Electricity tariff hike: SERAP ní aráàlú kò lè máa jìyà, káwọn tó dipò òṣèlú mú máa gbádùn

Ajọ ajafeto-ọmọniyan kan ni Naijiria, SERAP ati awọn eeyan mejilelọọdunrun mii, ti pe aarẹ Buhari ati ile aṣofin lẹjọ lori afikun owo epo bentiroo ati owó ina ọba.
SERAP ati awọn ti wọn jijọ pe ẹjọ yii ni awọn fẹ ki ile ẹjọ "f'ọwọ rọ afikun owo epo ati ina ọba sẹyin.
Alaye wọn ni pe awọn eeyan to dipo nla mu ninu ijọba ko le maa gbadun, ki wọn wà ni k'ara ilu maa ṣe ifarada."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Buhari, ìwọ́de yóò yíwọ́, tó gbá jẹ́ káwọn ológun bá bẹ̀rẹ̀ ‘Operation Crocodile Smile’ "
- Ìjọba Eko pàdánù ₦234m láàrín ọ̀sẹ̀ kan torí ìwọ́de End SARS
- Bí o bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tí yóò rọ́pò SARS, wo àmúyẹ tí o gbọ́dọ̀ ní
- Aisha Buhari polongo àwo orin tó ní Nàíjíríà ń ṣun ẹ̀jẹ̀ lásìkò ìwọ́de
- Lizzy Anjorin ń kiri àgọ́ ọlọ́pàá láti gba ọ̀dọ́ afẹ̀hónúhàn, tó wà láhàámọ́ sílẹ̀
- 2015 ni mo ti ń kígbe pé gudugbẹ̀ máa já ní Nàíjíríà - Oyedepo
- Wo ohun tí ìwọ́de ENDSARS ṣé fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ ṣèdánwò NECO
- Láàrin wákàtí mẹ́ta, wọ́n dá ₦4m fún àkàndá ẹ̀dá tó kópa nínú ìwọ́de
Ninu awọn ti wọn pe lẹjọ yii la ti ri igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo, aarẹ ile aṣofin agba Ahmad Lawan ,Olori ile aṣoju-ṣofin, Femi Gbajabiamila ati awọn mii.

Oríṣun àwòrán, NERC
SERAP tun n beere pe ki ile ẹjọ kéde pe aarẹ Buhari lo agbara to ni labẹ ofin, lati le fi owo kun owo epo ati ina ni ilokulo ati lọnà to tako ẹjẹ to jẹ labẹ ofin yi kan naa.
Agbẹjọro SERAP Kolawole Oluwadare ati Opeyemi Owolabi to pe ẹjọ yii ni:
"Ṣiṣe iṣẹ tọ ilu tumọ sí pe kí eeyan fi awokọṣe daada le'lẹ to fi mọ ki awọn to di ipo mu gan mu adinku ba owo gọbọi ti wọn n gba, ko le wa ni ibamu pẹlu t'awọn ara ilu to pe wọn lẹjọ"
Won tun ni ki ile ẹjọ f'asẹ sí pe owo t'awọn eekan ninu ijọba n gba, toun ti bi ilu ko ṣe rọgbọ, ko bofin mu.
Awọn alaṣẹ ti wọn darukọ ni aarẹ ile aṣofin agba,aare Buhari ati igbakeji rẹ tó fi mọ olori ile aṣojuṣofin.
Irọ́ ni pé a fẹ́ fowó kún owó iná mọ̀nàmọ̀nà- NERC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Jìbìti ni àfikún owó iná mọ̀nàmọ́ná tí ìjọba kéde rẹ̀- Egbẹ oṣiṣẹ
Ẹgbẹ oṣiṣẹ lapaapọ atawọn ẹgbẹ ajafẹtọ ti koro oju si afikun owo ina mọnmọna ti ijọba apapọ kede rẹ.
Wọn ni jibiti ni ki ijọba fikun owo tawọn araalu n san fun ina mọnamọna nigba ti ina ọhun n ṣe ṣegeṣege ni gbogbo igba.
Ajọ to n ri si okowo ati ile iṣẹ nipinlẹ Eko ni tirẹ bu ẹnu ẹtẹ lu bi ijọba ko ṣe wa nnkan ṣe si bi ile iṣẹ mọnamọna ti n bu owo tawọn eeyan n san lai lo ẹrọ mita.
Ṣe lootọ ni afikun owo maa gori ina mọnamọna?
Ogbeni Usman Arabi, to jẹ ọga agba ẹka ọrọ ara ilu nile iṣẹ mọnamọna NERC kede ninu atẹjade kan pe irọ to jina si ootọ ni iropyin naa.
Loju opo ileeṣẹ iroyin Naijiria, ati itakun agbaye wọn ni Arabi ti ṣalaye lọjọ Aiku pe afikun owo ina mọnamọna to gbode kan kii ṣe tuntun.
O ni o ti wa lati atunṣẹ ti wọn gba aṣẹ lati ṣe ninu agbeyẹwo todun 2016 si 2018 ni.
O ni igbesẹ naa kan ti ọdun 2016, 2017 ati 2018.
Arabi kede pe fun idi eyi ko si alekun owow ori ina mọnamọna rara.
O ni iru igbesẹ bẹẹ ko le deede waye laisi pe ijọba pe ijoko ijiroro pẹlu gbogbo awọn ara ilu ti ọrọ kan ṣaaju fifi owo kun owo ina mọnamọna.
Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?
Lọjọ Satide ọsẹ to kọja ni iroyin ni ajọ to n ṣamojuto ina ọba paṣẹ fawọn ile iṣẹ to pin ina mọnamọna mọkanla to wa ni orilẹ-ede Naijiria pe ki wọn fikun owo ina bẹrẹ lati oṣu kẹrin ọdun 2020.
Igbesẹ yii fihan pe o ti di igba mẹta ọtọọtọ bayii ti ijọba ti ṣe afikun owo ina laarin ọdun marun un sẹyin ni Naijiria.
Alaga igbimọ to n dundura pẹlu ijọba atawọn oṣiṣẹ, Abdulrafiu Adeniji ni o ṣeni laanu pe ijọba le sare kede afikun owo ina nigba ti ko ti yawo kan dejo lori ẹkunwo owo oṣu oṣiṣẹ kaakiri Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan ijọba ipinlẹ mẹẹdogun ni ko tii fẹnu ko lori ẹkunwo owo oṣu tuntun fawọn oṣiṣẹ, bi o tilẹ jẹ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2019 ni gbendeke ti ẹgbẹ oṣiṣẹ fawọn gomina.
Ọgbẹni Adeniji ṣalaye pe afikun owo ina ọba dabi jija awọn ọmọ Naijiria lole.
Bakan naa ni akowe ati alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ologbondiyan sọ pe igbesẹ ijọba lati fowo kun owo ina yoo dakun iṣoro awọn araalu.
Ọgbẹni Ologbondiyan ni ijọba ko ni ifẹ araalu ninu pẹlu igbesẹ yii lẹyin owo ori gọbọi tawọn eeyan n san ati ọwọ gogo ọja.

















