Ghana: Ìbọn ìléwọ́ mẹ́fà àti àdó olóró àtọwọ́dá méjìlélógún ni wọ́n ká mọ́ wọn lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ orilẹ-ede Ghana ti fi ṣikun ọba mu awọn afurasi mẹta ti wọn fẹsun kan pe wọn n gbimọ lati ditẹ gba ijọba lọwọ aarẹ orilẹ-ede naa.
Ninu atẹjade ti ijọba ilẹ naa fi lede loju opo Twitter rẹ lo ti sọ pe, ọtẹ ọhun ni awọn eeyan naa fẹ fi da orilẹ-ede Ghana ru.
Ijọba naa ni awọn ọmọ ologun kan kopa ninu iṣẹlẹ naa, ni bi wọn ṣe pese ohun ija fun awọn afurasi ọhun.
Awọn ẹni yii n gbe igbvesẹ kọni lati gba ijọba mọ Nana Akufo-Addo lọwọ ni Ghana.
Gẹgẹ bi ọrọ ti ijọba sọ, awọn afurasi naa ni afojusun lati ko awọn ọdọ mọra, lọna lati mu ki wọn darapọ mọ ọtẹ ọhun.
Odindin oṣu mẹẹdogun ni awọn oṣiṣẹ eleto aabo ni Ghana fi fọwọsowọpọ ṣiṣẹ ti wọn fi ri awọn eniyan yii mu.

Oríṣun àwòrán, @Amhere
Lẹyin ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ ti bẹrẹ iwadii awọn eeyan naa fun oṣu marundinlogun ni fi wọn ṣawari ibi ti wọn n ko ohun ija si.
Lara awọn ohun ija ti wọn ri ni, ibọn ilewọ mẹfa, tajutaju, ado oloro atọwọda, ọta ibọn AK47 ati ọbẹ.
Omowe Fredrick Yao Mac-Palm, Ezor Kafui ni wọn n rọ awọn ohun eelo ija pamọ fun awọn eniyan yii.
Awọn eni yii n wa ifowosopo awon ọmọ ogun lati jọ ri agbara gba ni ero ileeṣẹ ifitonileti ijọba Ghana.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ni eyi ti iwadii fihan pe ọpọlọpọ ipade bonkẹle lo ti waye ni awọn ibudo ikọkọ.
Koda, wọn ṣawari ohun ija oloro ni ileiwosan bii ti Citadel Hospital ni Alajo ti wọn ko wọn pamọ si.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Bẹẹ ni wọn tun ṣawari ẹrọ ayara bi aṣa, ẹrọ ti wọn fi n gbohun silẹ ati iwe irina orilẹ-ede Ghana.
Ọkan lara awọn afurasi naa to jẹ dokita ni wọn fi ẹsun kan pe o ti n ra ibọn ati awọn ohun ija oloro miran, eyi to fẹ po pọ lati ile iwosan kan ti wọn ko darukọ.
Awọn onimọ nipa eto aabo ilu kan ti sọ pe, oṣeeṣe ki afojusun awọn afurasi naa ma jẹ lati ditẹ gbajọba, nitori awọn ohun ija ti wọn ka mọ wọn lowọ ko to lati gba ijọba.













