Amotekun: Toogun ní àwọn sá fún ariwo ni wọ́n ṣe ń ṣàyẹ̀wò fún ọ̀dọ́ 47,000 tó bèèrè iṣẹ́

Alakoso ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Ajibọla kunle Togun ti ṣalaye pe, aisi iṣẹ fun awọn ọdọ, lo mu ki iye awọn eeyan to forukọ silẹ lati darapọ mọ ikọ Amọtẹkun pọ yanturu.
Ninu ọrọ to ba ikọ BBC Yoruba sọ l'Ọjọbọ, nibi ti ayẹwo ti n lọ lọwọ fun awọn to fẹ darapọ mọ ikọ Amọtẹkun ni papa iṣere Lekan Salami nilu Ibadan, ni Toogun ti sisọ loju ọrọ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Wo àwọn obìnrin abúlé kan tó dáwó ra ọkọ̀ láti máa gbé aláboyún lọ ilé ìwòsàn
- Alámì ẹ̀yẹ Scrabble Paul Sodje àti ọ̀rẹ́ rẹ́ kú lásìkò tó fẹ́ lọ́ sanwó ìdóòlà ẹ̀mí àbúrò rẹ̀, tí afurasí darandaran jí gbé
- Ìjàmbá iná míràn tún wáyé ní pápákọ̀ ojú omi Beirut
- Ẹ fi dókítà àgùnbánirọ̀ rọ́pò àwọn dókítà tó ń yanṣẹ́ lódì - Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ
- Afenifere fara ya lórí bí Tinubu ṣe jókòó kí Ooni
- Háà ilẹ̀ wẹ! ọ̀dọ́ 47,000 fẹ́ di Amotekun, agbófinró yẹ̀ wọ́n wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́
- Aáwọ̀ oyè PDP gbé Fayose àti Seyi Makinde kọlu ara wọn, ìjà ń bọ̀
Ajagunfẹyinti naa ni ifilọ ti wọn ṣe ni pe, ẹnikẹni to ba jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ lọkunrin ati lobinrin laarin ọmọ ọdun mejilelogun de ọmọ ọgọta ọdun, lo ni anfaani lati gba fọọmu fun Amọtẹkun.

Togun tẹsiwaju pe "nigba ti fọọmu jade, o wa lori itakun ayelujara fun nnkan bi i ọjọ mẹjọ, wọn si fopin si i.
Ṣugbọn ohun ti a ri ni pe, awọn to ti forukọ silẹ ti le ni ẹgbẹrun mẹtadinlaadọta."
O ni awọn to forukọ silẹ lọna to tọ ko ju ẹgbẹrun mọkanla lọ, ṣugbọn ariwo maa pọ to ba jẹ pe awọn to ṣe e lọna to tọ nikan, ni wọn fun ni anfani lati ṣe ayẹwọ.

Lara awọn ohun amuyẹ ti wọn si n wo ni iriri nipa iṣẹ eto aabo ati ilera to dantọ.
Alaga ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ fi kun ọrọ rẹ wi pe, ọgbọn iwe nikan kọ ni Amọtẹkun da le lori.
O ni awọn figilante, sọludẹrọ ati awọn ọdẹ to ti n gbogun ti iwa ọdaran lati ẹyin wa, naa yoo lanfani lati darapọ mọ ikọ Amọtẹkun, ti wọn yoo si maa gba owo oṣu labẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ.

Bakan naa lo sọ wi pe iye owo kan naa kọ ni wọn o fi bẹrẹ fun gbogbo ẹni ti wọn ba gba. Ayẹwo to n lọ lọwọ ni yoo sọ ipo ti wọn o gba onikaluku si.
O ni bi i ẹgbẹrun meji eeyan pere lo ṣeeṣe ki wọn gba lẹyin gbogbo ayẹwo naa, bo tilẹ jẹ pe ọgọọrọ awọn eeyan lo forukọ silẹ nitori aisi iṣẹ lorilẹede yii.

Alaye rẹ ni pe, "O yẹ ki gbogbo aye mọ nisinyii pe ko si iṣẹ. Aye ti iṣẹ ba ti ṣi silẹ, awọn eeyan yoo sa lọ ibẹ ni, idi niyii ti ero fi pọ".
Pupọ ninu awọn eeyan to ba wa sọrọ ninu awọn to forukọ silẹ ṣalaye wi pe, ilepa ati ja fun ẹtọ ọmọniyan lo sun wọn de ibi iforukọsilẹ fun ikọ Amọtẹkun.
Ati ọmọde ati agba, ati ọkunrin ati obinrin, lo si wa ninu wọn.

Ayẹwo fun awọn to forukọ silẹ nilu Ibadan yoo waye laarin ọjọ kẹẹsan si ọjọ kẹrinla oṣu kẹẹsan ọdun yii, nigbati awọn ayẹwo to ku jakejado ipinlẹ Ọyọ yoo waye laarin ọjọ kẹẹdogun si ọjọ kọkanlelogun oṣu yii.
Háà ilẹ̀ wẹ! ọ̀dọ́ 47,000 fẹ́ di Amotekun, agbófinró yẹ̀ wọ́n wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́

Oríṣun àwòrán, Others
Orin wo la fẹ kọ si gbẹdun eyi, afi ero ya waa wo o, ni eto igbaniwọle awọn osisẹ fun ikọ Amotekun ba de bayii.
Idi ni pe o le ni eeyan ẹgbẹrun lọna mẹtadinlaadọta to yọju lọjọru, nibi eto igbanisisẹ fun ikọ alaabo Amotekun to bẹrẹ.
Bẹẹ lo se ni laanu pe, aaye ẹgbẹrun meji pere lo wa nilẹ ninu ikọ alaabo naa, ti wọn fẹ gba osisẹ si.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Aáwọ̀ oyè PDP gbé Fayose àti Seyi Makinde kọlu ara wọn, ìjà ń bọ̀
- Ènìyàn mẹ́ta pàdánù ẹ̀mí wọ́n lọ́wọ́ àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà ní Ọjọ́ọ̀rú
- Bí nǹkan ọkùnrin bá há sójú ara obìnrin, kìí ṣe Mágùn, ẹ má páyà
- Bàbálọ́jà márùn ún la ó ò ní l'Oyo tí Makinde bá lè buwọ́lu ìyànsípò YK Abass
- Ìjọba, e yé dẹ́yẹ sí wa mọ́, àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ṣèwọ́de n'Ibadan
- Auxiliary gbé èèyàn mẹ́fà tó ń jáwèé ayédèrú fáwọn awakọ̀ lọ sí ilèẹjọ́ ní Ibadan
Lara awọn eeyan to yọju lati gba isẹ naa la ti ri awọn ọmọ ẹgbẹ Agbẹkọya, ọdẹ, Fijilante, ọmọ ẹgbẹ OPC, awọn ọdẹ Soludero atawọn eeyan miran.

Bi ojumọ si se n mọ ni deede aago mẹjọ aarọ, ni papa isere idaraya Lekan Salami ti kun babi, nibi ti eto ayẹwo awọn to fẹ di Amotekun ti n waye.
Lara awọn ohun ti wọn n beere lọwọ ọpọ awọn eeyan naa, ti pupọ wọn ko niwe ẹri iwe ni, iwe iforukọsilẹ wọn, ati kaadi idanimọ wọn.
Ko tan sibẹ o, wọn tun n beere iriri ti wọn ni nidi didaabo bo adugbo wọn, ati ipa ti wọn n ko ladugbo si aabo awujọ nijọba ibilẹ wọn.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, Alaga ikọ Amotekun nipinlẹ Oyo, Ajagunfẹyinti Kunle Togun, sisọ loju rẹ pe awọn yoo finmu finlẹ lati mọ boya awọn eeyan yii ni akọsilẹ iwa ọdaran ri.
O fikun pe, awọn gba ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS atawọn osisẹ aabo ara ẹni, laabo ilu, Civil Defence lati se ayẹwo awọn oludije naa, ki wọn lee yọ eepo kuro lara Alikama.
Ikọ Amotekun ko ni gbe ibọn - DAWN commission

Oríṣun àwòrán, @DAWNCommission
Ọpọ ibeere to ti n jẹyọ nipa ikọ alaabo fun ẹkun Ila Oorun Naijiria ti a mọ si Amotekun ni Ọgbẹni Seye Oyeleye ṣalaye lẹkunrẹrẹ.
Oyeleye to jẹ oludari agba ajọ DAWN Commission to n ṣamojuto ilọsiwaju idagbasoke ọlọjọ pipẹ ni ẹkun Ila Oorun Naijiria ti wọn tun gbe iṣẹ le lọwọ lori ṣiṣamojuto eto Amotekun ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀.

Lori Owo Oṣu Ikọ Amọtẹkun
"Bẹẹ ba ri iye owo kan ti awọn eeyan kan n tan kalẹ bii N13,500 abi nkan mii pe ohun ni owo oṣu wọn, irọ nla ni o.
Oyeleye ni ijọba ipinlẹ ni yoo maa mojuto sisan owo oṣu wọn, ẹ si mọ pe ilana fun sisan owo oṣu oṣiṣẹ ijọba wa ni Naijiria, ohun ti wọn yoo tẹle niyẹn.
O tẹnu mọ ọ pe ko si ipinlẹ kankan ti yoo san owo to kere ju deede iye owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ gẹgẹ bi ilana ijọba.
- Ilé iṣẹ́ ọmọogun kò sọ fún mi pé ọkọ mi kú fún ọdún kan- Iyawo soja
- Iran ní àwọn kò mọ̀ọ́mọ̀ ju irínṣẹ́ ìbúgbàmù "missile" lu bàálù Ukrain tó já
- Wo Sultan Qaboos bin Said, ẹni tó gbàkóso ìgbé ayé òṣèlú Oman fún àádọta ọdún
- Ẹ́ gba fóónù, ẹ pe ẹbí yín pé a fẹ́ dáná ṣun yín - Aráàlú sọ fún adigunjalè méji
Eto igbanisiṣẹ sínu ikọ Amọtẹkun
Oyeleye jẹ ko di mimọ pe lara awọn to n ṣiṣẹ ninu ikọ Amọtẹkun yii wa latara awọn ẹgbẹ alaabo kọọkan to wa nikalẹ tẹlẹ tori gbogbo ipinlẹ lo ni awọn to n mojuto aabo wọn tẹlẹ.
Fun apẹẹrẹ, eeyan to n ṣiṣẹ laarin ẹgbẹ Peace Corpse, OPC, ẹgbẹ Fijilante tẹlẹ lo dara pọ mọ Amotẹkun kii ṣe awọn ti ko ni gbongbo kankan ninu iṣẹ aabo tẹlẹ.
Nitorinaa, awọn eeyan labẹle ninu awọn ilu naa lo jẹ awọn ti wọn ko jọ lati di ikọ Amọtẹkun niwọn igba ti wọn ba ti ni ikoju osuwọn to yẹ fun didara pọ mọ Amọtẹkun.

Oríṣun àwòrán, @DAWNCommission
Ilana Iṣiṣẹ Amọtẹkun
Gbogbo ipinlẹ lo da ni ikọ Amọtẹkun tirẹ wọn ko si ni re si ti ipinlẹ mii bii ki ọmọ ẹgbẹ Amọtẹkun kan re wa lati ipinlẹ Ondo lọ ṣiṣẹ ni Ekiti.
Ẹwẹ, ohun to tun mu eto yii dantọ ni pe bi ohunkohun ba ṣẹlẹ ni bii agbegbe aala tabi ibode ipinlẹ Yoruba meji ti iṣẹlẹ kan si waye, ikọ Amọtẹkun ipinlẹ mejeeji lee re sọdọ ara wọn lati jọ ṣiṣẹ papọ tori aala pa wọn pọ.
Bakan naa o mẹnu ba ọrọ adari ikọ Amotẹkun pe "ẹ o le ri eeyan kan ko dede jade wa pe oun ni Ọgagun Olori Amọtẹkun fun gbogbo Iwọ Oorun Naijiria".
Gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye, nkan ti o wa nilẹ ni igbimọ kan to ja gbogbo ipinlẹ mẹfẹẹfa pọ ti adari tabi alamojuto ipinlẹ kọọkan yoo korajọ loṣooṣu lati ṣepade lori ilana iṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun.
Lafikun. oludari agba ajọ DAWN Commission ni kii ṣe eyi ti yoo kasẹ nilẹ kiakia o, o wa lati duro titi ayeraye ni tori pe iye Ọlọpaa to wa ni Naijiria nikan ko to lati ṣe aabo loori gbogbo araalu.
O ni iye eeyan to wa lorile-ede Naijira gan an ti pọ si i.
"Amọtẹkun ko ni gbe ibọn, ikọ alaabo sọ́ọ́ ni yoo jẹ ni ipinlẹ"
"Iṣẹ Amọtẹkun ati ija ko jọ ara wọn rara o, Amọtẹkun ko ni jagun, ọrọ aabo ni iṣẹ tiwa". Wọn ni ẹrọ ibanisọrọ̀ laarin ara wọn.
Oyeleye ni awọn gomina naa ti sọ ọ nibi eto ifilọọlẹ pe Amọtẹkun kii ṣe ọlọpaa tabi sọja o, ọlọpaa ibilẹ lasan ni wọn jẹ
Nigba ti akọroyin BBC beere pe ṣebi nigba ti wọn wa ninu ikọ figilante fun apẹẹrẹ wọn maa n gbe ibọn, esi ti o fọ ni wi pe ṣe bi ibọn ṣakabula lasan ti wọn fi n pa ẹran ninu igbo niyẹn.
O ṣe apejuwe pe ọlọpaa lo maa n gbe ibọn, ikọ Amọtẹkun ko ni lo ibọn tabi nkan ijagun. Ọrọ aabo ilu lasan ni wọn yoo maa ri si lati ran awọn Ọlọpaa lọwọ ninu iṣẹ wọn.
Lakotan, o ni ki awọn ara ẹkun mii to n sọrọ lodi si agbekalẹ ikọ Amọtẹkun lọ jokoo tori oye ko ye wọn to ni.
O ṣapejuwe Ọlọpaa Hisbah ti Kano ti ẹnikẹni ko le ni ki wọ́n kasẹ rẹ nilẹ bẹẹ si ni o ṣalaye pe awọn Ọlọpaa ibilẹ yii nikan lo le mọ bi ajoji ba wọ ilu.
Bi wọn ba si ri iṣẹlẹ to waye loju ọna, loju igbo tabi ninu ilu, to kan iṣẹ ọlọpaa, wọn a fa iṣẹ naa le ọlọpaa lọwọ.

Oríṣun àwòrán, @DAWNCommission



















