Láàrin wákàtí mẹ́ta, wọ́n dá ₦4m fún àkàndá ẹ̀dá tó kópa nínú ìwọ́de

Yoruba bọ wọn ni bi Oluwa ba n se rere, a sọ pe o n se ibi.
Oniruuru itumọ ni iwọde awọn ọdọ to n lọ lọwọ lee ni fun ọpọ eeyan, bi awọn miran se ro pe ohun buburu ni, amọ ohun ayọ lo n jẹ fawọn eeyan miran.
Idi ni pe iwọde awọn ọdọ to n fẹhonu han, ti wọn si n beere fun fifi opin si isẹ awọn ọlọpaa SARS, ti mu iroyin ayọ ba ọdọbinrin kan, Jane to jẹ akanda ẹda.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- 2015 ni mo ti ń kígbe pé gudugbẹ̀ máa já ní Nàíjíríà - Oyedepo
- Lizzy anjorin ń kiri àgọ́ ọlọ́pàá láti gba àwọn ọ̀dọ́ afẹ̀hónúhàn, tó wà láhàámọ́ sílẹ̀
- Àwọn ọ̀dọ́ se ìrẹsì jọ̀lọ̀ọ́fù ní márosẹ̀ Benin sí Ore láti fẹ̀hónú hàn
- Afárá Marina àti Eko yóò di ṣíṣí padà lọ́la
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ 'Operation Crocodile Smile' yíká Naijiria fún oṣù méjì
- Òkú tó jí lọ́jọ́ kejì ní mọ́ṣúárì padà kú síléèwòsàn
Ọdọbinrin naa ni wọn ti ge ẹsẹ rẹ kan, to si n fi irin rin lati fi sikeji ẹsẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, @aproko_doctor
Amọ ipenija ara yii ko da ọmọbinrin naa duro lati dara pọ mọ awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu iwọde ti wọn n se.
Aarọ ọjọ isinmi si ni wọn gbe iroyin nipa iwa akinkanju Jane yii sori ayelujara, ẹni ti wọn ni ko nisẹ lọwọ lati ọdun 2013 nitori ipenija ara to ni.
Awọn ọdọ akẹẹgbẹ rẹ yii ni wọn ni ihuwasi Jane naa wu awọn lori, ti awọn si fẹ seto iranwọ owo fun.
Ọpọ ọdọ to ka ikede yii nipa ọmọbinrin akanda ẹda naa ni ori wọn wu, ti wọn si n da owo jọ si apo asunwọn ti wsn gbe kalẹ fun Jane.
Fun iyalẹnu, laarin wakati mẹta ti ikede ẹdawo ọhun de ori ayelujara, awọn ọdọ yii atawọn ọmọ Naijiria miran ti da owo to fẹ wọ miliọnu naira fun Jane.
Awọn ọdọ naa ni awọn fẹ ra ẹsẹ atọwọda fun ọmọbinrin naa, ko le e maa rin lai lo igi mọ.
Ọba oke nikan si lo lee sọ iye ti Jane yoo ri ko jọ ki ilẹ oni to su, eyi to n parọwa siwa pe ilẹ aanu Oluwa kii su.













