End SARS protest: Lára àwọn ìlú tí ìwọ́de ti wáyé ní Ibadan, Ado Ekiti, Osogbo, Ado Ekiti ati Eko

Se ni eto okoowo dẹnu kọlẹ kaakiri awọn ipinlẹ to wa nilẹ wa Naijiria ati olu ilu ilẹ wa Abuja.
Idi ni pe awọn oluwọde yika orilẹede yii, to n beere fun opin ọlọpaa SARS, ni wọn gbe igi dana lawọn opopona ati papakọ ofurufu.
Koda, awọn ọlọja ko lee si sọọbu tabi patẹ ọja wọn lasiko ti iwọ̀de naa n waye, ti ohun gbogbo si dẹnu kọlẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹlẹ́wọ̀n 200 sálọ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Benin lásìkò ìwọ́de EndSars
- Ìjọba da ológun sí Abuja láti dẹ́kun ìwọ́de
- Mo fura pé ẹ fẹ́ da Nàíjíríà rú, ń kò ṣe ìwọ́de mọ́ - Segalink, agbátẹrù ìwọ́de yọwọ́
- Ìwọ́de EndSARS gboró n‘Ibadan, kò sẹ́ni tó le wọlé tàbí jáde
- "Buhari, ìwọ́de yóò yíwọ́, tó gbá jẹ́ káwọn ológun bá bẹ̀rẹ̀ ‘Operation Crocodile Smile’ "
- Ìjọba Eko pàdánù ₦234m láàrín ọ̀sẹ̀ kan torí ìwọ́de End SARS
- Bí o bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tí yóò rọ́pò SARS, wo àmúyẹ tí o gbọ́dọ̀ ní
- Aisha Buhari polongo àwo orin tó ní Nàíjíríà ń ṣun ẹ̀jẹ̀ lásìkò ìwọ́de
Se ni awọn akẹkọọ pada sile ni lai le kẹkọọ tawọn ile iwe gbogbo si gbe ilẹkun wọn tipa, bẹẹ ni awn to yẹ ko joko sedanwo NECO, ko le wa sile iwe.

Koda, laasigbo to waye lati ipasẹ iwọde to n lọ lọwọ yika Naijiria yii ko yọ awọn osisẹ ọba silẹ pẹlu, nitori wọn ko ri ọkọ wọ tabi gbe lọ sibi isẹ wọn.
Awọn osisẹ to si ti de ibi isẹ ni wọn gan sare gbe ilẹkun ọọfisi wọn ti, ki wọn lee tete pada sile ki ohun gbogbo to fọnna soju.
Awọn oluwọde naa, laarọ ọjọ Aje, si ni wọn n kọ oniruuru orin to n tabuku ijọba Buhari.

Lati igba ti iwọde End SARS ti bẹrẹ, gbogbo awọn ilu nla nla ni Naijiria lo ti ni imọlara iwọde naa, lara awọn ilu nla nla ti iwọde naa ti milẹ titi ni Eko, Abuja, Osogbo, Ibadan, Ilorin, Ado Ekiti, Abeokuta ati bẹebẹẹ lọ.
Ohun ti awọn oluwọde naa n beere fun ni pe, ki ijọba apapọ fopin si SARS, ki wọn si tun fi oju gbogbo awọn ọlọpaa to fi iya jẹ ara ilu lọna aitọ wina ofin.
Wo diẹ lara bi iwọde naa ṣe waye lawọn ilu nla ni Naijiria ni ọjọ Aje:
Ipinlẹ Ekiti:
Nilu Ado Ekiti, tii se olu ilu ipinlẹ Ekiti, iroyin to wa lati ibẹ ni se lawọn oluwọde oluwọde naa ti gbogbo opopona pa lai si lilọ bibọ ọkọ ati ero

Oríṣun àwòrán, @Ekitiupdate
Awọn opopona to gbajumọ ti wọn tipa naa ni ọna Fajuyi Park, Okeyinmi, Ijigbo, Adebayo, Basiri ati Ajilosun.
Awọn oluwọde yii ni wọn n kọ orin ibilẹ wa ati tipinlẹ Ekiti, ti wọn si gbe oniruuru akọle to n tabuku aarẹ Buhari ati ijọba rẹ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, @sosintayo
IpinlẹEko:
Lara awọn ibi ti wọn gbe iwọde ọhun de ni ilu Eko ni, opopona marosẹ Lekki si Ajah, Alausa ni Ikeja, Oba Akran, Allen Avenue, ati bẹbẹ lọ.
Se ni wọn si ti awọn opopona to gbajumọ pa nilu Eko, to si nira fawn eeyan ati ọkọ lati kọja lati adugbo kan si omiran.

Lara awọ̀n adugbo ti wọn ti pa ni opopona Allen si oba Akran, koda paro paro ni awọn agbegbe naa da.
Bakan naa ni awọn oluwọde sọ iloro ti ijọba ipinlẹ Eko ti n gba owo ibode ni Lekki di ile, nitori ọpọ ninu wọn lo kọ lati pada sile wọn, bakab naa ni wọn sọ ibẹ di ile ijọsin lọjọ Isinmi.

Oríṣun àwòrán, @ajplus
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
IpinlẹOgun:
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ni ipinlẹ Ogun, awọn olufẹhonuhan korajọ si opopona marosẹ Eko si Ibadan, iyẹ loju ọna to lọ si Mowe ni ipinlẹ Ogun, ti wọn si n kọrin pe "Sọrọ soke" ati pe ki ijọba apapọ "End SARS."

Oríṣun àwòrán, @VoicingNG
Iwọde naa di ọna mọ awọn arinrinajo to n bọ lati Ibadan si ilu Eko, bakan naa ni ko si ọpna lati relọja lati Eko si Ibadan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3

Oríṣun àwòrán, @itz_chibuisky
Yatọ si eyii, awọn oluwọde tun gbọna ọfiisi gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiodun lọ lati sẹ ifẹhonuhan nibẹ.
Ipinlẹ Osun:
Lara iṣẹlẹ to lamilaaka ninu iwọde End SARS ni eyii to waye ni ilu Osogbo lẹyin ti gomina ipoinlẹ naa, Gboyega Oyetola yọju si awọn oluwọde naa, ṣugbọn ti awọn janduku kan ṣekọlu sii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Ipinlẹ Ondo:
Bakan naa ni ọmọ sori nilu Akure tori se ni awọn oluwọde ọhun gbe idi dana lawọn opopona nlanla nipinlẹ Ondo, ti ko si si lilọ bibọ ọkọ ati ero.

Ni ti awọn eeyan ilu Akure, adura ni wọn fi iwọse wọn ṣe ni bi wọn pe ipade adura lati fi ifẹhonuhan.

Oríṣun àwòrán, @CAPT__Vincent
Ọgangan iwaju ọfisi gomina ipinlẹ ọhun, Rotimi Akeredolu ni wọn patẹ eto adura naa si, ti wọn si n ke pe Eledua pe ko da si ọrọ Naijiria.
Yatọ si pe awọn naa gbadura, wọn tun ṣe iwọde kaakiri ilu Akure de agbegbe ọja NEPA, Alagbaka, olu ileeṣẹ ọlọpaa ni ọna Igbatoro, ati bẹẹbẹẹ lọ.

bakan naa ni awọn eeyan to n fi ẹhonu han yii tun gbe apẹ kana loju popo, ti wn si n se ounjẹ lọ lai bikita.
Ipinlẹ Kwara:

Oríṣun àwòrán, @TheLonerMan
Orita Challenge ni awọn oluwọde End SARS fi ipade wọn si ni ilu Ilorin, bakan naa ni wọn tun gbe iwọde naa de Tanke Tipper Garage, ki wọn to fi abọ si ile ijọba ipinlẹ ọhun.
Iroyin kan tilẹ sọ pe awọn eeyan naa di oju ọna to bẹẹ ti gomina Abdulrahman Abdulrazaq fi gbe alupupu lọ ile rẹ.
₦500m lóṣù nìjọba Eko ń pa tẹ́lẹ̀ lọ́nà márosẹ̀ Lekki-Epe

Oríṣun àwòrán, @TheLazyCheff
O kere tan, ọjilenigba din mẹfa miliọnu naira ni ijọba ipinlẹ Eko ti padanu nitori awọn ẹnu iloro ti wọn ti n gba owo ibode to di titipa, lati igba ti iwọde End SARS bẹrẹ.
Gẹgẹ bi abọ iwadii ti ileeṣẹ to n ṣakoso awọn ẹnu ibode naa, Lekki Concession Company, LLC, gbe jade, amọ ijọba Eko ṣi n pa owo lori awọn ipolowo ọja to wa lori awọn iloro ọhun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Buhari, ìwọ́de yóò yíwọ́, tó gbá jẹ́ káwọn ológun bá bẹ̀rẹ̀ ‘Operation Crocodile Smile’ "
- Bí o bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tí yóò rọ́pò SARS, wo àmúyẹ tí o gbọ́dọ̀ ní
- Aisha Buhari polongo àwo orin tó ní Nàíjíríà ń ṣun ẹ̀jẹ̀ lásìkò ìwọ́de
- Lizzy Anjorin ń kiri àgọ́ ọlọ́pàá láti gba ọ̀dọ́ afẹ̀hónúhàn, tó wà láhàámọ́ sílẹ̀
- 2015 ni mo ti ń kígbe pé gudugbẹ̀ máa já ní Nàíjíríà - Oyedepo
- Wo ohun tí ìwọ́de ENDSARS ṣé fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ ṣèdánwò NECO
- Láàrin wákàtí mẹ́ta, wọ́n dá ₦4m fún àkàndá ẹ̀dá tó kópa nínú ìwọ́de
Ọkan lara awọn kọmiṣọna ipinlẹ Eko, ti ko fẹ fi orukọ rẹ lede ni, o kere tan, ijọba n reti miliọnu mẹwaa naira lojumọ lori afara to so Lekki pọ mọ Ikoyi nikan ṣoṣo.

Oríṣun àwòrán, @Justapollion
Bakan naa ni iye ti Admiralty Circle Plaza, to wa loju ọna marosẹ Lekki-Epe maa n pa lojumọ kan, ko din ni miliọnu mẹrindinlogun naira.
Kọmiṣona naa fi kun pe, iye ti ijọba maa n ri lori afara Lekki-Ikoyi loṣu ko din ni ọọdunrun miliọnu naira, nigba ti oju ọna Lekki-Epe maa n pa nnkan bii ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira loṣu fun ijọba.
O ni "Ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọrin ọkọ to maa n gba ẹnu awọn iloro naa lojojumọ, ṣugbọn lati igba ti iwọde End SARS ti bẹrẹ, iloro naa ko pa owo kankan wọle mọ."
Nigba ti awọn akọrọyin kan si agbẹnusọ ileeṣẹ LLC, Veronica Jacob, o ni oun ko ni ọrọ kankan lati sọ nipa awọn iloro naa lọwọ yii.
O ti le ni ọsẹ kan ti awọn ọdọ kaakiri Naijiria ti gunle ifẹhonuhan, lori bi awọn oṣiṣẹ ẹka to n gbogun ti iwa idigunjale ni ileeṣẹ ọlọpa, SARS, ṣe pa awọn eeyan lọna aitọ.
Ifẹhonuhan naa ti mu ki ijọba apapọ tu ẹka ileeṣẹ ọlọpaa naa ka to si gbe omiran, SWAT, kalẹ, ṣugbọn ọdọ naa ni o ku nibọn n ro.
Oriṣiriṣi awọn gbajumọ ni Naijiria ati lawọn orilẹ-ede miran lagbaye lo ti n ṣegbe lẹyin iwọde ọhun.
Ìfẹ̀hónú gbọ̀nà míràn yọ ní Benin

Oríṣun àwòrán, royzkingin / Twitter
Ọna ara ni iwọde a ko fẹ ọlọpaa SARS mọ gbayọ lopopona marosẹ ilu Benin nipinlẹ Edo, nigba tawọn ọdọ di oju popo pa.
Awọn ọdọ to n se iwọde naa, ti oju wọn ko rẹrin rara, ni wọn gbarodan jọ siwaju ẹnu ọna abawọle fasiti Benin, to wa lopopona marosẹ Benin si Ore.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Afárá Marina àti Eko yóò di ṣíṣí padà lọ́la
- Wo àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Nàìjíríà àti l'Áfíríkà tó ń wólẹ̀ àdúrà kí Trump lè wọlé ìbò ààrẹ America
- Iléeṣẹ́ ológun bẹ̀rẹ̀ 'Operation Crocodile Smile' yíká Naijiria fún oṣù méjì
- Òkú tó jí lọ́jọ́ kejì ní mọ́ṣúárì padà kú síléèwòsàn
- Ṣé lóòtọ́ ni àjọ ọlọ́pàá dá Abayomi Shogunle àti Dolapo Badmus dúró?
Iyalẹnu lo wa jẹ pe opopona marosẹ ti wọn di pa yii, ni wọn gbe agbada kana si lati se irẹsi ati ọbẹ fun ounjẹ alẹ.

Oríṣun àwòrán, royzkingin / Twitter
Ara ọna tawọn ọdọ yii si n gba fi ẹhonu han ree lati tako ipo ti orilẹede Naijiria wa lọwọ lọwọ bayii.
Bakan naa ni wọn n se iwọde lati ke si ijọba pe ko fi opin si awọn ọlọpaa to n gbogun ti iwa idigunjale, taa mọ si SARS, ti wọn n yọ wọn lẹnu.

Oríṣun àwòrán, royzkingin / Twitter
Se lawọn ọdọ naa da ina igi soju popo naa, ti wsn si gbe apẹ kana, bẹẹ ni wọn fọ irẹsi nu soju titi naa.
Koda wọn din ẹran lati fi jẹ irẹsi jọlọfu ọhun, ti ohun gbogbo si n se yatayoto.

Oríṣun àwòrán, royzkingin / Twitter
Igbesẹ wọn naa fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ni opopona marosẹ Benin si Ore, tawọn ọlọkọ ko si le tẹsiwaju lẹnu irin ajo wọn naa.
Àwọn olùwọ́de ṣetán láti bá mínísítà FCT Abuja wọ̀ ṣòkòtò kan lórí àṣẹ má ṣe ìwọ̀de

Oríṣun àwòrán, @FCT
Aṣẹ ti Minisita olu ilẹ Naijiria, Mallam Mohammed Bello pa ti mu ki awọn oluwode bẹnu atẹ lu u, t'awọn kan si ni awọn o kọ lati gbe e lọ si ile ẹjọ.
Lara awọn to tako àṣẹ rẹ yi la ti ri Aisha Yesufu, awọn agbẹjọro to fi mọ awọn ajafeto-omoniyan.
Àwọn oluwọde #EndSARS yii n ṣé iwọde lati pe fun iwogile ikọ ọlọpaa SARS ati pe ki ijọba fi iya to tọ jẹ awọn to ti ṣọṣẹ ibi fun ara ilu sẹyin.
Wọn si ni awọn ṣetan lati gbena woju Minisita Mohammed Bello lori aṣẹ to pa ki wọn máa ṣe iwọde.Gege bi wọn ti ṣe sọ,wọn ni ko le di awọn lọwọ lati ma se iwọde.
Bẹẹ naa lawọn ẹgbẹ ajafeto-omoniyan kan ati awọn agbẹjọro bẹnu àtẹ lu igbesẹ yi, pe minista fun FCT ni Abuja to jẹ olu ilu Naijiria ko ni agbara aṣẹ lati sọ pe ki iwọde ma wa nitori pe ẹtọ ọmọ Naijiria ni.
Wọn ní otubante ni aṣẹ yi jẹ ti ko si ba ofin Naijiria mu.
- Ohun tí ojú ìyàwó mi rí lọ́wọ́ SARS kò ṣe é fẹnusọ- Poju Oyemade
- Wo ìsọ̀rí àwọn tó jẹ́ kí ìwọ́de End SARS / end SWAT lárinrin àti ìtumọ̀
- Ajínigbé tú ìyá àti ọmọ ọdún mẹ́ta sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ₦1.2 mílíọ́nù owó ìtanràn
- Ìjọba Nàìjíríà ti gbà láti san N30b owó àjẹmọ́nú fún ASUU
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
Ẹwẹ agbarijopo ẹgbẹ àwọn Gomina ariwa Naijiria ti ni awọn ko lodi si ikọ SARS.
Gomina ipinle Plateau to tun je alaga ẹgbẹ naa lasiko to n ba awon akọroyin sọrọ nilẹ ijoba ni SAR Swulo fawọn nipa kikoju ipenija aabo ni Ariwa Naijiria.
Wọn de ọrọ yi lade pẹlu atejade kan leyin Ipade to waye ni ọjọru pe gboyin gboyin lawọn wa lẹyin oga ọlọpaa lati se atunto ileesẹ ọlọpaa.
- A ti yanjú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ agbépo tó dànù lágbègbè AIT, Alagbado - LASEMA
- Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram
- Ìdí táwọn olùwọ́de EndSARS fi kọ oúnjẹ àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí MC Oluomo gbé wá rèé
- Wo nọ́mbà tí o le è pè láti gba owó gbà-má-bínú tí ọlọ́pàá bá fìyà jẹ ọ́ lọ́nà àìtọ́ l'Eko
- Wo ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí Gómìnà Obiano gbé lórí ọ̀rọ̀ SARS ní Anambra
Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ?
#EndSARS: Àwọn olùwọ́de kọ etí ikún sí àṣẹ ijọba, wọ́n tẹ̀sìwájú ìwọ́de l'Abuja
SARS Nigeria: Àwọn olùwọ́de kọ etí ikún sí àṣẹ ijọba, wọ́n tẹ̀sìwájú ìwọ́de l'Abuja
Awọn oluwọde #EndSARS kọ eti ikun aṣẹ ijọba ilu Abuja to fofin de iwọde nitori itankalẹ aarun coronavirus.
Niṣe ni ọgọọrọ awọn olufẹhonuhan bọ soju oju ti wọn si tẹsiwaju pẹlu ifẹhonuhan wọn.
Koda wọn tun gbe iwọde wọn lọ si iwaju ile igbimọ aṣofin agba niluu Abuja.
- Ẹ̀yin olùwọ́de, ẹ lọ kọwọ́ ọmọ yín bọṣọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́...- iléeṣẹ́ ológun kìlọ̀
- Irọ́ ni pé wọ́n hú òkú Kolawole Gold lórí pẹpẹ ìjọ ọkọ mi- Bisola aya Sotitobire
- Ẹ wo èrò bìbà níbi ìwọ́de #EndSARS ní ìlú Ibadan
- Wo bí àwọn jàndùkú ṣe yabò àwọn olùwọ́de #ENDSARS ní Alausa l'Eko àti Abuja
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàfin Oyo táwọn èèyàn fi ń ki Alaafin ní mẹ́sàn án mẹ́wàá?
Awọn onimọto ko ti ẹ ri aaye kọja lagbegbe olu ile iṣẹ ijọba apapọ lẹyin tawọn oluwọde di ọna to wọ inu ibẹ lọ.
Ẹwẹ, ajọ FCTA to n ṣakoso ijọba olu ilu Naijiria, Abuja ti kọkọ fofin de iwọde ki wọde kaakiri ilu Abuja.
Igbesẹ yi waye lẹyin ti iwọde #EndSARS gbode kan kaakiri orilẹede Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Minisita ilu Abuja, Muhammad Bello sọ pe awọn oluwọde naa ko tẹle ilana coronavirus lo jẹ ki ajọ FCTA gbe igbesẹ yii.
- Kanye West, Ozil, Boyega, àti àwọn gbajúmọ̀ ilẹ̀ ilẹ̀ okèèrè tó ṣàtìlẹyìn fún ìpolongo #ENDSARS
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàfin Oyo táwọn èèyàn fi ń ki Alaafin ní mẹ́sàn án mẹ́wàá?
- Ṣé Èdùà dá ààtàn isó ni? Ọkùnrin kan tó yasó nínú ọkọ̀ Uber rí ẹ̀wọn he
- Àṣé àṣírí wà nínú Hijabu tí Aisha Yesufu ń wọ̀ lọ ìwọ́de
Ninu atẹjade ti ajọ FCTA fi sita lonii Ọjọbọ, ajọ naa ṣalaye pe lootọọ ni awọn ọmọ orilẹede Naijiria lẹtọ labẹ ofin lati ṣe iwọde wọọrọwọ lori ohun ti ko ba tẹ wọn lọrun.
Ajọ naa sọ pe ọna ti wọn n gba ṣe iwọde ọhun tako ilana ati dena itankalẹ aarun coronavirus bii itakete si ara ẹni.
Ajọ naa tun sọ pe ifẹhonuhan ti wọn n ṣe lori fopin si ọlọpaa SARS eyi ti ijọba ti fagile jẹ inilara fawọn ọmọ Naijiria mii.
Wo bí àwọn jàndùkú ṣe yabò àwọn olùwọ́de #ENDSARS ní Alausa l'Eko àti Abuja
Wahala ti waye laarin awọn oluwọde #ENDSARS nilu Abujaati awọn ọdọkunrin kan, ti ko faramọ iwọde to n lọ lọwọ.
Oju ọna olobiripo (roundabout) Berger to wa ni iṣẹlẹ naa ti waye, nibi ti awọn eeyan ti n wọde lati owurọ kutu.

Lasiko ti awọn oluwọde naa n pariwo ẹ fi opin si SARS, ati awọn nkan miran, ni awọn janduku naa ya de, ti wọn si bẹrẹ si ni kọlu wọn pẹlu àdá ati igi.
Koda, wọn ba awọn ọkọ kan jẹ, wọn si tun fọ kilaasi ọpọlọpọ ọkọ ti wọn ba nibi iwọde naa.
Awọn eeyan kan si tun farapa.
Bakan naa ni ọrọ ṣe ri ni agbegbe Alausa nilu Eko.

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe awọn janduku ti yabo awọn to n ṣe iwọde #ENDSARS ni ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Alausa.
Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi iwọde naa jabọ pe ada, okuta ati awọn nkan ija mii ni awọn janduku naa ko dani.
Bakan naa ni ẹnikan lara awọn to n ṣe iwọde farapa lasiko naa.
Ṣugbọn ṣa, awọn oluwọde naa pada le awọn janduku naa lọ.
Pásítọ̀ Sam Adeyemi ní kí àwọn ọ̀dọ́ lo ìfẹ̀họ̀núhàn #EndSARS lati fí tún gbogbo ohun tó bàjẹ́ ṣe ní Naijiria
Adari ijọ Daystar Christian Centre, Pasitọ Sam Adeyemi ti fi ohun rẹ si ifẹhọnuhan to n ja ranyin kaakiri lorilẹede Naijiria pẹlu asia #EndSARS.
Pasitọ Sam Adeyemi sọ ọrọ naa loju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.
Sam Adeyemi rọ aarẹ Muhammadu Buhari, awọn ajọ amuṣẹya, awọn aṣofin Ile Igbimọ Aṣofin, awọn gomina ati gbogbo awọn obi lati lo ifẹhọnuhan yii fun ohun rere.
- EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde
- Owó oṣù tuntun fáwọn olùkọ́ tí Buhari kéde yóò dá aáwọ̀ sílẹ̀- Wike
- Àfikún owó epo, owó iná àti owó orí VAT ló jẹ́ ká fowó kún tàríìfù DSTV- Ọ̀gá MultiChoice
- Kò gbọdọ̀ sí ìfẹ̀họ́núhàn EndSARS ní ìpínlẹ̀ Rivers - Gomina Wike
- Ẹfunsetan Aniwura, ọmọ Ẹ̀gbá tó di akíkanjú obìnrin nílẹ̀ Ibadan
Pasito Adeyemi ni: ''Ọdun mẹrindinlọgbọn si mẹtadinlọgbọn sẹyin ni awọn ti ṣe iru ifẹhọnuhan yii ri to si di ohun to jẹ ki eto oṣelu tiwantiwa jinlẹ de ibi to de loni ni Naijiria.''
''O fihan gbangba pe awọn ọdọ asiko yii ko ni tẹriba fun iwa agidi ti ijọba ma n lo pẹlu awọn eniyan nigbakan ri.''
Adari ijọ naa ni: ''Ni asiko yii, awọn eniyan ti gbọnju ti wọn si mọ ọna lati ja fun ẹtọ wọn ni ọna igbalode lorilẹede Naijiria.''
''Nibayii, iṣejọba to ba gbọ ti araalu nikan lo le ni aṣeyọri ni Naijiria, nitori awọn ọdọ ti gbọn bayii.''
- Mọ̀ sí i nípa díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí ikú wọn 'láti ọwọ́ ọlọ́pàá' milẹ̀ tìtì ní Nàìjíríà
- Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá
- Inú mi dùn sí iwọ́de EndSARS tàwọn ọdọ́ Nàìjíríà ń ṣè - Ooni Ogunwusi
- Àìbìkítà yíì gbọ́dọ̀ dópin, ìjọba gbọdọ̀ mú ẹ̀dùn ọkàn àwọn aráàlú lọ́kùnkúndùn- Agbẹjọ́rò Àgbà
- Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá
Adari ijọ Daystar Christian Centre, Pasitọ Sam Adeyemi fikun wi pe awọn ọlọpaa ni alakọja ti wọn dojukọ nitori aisan owo oṣu wọn deede lo mu ki awọn naa ma a ṣe aṣiṣe.
Bakan naa ni Pasitọ Sam Adeyemi rọ Aarẹ Buhari lati gbọ ohun ti awọn araalu sọ, ki o wọ ibi ti bata ti n ta wọn lẹsẹ, ki o si ṣe atunṣe.
Inú mi dùn sí iwọ́de EndSARS tàwọn ọdọ́ Nàìjíríà ń ṣè - Ooni Ogunwusi
Ọ̀ba Eniitan Ogunwusi Ọjaja II, Ooni Ile Ifẹ ti sọ pe wamu wamu loun wa lẹyin awọn ọdọ Naijiria lori iwọde ENDSARS to gbode.
Ori ade yi ni niṣe ni iwọde naa mu idunnu ati ayọ wa si ọkan oun nitori awọn ọdọ ti taju pẹlu ohun kan ati afojusun kan naa.

A ri ọrọ yi ka loju opo Twitter Ooni pẹlu ẹkunrẹrẹ alaye ati akawe oun to ṣẹlẹ ti o fi sọ bẹẹ.
Ooni ṣalaye pe irufẹ iriri tawọn ọdọ n koju lọdọ oṣiṣẹ SARS ti ṣẹlẹ si ọmọ bibi oun lobirin koda o fẹ ẹ padanu mi rẹ lọwọ wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 7
Oba Alaye yi ni ti iru eleyi fi le ṣẹlẹ si ọmọ oun, aimọye ọdọ ni iru rẹ yoo ti ṣẹlẹ si.
Ooni wa ni ibeerẹ ohun rẹrẹ ni Naijiria ni iṣẹlẹ yi jẹ fun ara ilu ati awọn ọlọpaa naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 8
Ooni ni oriade akọkọ ti yoo gbaruku ti awọn oluwọde ENDSARS ni Naijria lati igba to ti bẹrẹ ni nkan bi ọjọ marun un sẹyin.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Buhari
A ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni pẹ̀lú títú FSARS ká, àtúntò ọlọ́pàá ń bọ̀- Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọrọ fun igba akọkọ lati igba ti iwọde to n pe fun kika ikọ ọlọpaa FSARS kuro nilẹ ti bẹrẹ.
Ninu fọnran fidio ti aarẹ fi si oju opo rẹ ni Twitter, o ni atuntọ iṣẹ ọlọpaa n bọ lẹyin ti ijọba tu FSARS ka.
Bakan naa ni aarẹ ni ijọba ko ṣalai mọ nipa ohun to n ṣẹlẹ nitori naa ki ara ilu ṣe ṣuuru, atunto yoo waye.
- Wọ́n kò pa ẹnikẹ́ni sí ààfin Ṣọun Ogbomosọ, òkú tí àwọn ọdọ́ gbé wa ni ọlọ́pàá wọ́ jáde- Agbẹnusọ Ṣọ̀un
- Wo àwọn kọ̀ndísàn tuntun tí àwọn olùwọ́de #ENDSARS gbé jáde lẹ́yìn tí wọ́n tú SARS ká
- Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- Àìbìkítà yíì gbọ́dọ̀ dópin, ìjọba gbọdọ̀ mú ẹ̀dùn ọkàn àwọn aráàlú lọ́kùnkúndùn- Agbẹjọ́rò Àgbà
Buhari ni: ''Igbesẹ akọkọ ni pe a tu SARS ka lara ipinu wa lati mu atunto to gbooro ki awọn ọlọpaa baa le ṣe
Iṣẹ wọn to jẹ didaabo bo ẹmi ati ọna ijẹ ara ilu''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 9
Bẹẹ naa ni aarẹ ni gbogbo awọn to taṣẹ agẹrẹ sofin ni yoo foju wina ofin.
O tunbọ daro iku oluwọde to padanu ẹmi rẹ ni Ogbomosho nipinlẹ Oyo iyẹn Isiaq Jimoh.
- Ilé alájà mẹ́ta wó pa èèyan méje, èèyàn 20 farapa ní Obalende, Eko
- A máa ná N10.2 bílíọnù fi tún wáyà iná àti inú ilé Aso Rock ṣe- Buhari
- Tani Akeredolu tó wọlé láti tukọ̀ ìṣàkóso ípìnlẹ̀ Ondo lẹ́ẹ̀kejì yìí?
- Ààrẹ Buhari kí Akeredolu kú orííré bí ó ṣe jáwé olúborí nínú ìdìbò sípò gómínà
- Ìdí márùn ún tí agbára Covid 19 ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ kò fi tó tí àwọn ilẹ̀ àgbáyé míràn
Aarẹ ni oun ti paṣẹ ki iwadii bẹrẹ lati tọ piinpin iku to pa.
Kaakiri Naijiria ni iwọde ti n waye lọjọ keji ti ijọba lawọn tu ikọ ọlọpaa FSARS ka.
Ohun tawọn ọmọ Naijiria n sọ ni pe titu SARS ka nikan ko to bi kii ṣe pe ki ijọba ṣe atunto iṣẹ ọlọpaa.
Ariwo ''Executive Order'' lawọn eeyan n mu bẹnu pe ki aarẹ buwọlu aṣẹ ti yoo fofin de FSARS patapata.





















