Calabar Killing: Àwọn ará ilú dáná sún èèyàn méji tí wọ́n furasí bíi olè

Fire

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Calabar Killing: Àwọn ará ilú dáná sú èèyàn méji

Àwọn ènìyàn méjì kan ti wọ́n fura si gẹ́gẹ́ bi olè, ni wọ́n ti dáná sun nilu Calabar, tii ṣe olú ilú Cross River.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ni agbègbè Akai Effa, tawọ́n si fi tipa fun àwọn afurasi náà ni fóònù láti pe àwọn ẹbí wọ́n láti sọ fún wọ́n pé, wọ́n ti fẹ́ dána sun àwọn nítorí àwọn jalè ki wọ́n to dána sun wọ́n.

Ìròyìn sọ pé, àwọn ará àdúgbò ọhun pà imọ̀ pọ̀ láti dána sún àwọ́n afurasi adigunjale naa nítori bi àwọn olè ṣe n já ládúgbò láti ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn.

Ní ọjọ ọdún kérésìmesi, afurasi ọ̀daran kan lẹ́yìn to jalè tán, tún fipa bá ẹni to kamọle lòpọ̀ ni àgbègbè Okoro Agbor ní Calabar.

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

Amọ o papa bọ si ọwọ àwọn ara ilú, wọ́n lùú, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọlọpàá gbìyànjú láti gba silẹ̀ sùgbọ́n ẹmi ti bọ lára rẹ̀ ki wọ́n to gbé de ilé ìwòsàn.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Alukoro ọlọpàá ipinlẹ Cross Rivers, DSP Irene Ugbo, fìdi ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé lootọ ni isẹlẹ naa waye, bi ko tilẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ míràn kún alaye rẹ mọ.

Àkọlé fídíò, 'Inu mi bàjẹ́ nígbà tí mo bí i, odidi oṣù mẹ́ta, mi ò lè gbàdúrà s'Ọ́lọ́run'