Amotekun: APC ń fẹ́ káwọn ẹkùn yókù wàwòkọ́ṣe Ikọ̀ àbò àmọ̀tẹ́kùn fún àbò ẹkùn wọn

Awọn ọlọpaa n rin pẹlu aja wọn

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Ẹgbẹ oṣelu APC ti rọ awọn ẹkun miran lorilẹede Naijiria lati ya omi ọgbọn bu mu lori eto abo tuntun 'Operation Amọtẹkun' tawọn ijọba lẹkun iwọ orun gusu orilẹede Naijiria ṣẹṣẹ fẹ gbe sita eyi ti wọn yoo fi lọọlẹ lonii.

Igbakeji alaga apapọ ẹgbẹ oṣelu APC fun ẹkun iwọ orun gusu Naijiria, Bankọle Oluwajana lo sọ bẹẹ.

O ni bi oun ṣe n wo o, ọwọja ikọ alaabo naa yo rinlẹ daadaa paapaa julọ bi awọn ẹkun yoku ba lee wo awokọṣe rẹ.

O ni awọn ẹkun bii aringbungbun gusu orilẹede Naijiria, ila oorun gusu ati aringbungbun ariwa orilẹede Naijiria naa yoo nilo lati tun ya a lo nitori ikọ alaabo tuntun naa yoo gba ẹkun Yoruba pada lọwọ awọn janduku ati ọdaran to n ṣọṣẹ nibẹ.

Ni Ọjọbọ, ọjọ kẹsan oṣu kinni ọdun 2020 ni awọn gomina ipinlẹ mẹfẹẹfa to wa nilẹ Yoruba yoo ṣefilọlẹ ikọ abo Amọtẹkun nilu Ibadan.