Buhari vs Atiku: Atiku ní kí ilé ẹjọ́ kéde òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @YouthSupportPDP

Àkọlé àwòrán, Buhari vs Atiku: Atiku ní kí ilé ẹjọ́ kéde òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí

Atiku ní kí ilé ẹjọ́ kéde òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí nínú ìbò ààrẹ àbí kó kéde ìdìbò míràn

Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ to tun jẹ oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar ti gba ile ẹjọ to gaju lorilẹ-ede yii lọ.

O ni oun gbe igbesẹ, lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lori esi idibo sipo aarẹ to waye loṣu keji ọdun yii.

Lọjọ kọkanla oṣu yii ni ile ẹjọ to n gbọ ẹsun eto idibo ti kede aarẹ Muhammadu Buhari gẹgẹ bi ojulowo ẹni to jawe olubori ninu idibo naa, to si da ejọ Atiku nu.

Igbimọ naa ni awọn ẹlẹri ti Atiku ko wa sile ẹjọ ko lee fi idi ọrọ mule pe aarẹ Buhari ṣe magomago ninu idibo ọhun.

Bẹẹ ni igbimọ naa tun ṣalaye pe ẹgbẹ PDP ko pese ẹri to daju lati fi han pe, oludije ninu ẹgbe APC ko ni iwe ẹri to yẹ lati dije sipo aarẹ.

Agbẹjọro agba fun Atiku, Mike Ozekhome ni, ipẹjọ naa da lori idi mẹrindinlaadọrin ti ko fi yẹ ki ile ẹjọ to n gbọ ẹsun eto idibo kede aarẹ Buhari gẹgẹ bi ẹni to jaweolubori ninu idibo to kọja.

Bi o tilẹ jẹ pe Ozekhome ko mẹnuba ọpọ ninu awọn idi ti ẹjọ kotẹmilọrun naa da le lori, sugbọn ẹjọ naa rọ mọ ọrọ iwe ẹri aarẹ Buhari ati ẹrọ ayara bi aṣa ajọ INEC.

Atiku n fẹ ki ile ẹjọ giga yii da idajo ti igbimọ to n ri si eto idajọ idibo da lọjọ kọkanla oṣu yii nu, ko si kede oun gẹgẹ ẹni to yege ninu idibo ọhun.

Bi ile ẹjọ naa ko ba lee ṣe eyi, Atiku fẹ ki ile ẹjọ giga naa da ibo sipo aare naa nu, ko si kede pe ki idibo miran waye.

Àkọlé fídíò, Sport Betting: Idí rèé tí àwọn ọ̀dọ́ kan fi n ta tẹ́tẹ́...