CAN rọ ìjọba àpapọ láti tú àwọn òǹdè Boko Haram silẹ̀

Ayokunle Samson

Oríṣun àwòrán, Ayokunle

Àkọlé àwòrán, CAN rọ ìjọba àpapọ lati tú àwọn òunde Boko Haram silẹ̀

Ẹgbẹ́ tó n ri sí ọ̀rọ̀ tó kan àwọn ọmọ lẹ́yìn Krísti lórílẹ̀-èdè Naijiria (CAN) ti rọ ìjọba àpapọ láti lo gbogbo ǹkan to ba wà ni ìkáwọ wọ́n láti tu àwọn Kristẹni to wà ni àhámọ Boko Haram àti ISWAP silẹ̀.

Wọn ni o ṣe pataki nítori pé àwọn ti wọ́n pa laipẹ yìí fi han pé, àwọn onígbàgbọ́ lorilẹ̀-èdè Naijiria n kojú inúnibini.

Nínú àtẹjáde kan láti ọ̀dọ̀ ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Ọmọwe Samson Ayokunle, èyí ti olùrànlọ́wọ́ pàtàkì lori ibanisọrọ, Adebayo Oladeji fọwọ si nílu Abuja, LO TI SỌRỌ NAA.

O ṣàlàyé pé alága ẹgbẹ́ CAN ti Michika ni ìpínlẹ̀ Adamawa, Lawan Andimi ti wà ní àhámọ Boko Haram láti ọ̀ṣẹ̀ to kọja nígba ti wọ́n yabo ilú náà to jẹ́ pé Kristẹni lo pọ̀ níbẹ̀.

O fí kún un pé " bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ ogun jà fitafita, ki wọ́n to fi tipa gbé Andimi lọ pẹ̀lú ọkọ Hilujx wọ́n, nínú fọ́nran ti wọ́n fi si ta.

Àkọlé fídíò, Olaitan Olamide: mò lè má nílò ìwé ẹ̀rí mi tí mo bá parí ní LASU

O ní oníwàásù náà ti n bẹ ìjọba àpapọ, gómìnà Adamawa àti àwọn adari CAN láti ran òun lọ́wọ́."

Àkọlé fídíò, Yoruba language: Ọdún 2020 to wọlẹ́ dé yìí á tu gbogbo wa lára

Ààrẹ CAN tún fi ẹdun ọkàn rẹ̀ hàn pé, àfi bi ẹni pe èyí kò tó ni àwọn alọkolohun kígbe tun yabo ilú ti àwọn Kritẹni to n gbé ni Ijọba ibilẹ̀ Chikun ni ìpínlẹ̀ Kaduna ní déEdé ààgo mẹ́fà ààbọ lọ́jọ́ Ajé.

Nibẹ ni wọn ti kó èníyàn mọkànlélógún to fi mọ olùṣọagùntàn, Joshua Samaila ti ko si si ẹni to mọ ǹkankan nípa wọ́n titi di àsìkò yìí.

Bakan náà ni wọ́n ke si àjọ ìsọkan àgbáyé (UN) ilẹ̀ Amerika, àti ilẹ̀ Gẹẹsi to fi mọ àwọn orilẹ̀-ede míràn láti dide ìrànwọ, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba Naijiria láti dóòlà ẹmi àwọn ènìyàn wọ̀nyi ko to pẹ́ jù.

Àkọlé fídíò, Fadele: Dán an wò, lóbí ìyá ọ̀kẹ́rẹ́ ni a fi ọ̀rọ̀ ọ̀kadà náà ṣe

CAN àti gbogbo àwọn ọmọ Naijiria wá fi da àwọn to wà nínú ìgbèkùn lásìkò yìí lójú pé àwọn ǹ gbà àdúra fun wọ́n àti pe Ọlọrun yóò tú wọ́n sílẹ̀ nínú ìgbèkùn ti wọ́n wà gẹ́gẹ́ bi o ṣe gbà àwọn ọmọ Isrẹli silẹ̀ lọ́jọ́si.

Àkọlé fídíò, 'Inu mi bàjẹ́ nígbà tí mo bí i, odidi oṣù mẹ́ta, mi ò lè gbàdúrà s'Ọ́lọ́run'