Amotekun: Fayemi ni ikọ̀ àláàbò yìí ni yóò máa ṣe àkóso ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan

Gomina Kayọde Fayẹmi ti ipinlẹ Ekiti, to tun jẹ alaga agbarijọpọ awọn gomina orilẹede Naijiria ṣe alaye wi pe, lojoojumọ ni a n koju ipenija wahala awọn adigunjale, darandaran ati bẹẹbẹẹ lọ ni ẹkun iwọ oorun Naijiria.
O ni bo tilẹ jẹ wi pe awọn ileeṣẹ agbofinro sa ipa wọn, sibẹ, omi pọ ju ọka lọ nitori ọkan lara awọn adari ẹya Yoruba, Reuben Faṣọranti naa padanu ọmọ rẹ sinu laasigbo to n ba ilẹ Yoruba finra ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìfẹ́ èmi àti olólùfẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ta jẹ ètè ara wa nínú sinimá - Nkechi Blessing
- Ẹ̀yin ẹkùn yókù, ẹ fi ikọ̀ àbò "Amotekun ṣe àwòkọ́ṣe rere - APC
- Ọmọọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Harry àti ìyàwó rẹ̀ kọ ipò wọn sílẹ̀ ní ìran ọba
- Ta ló ń fi ògùn Paracetamol, Hypo dín Gààrí lọ́dọ̀ yín níbẹ̀ yẹn?
- Makinde fẹ́ san ₦30,000 fáwọn òṣìṣẹ́ l’Oyo, yóò tún kọ́ ọjà ìgbàlódé sí Akẹ̀sán
Fayẹmi tẹsiwaju wi pe, eyii lo ta awọn gomina ilẹ Yoruba nidi kan lati pe ipade pajawiri lori eto aabo ilẹ Yoruba ni bii oṣu mẹfa sẹyin, abajade apero naa si ni Amọtẹkun ti wọn n ṣiṣọ loju ẹ lonii.
O ni Amọtẹkun ko waye lati rọpo awọn ileeṣẹ aabo to n bẹ nilẹ tẹlẹ, ṣugbọn yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹṣọ aabo to ku, ki eto naa le kẹsẹjari.

O ṣe afikun ọrọ wi pe, gbogbo awọn aṣoju Amọtẹkun ni yoo maa ṣe amojuto awọn agbegbe kọọkan pẹlu oye ede ati aṣa awọn agbegbe naa.
Fayẹmi ṣe alaye wi pe, Amọtẹkun ipinlẹ kọọkan ni yoo maa mojuto ipinlẹ ti wọn pin wọn si lai rekọja lọ si ipinlẹ mii, ayafi ti iṣẹlẹ pajawiri ba waye.

Igbakẹji gomina Ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Alabi to soju gomina Gboyega Oyetola nibi akanṣe eto naa ni, agbekalẹ Amọtẹkun jẹ ojuṣe awọn gomina nitori ikawọ wọn ni aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ilu wa.
O dupẹ lọwọ ileeṣẹ ologun ati awọn agbofinro to ku, fun bi wọn ṣe ji giri si ojuṣe wọn lasiko ti ipenija eto bẹrẹ ni ẹkun iwọ oorun Naijiria.
O wa parọwa si awọn aṣoju Amọtẹkun lati ṣiṣẹ wọn pẹlu otitọ inu pẹlu alaye wi pe, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ya ikorita Ọlajokun silẹ ni opopona maroṣẹ Gbọngan, ti yoo maa jẹ olu ileeṣẹ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun.

Ninu ọrọ ti ẹ, gomina ipinlẹ Ondo ti o tun jẹ alaga agbarijọpọ awọn gomina ilẹ Yoruba, Rotimi Akeredolu ni ifilọlẹ Amọtẹkun jẹ nnkan ayọ fun gbogbo awọn gomina ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.
O ni eto aabo ilẹ Yoruba ṣe pataki si awọn gomina naa, eyi lo si ṣe atiwaye ifilọlẹ Amọtẹkun.
Akeredolu ni ko si ipinlẹ kankan ti o bọriyọ lọwọ awọn ipenija eto aabo lorilẹede yii, eyii lo si mu ki awọn ọmọ orilẹede yii to n bẹ loke okun maa bẹru lati wa si ilẹ baba wọn.
Gomina ipinlẹ Ondo tẹsiwaju wi pe, agbekalẹ Amọtẹkun yoo mu opin de ba wahala awọn adigunjale, darandaran ati ijinigbe.
O ni awọn gomina ilẹ Oodua ko ni tẹti ninu ojuṣe wọn titi ti ipenija eto aabo yoo fi di ohun igbagbe ni ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, eyii lo si mu ki gbogbo awọn gomina naa fi orikori lati ṣe ifilọlẹ Amọtẹkun.

Lẹyin eyi ni gomina ipinlẹ Ondo ti o tun jẹ alaga awọn gomina ilẹ Yoruba, Rotimi Akeredolu ti ṣiṣọ loju awọn ọkọ iwọde fun Amọtẹkun.
O ṣe alaye wi pe alupupu bii ọgọrun mii tun wa kaakiri awọn ipinlẹ to n bẹ ni iwọoorun guusu fun iwọde Amọtẹkun.
Àsìkò tó fún ilẹ̀ Yorùbá láti dẹ́rù ba ẹ̀rù fúnra rẹ̀ pẹ̀lú Amotekun - Seyi Makinde

Lẹ́yin o rẹyin, eto ifilọlẹ Amotekun to yẹ ko ti bẹrẹ lati aago mẹsan aarọ, ti gberasọ bayii, tawọn eeyan jankan-jankan, to fi mọ awọn gomina mẹfẹẹfa nilẹ Yoruba, si ti de sibi eto naa.
Bakan naa ni awọ̀n oriade nilẹ́ Yoruba bii Ọ́ọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, Olugbọn tile Igbọn ti peju sibi ayẹyẹ naa.
Ninu ọrọ ikini kaabọ rẹ, olugbalejo pataki nibi ayẹyẹ ifilọlẹ ọhun, gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ ni, asiko ti to fun ilẹ Yooba lati dẹruba ẹru gangan funra rẹ.

Makinde tẹsiwaju pe agbẹkale Amọtẹkun waye fun igbaye-gbadun ati eto aabo to nipọn fun gbogbo ọmọ Oodua. O ni gbogbo gomina lo bura lati bọwọ fun ofin nipa ṣiṣe agbekale eto aabo ti yoo rẹsẹwalẹ fun gbogbo awọn araalu.
Gomina ipinlẹ Ọyọ fikun pe akanṣe eto yii si jẹ imuṣẹ ileri ti awọn gomina ṣe lasiko iburawọle, pẹlu alaye pe inu oun dun lati jẹ olukopa ninu agbekalẹ eto ti yoo fẹ oju eto aabo ati igbayegbadun awọn eeyan ilu.

O tẹsiwaju wi pe, ipinlẹ Ọyọ tun ti gba oye tuntun gẹgẹ bii ipinlẹ ti agbekalẹ eto aabo ẹlẹkunjẹkun akọkọ iru ẹ ti gbinaya.

Kí ló ń fa ìdádúró nípa ìfilọ́lẹ̀ 'Amotekun' tó yẹ kò wáyé lónìí?
Ifilọlẹ eto aabo alajumọse ti awọn gomina ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria se agbatẹru rẹ, ti wọn pe ni "Amọtẹkun" ti gbinaya bayii.Agbekalẹ naa waye lati bomirin eto aabo nilẹ Yoruba, paapaa julọ lori ikọlu awọn darandaran to n gogo lẹnu lọọlọ yii.Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akereolu ti o jẹ alaga awọn gomina ilẹ Yoruba ni ireti wa wi pe yoo ṣi'ṣọ loju eto naa, ti yoo waye lọọfisi gomina nilu Ibadan.
Ireti si wa pe gomina Seyi Makinde ni yoo jẹ olugbalejo nibi ayẹyẹ naa.
Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi ifilọlẹ eto aabo naa fi to wa leti pe, aago mẹsan ni eto naa yẹ ko bẹrẹ, ti wọn si n reti awọn alejo pataki lọwọlọwọ.

Awọn ẹṣọ aabo igberiko ati diẹ lara awọn alejo ti wọn fi iwe pe nikan lo wa nikalẹ, ti wọn si ti gbe awọn ọkọ isẹ ti wọn fẹ pin fun awọn osisẹ alaabo kalẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, ana Ọjọru ni ileeṣẹ aarẹ kesi awọn gomina mẹfẹẹfa to n bẹ nilẹ Yoruba lati wa wi tẹnu wọn lori agbẹkalẹ eto aabo Amọtẹkun naa, amọ titi di akoko yii, a ko tii mọ ohun ti wọn ba bọ lati ileesẹ aarẹ.

Iroyin kan to n ja rainrain labẹlẹ ni wi pe, o ṣeeṣe ki ileeṣẹ aarẹ pagidina agbekalẹ eto aabo Amọtẹkun lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria.
Ohun mii ti awọn eeyan tun un sọ ni wi pe o ṣeeṣe ki ileeṣẹ aarẹ maa bẹru wi pe, ilẹ Yoruba ti fẹ ya ara wọn kuro ni Naijiria nipasẹ agbekalẹ naa.
Bi isẹlẹ naa ba se n lọ, a maa mu wa fun yin.













