Osun Kidnapping: Àwọn afunrasí darandaran jí èèyàn mẹ́rìnlá gbé nńú bọ́ọ̀sì Osogbo sí Abuja

Oríṣun àwòrán, @osun247
Awọn eeyan kan ti wọn funra si pe wọn jẹ darandaran ti ji eeyan mẹrinla gbe ni agbegbe Ọtan Ayegbaju ni ipinlẹ Ọṣun
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe lati ilu Oṣogbo ni akero to ko awọn eeyan naa ti gbera.
O si dori kọ ilu Abuja ki awọn ajinigbe pawo naa to ṣe ọṣẹ wọn ni ikorita Ajeoku ni opopona Otan-ile si Okemesi.
Awọn oniṣẹ ibi naa ni a gbọ wi pe wọn ba awọn ero wọ ọkọ gẹgẹ ero to n lọ si ilu Abuja lati ilu Oṣogbo ki wọn to ṣe ọṣẹ wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko tii si ẹni to lee sọ ni pato boya darandaran Fulani lawọn to ṣe iṣẹ buruku naa abi ẹya miran.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, Fọlaṣade Odoro ṣalaye fun BBC News Youba pe wọn ti doola eeyan mẹrin ninu awọn ti wọn ji gbe naa.









