ bii ibudokowo nla fun iṣẹ ati ile gbigbe.
Awọn eniyan n ṣe idaro Erin to goke alọ:
Ijọba ati gbogbo ọmọ ìpínlẹ Eko ló ń ṣe ìdárò Ọba Onirù- Sanwo Olu
Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo Olu ti kẹduin lori Oba Oniru ti Iru, Oba Idowu Oniru ti o waja ni ọjọ Aje.

Oríṣun àwòrán, @others
O ni ariṣe ni arika nitori iṣẹ rere ti Oba Oniru ṣe yoo maa fọhun lẹyin ipapoda rẹ.
Oniru ni o ṣe ayẹyẹ ọdun mejilelọgọrin ti wọn bi saye ni ọsẹ meji sẹyin, sugbọn leyin aisan ranpẹ o jade laye.
Ọba Ìdòwú Abiọdun Onírù, Oniru ti Iru nipinlẹ Eko wàjà, ẹbí, araá àti iyèkan n sọ nípa ohun rere tó gbé ilé ayé ṣe.
Diẹ lara awọn ọmọ Alayeluwa yii ni Adesẹgun Oniru to ti fi igba kan jẹ Kọmiṣọnna fun eto amojuto Omi ati Idagbasoke ni ipinlẹ Eko, Tolu Demuren (Toolz) to jẹ sọrọsọrọ atawọn ekan miran.
Dokita Adebule Oluranti Idiat to jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Eko tẹle naa ṣapejuwe Oba yii pe agba to fẹran alaafia nile Eko ni.
Waziri ti ile tapa ni Nupe, Isa Mohamed naa gbadura pe ki Olorun tu awọn ẹbi Alayeluwa ninu lasiko to n ba wọn kẹdun.
Omo ọba binrin Adu Rasheedat Abiodun to jẹ alaga ijọba ibilẹ Victori Island to da duro naa mẹnuba awọn idagbasoke to ba ilẹ̀ Iru lasiko ti Oba yii n jọba.
Aṣa Yoruba ko faaye silẹ ki wọn kan deede kede iku Oba ati awọn oloye pataki.
Ọpọ nkan lo ti maa ṣẹlẹ ti wọn gbọdọ kọkọ gbe awọn igbese kan ṣaaju ikede Oba to waja.













