Cardiac Attack: Wo ọ̀nà méje bí o ṣe lè dẹ́kun ikú òjijì

Cardiac Attack

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Kogi, Taiwo Kola-Ojo papòdà lẹ́yìn tí ó fò sánlẹ̀ kú níbí tó tí ń gbá bọ́ọ̀lù ẹ́lẹyin.

Ọpọlọpọ eniyan lai yọ ọmọde tabi agbalagba silẹ lo ti ku iku ojiji nitori aiṣe akiyesi ara wọn.

Koda, ni irọlẹ Ọjọ Isẹgun ni iroyin gbalẹ pe gba Alagba ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Kogi, Agbẹjọrọ Taiwo Kola-Ojo subu lulẹ, ni ibi ti o ti n gba bọọlu ẹlẹyin, lawn Tennis to si ku.

Bakan naa ni Osu Kẹwa, ọdun 2019 ni arakunrin kan fo sanlẹ to si ku, nibi to ti n sare ni agbeegbe WEMCO, ni Ogba, nipinlẹ Eko.

Tunwẹ, Ọdun 2018 ni Alaga Ajọ Ere Idaraya, Deji Tinubu naa fọ sanlẹ ku lasiko to n ṣe ere idaraya bọọlu alafẹsẹgba ni agbeegbe Epe ni Ilu Eko.

Ta ba wa ni ka beere, ki lo de tawọn eeyan fi n se agbako iku ojiji bayii, paapa lasiko ere idaraya atawọn ọna ta lee gba dena rẹ.

Nigba to n dahun awọn ibeere yii fun BBC Yoruba, Onimọ kan nipa eto ilera ara, Chidinma sọ awọn nkan to n fa iku ojiji lawujọ ati ọna abayọ.

Wo ọ̀nà méje bí o ṣe lè dẹ́kun ikú òjijì:

  • Aṣekudorogbo iṣẹ: ọkan lara iṣoro awa eniyan ni aye ode oni ni lati wa ounjẹ oojọ, eleyii ti o mu ki ọpọlọpọ eniyan miran ma a ṣe iṣẹ aṣekudorogbo. Ọna abayọ si ni lati ma a sinmi lati igba de igba
  • Ẹjẹ Riru: Eyi naa le e fa iku ojiji. nitorina eto ayewo ara, paapaa ifunpa to ga, ṣe koko
  • Oyun nini: Asiko iloyun jẹ asiko ẹlẹgẹ fun awọn obinrin, nitori naa o se koko ki oloyun se ayẹwọ ara ati ọmọ ni igba de igba
  • Omi mimu: Ti eniyan ko ba mu omi deede ati lasiko, o ṣeeṣe ki iru eniyan bẹẹ sagbako iku ojiji. Ọna abayọ ni lati ma a mu omi deede lasiko ni igba gbogbo
  • Ibẹru: Ẹni to ba n bẹru lati igba de igba le e ku ojiji. Ọna abayọ ni lati lọ si ile iwosan lati igba de igba fun itọju to peye
  • Idide pajawiri lori ibusun: Bi a ṣe n dide lori ibusun sé koko si ilera ara eniyan. Ti eniyan ba ji dide lojiji, o le e ku iku ojiji. Ọna abayọ ni ki eniyan kọkọ ji lori ibusun, ko yi sẹ gbẹ, lẹyin naa ko joko, ko gbe ẹsẹ le lẹ, ki o to sẹṣẹ dide lori ibusun patapata
  • Isubu ojiji: Ti eniyan ba subu lojiji, o le e ja si iku. Ọna abayọ ni lati kiyesi ara wa, paapaa ti aarẹ ba n se eniyan, abi to n rẹ ẹ lati inu wa.

Dokita Chidinma wa rọ awọn eniyan lati ma a se ayẹwo ara wọn ni ẹẹkan laarin oṣu mẹfa, ki wọn ba le mọ ipo ti ẹya ara wọn wa.

Bakan naa lo parọwa fun awọn eniyan lati ma a jẹ ounjẹ to n ṣe ara loore pẹlu eso jijẹ lasiko.