EndSars, End SWAT, Nigeria protest: Buharii ní àkókò tó táwọn ọ̀dọ́ yóò fòpin sí ìwọ́de náà

Aa bUhari, ne Lawan ati nrebu Gbajabiamila n jomitoto

Oríṣun àwòrán, Senatengr

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Aarẹ Muhammadu Buhari ti n ba awọn aṣiwaju ile igbimọ aṣofin apapọ jiroro nibi ipade kan lori ipo ti Naijiria wa bayii.

Gẹgẹ ba ti gbọ, afojusun ipade ọsan ọjọ Isinmi naa ni lati wa nnkan ṣe sawọn ẹdun ọkan tawọn ọdọ to n sewọde gbe siwaju ijọba, eyi to da lori ọna lati dẹkun iwa kotọ awọn ọlọpaa.

Aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Ahmad Lawan pẹlu olori ile aṣofin-ṣoju, Fẹmi Gbajabiamila si lo n ba aarẹ se ipade naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amugbalẹgbẹ fun aarẹ Buhari lori ọrọ ibanisọrọ ori ayelujara, Bashir Ahmad lo fi eyi sita loju opo Twitter rẹ, @BashirAhmad.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ọ̀nà tí o lè gbà láti di ọjọ́ ogbó pẹ̀lú olólùfẹ́ rẹ

Lẹyin ipade naa, aarẹ ile aṣofin apapọ, Sẹnetọ Ahmad Lawan ṣalaye fun awọn akọroyin pe, ijọba apapọ ti tẹwọ gba gbogbo ẹhonu awọn ọdọ to n wọde naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

O fikun pe asiko to fun wọn lati dẹkun iwọde naa, ki wọn le fun ijọba lanfani ati aaye lati mojuto awọn ẹhonu ti wọn gbe kalẹ.

Ẹ foríjìn wá ọmọ Nàìjíríà, mó mọ̀ pé ẹ̀ ń bínú tórí a kò tètè gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ EndSARS- Osinbajo

Ọjọgbọn Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Instagram/profosinbajo

Ẹyin ọmọ Naijiria ẹ jeburẹ o, ẹ forijin wa, lootọọ lo yẹ ki ijọba apapọ ti wa nkan ṣe si ọrọ awọn olufẹhonuhan lori ọlọpaa #EndSARS / End SWAT.

Igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinabjo lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi sita to si tun wa loju opo Twitter rẹ.

Ọjọgbọn Osinbajo ni ''mo mọ pe ẹ n binu, o si yẹ bẹẹ. O ye mi yekeyeke bi ọpọ ọdọ orilẹede ni inu wọn ko dun.''

''Ọpọ lo ro pe a ti dakẹ ju lọri ọrọ to wa nilẹ wi pe igbesẹ ijọba kudiẹ kaato. Wọn jare wa,'' Osinbajo lo sọ bẹẹ.

Igbakeji Aarẹ ni ''ọgọọrọ ọmọ Naijiria ni awọn ọlọpaa ti fi iya jẹ lọna aitọ, eyi ko si bofin mu.''

''Ojuṣe wa ni lati daabo bo awọn ọdọ papaa julọ lọwọ awọn ti ijọba n sanwo fun un lati daabo bo wọn,'' Ọjọgbọn Osinbajo lo woye bẹẹ.

Osinbajo gbagbọ pe iwọde #EndSARS to n lọwọ kaakiri orilẹede Naijiria ju ọrọ awọn ọlọpaa to n dunkoko mawọn ọdọ lọ nikan.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

O ṣalaye pe ijọba ti n ṣe ipade pẹlu awọn tọrọ kan lati ojutu si ohun tawọn ọdọ to n ṣe iwọde n beere fun.

''Emi fun ra mi ni alaga ipade pẹlu awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlọgbọn ati minisita olu ilu Naijiria, Abuja nibi ti a ti gbe igbimọ ti yoo ṣe iwadii iwa ika tawọn ọlọpaa #SARS ti hu.

Bakan naa ni igbakeji Aarẹ kẹdun pẹlu idile Jimoh Isiaq ti ibọn ọlọpaa pa niluu Ogbomoso atawọn mii naa to ti ba iwọde #EndSARS lọ.

Àkọlé fídíò, End SARS, End SWAT: Ó pé mi bí SARS kò ṣe sọ mí dolówọ́- Fulani Kwajafa

Mi ò mọ̀ nípa àwọn tọ́ọ̀gì tó da ìwọ́de EndSARS Alausa rú, mo ṣì wà lẹ́yìn yín digbí! - Sanwoolu

Ijọba ipinlẹ Eko ti ni oun ko lọwọ ninu idaru to waye nibi iwọde EndSARS to waye ni agbegbe Alausa ipinlẹ Eko.

Wọn si ni awọn kọ lawọn ṣe onigbọwọ awọn janduku to ṣaadede ya wọ ibẹ lati da iwọde ti awọn ọdọ n ṣe lodi si iwa aburu ti awọn ọlọpaa Naijiria n hu.

Kọmiṣọnna eto iroyin ni ipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso ninu atẹjade kan to fi sita ni ẹsun naa to n ja ranyin ranyin lori ayelujara jẹ ete awọn ọta lati ko nkan jọ lodi si ijọba.

Muhammed Adamu,gapaa Naijiria ati Gomina Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, twitter/babajide Sanwoolu

O ni, bẹẹ, ijọba ipinlẹ Eko lo ti n ṣa gbogbo ipa lati yanju iṣoro to wa nilẹ nipa gbigbaruku ti awọn ọdọ ninu akitiyan lati wa alaafia Naijiria.

Bakan naa gomina Babajide Sanwoolu fi si oju opo instgram pe oun ni imọlara ohun tawọn ọdọ n ja fun torinaa ko ṣeeṣe ki oun tun ran awọn janduku lati wa da iwọde wọn ru.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

"Mo bu ẹnu atẹ lu ikọlu to waye yii mi o si laye laye gbe lẹyin mọndaru ati iwa ipa si araalu".

Gomina Sanwoolu fi idaniloju han pe awọn ti y a ipinlẹ Eko sọtọ lati faaye gba awọn igbesẹ awọn oluwọde tori pe nkan to tọ ni wọn n ṣe.

Lowurọ ọjọbọ ọsẹ yii ni awọn janduku ti wọn dira pẹlu ohun ija ṣaadede yabo ibi ti awọn ọdọ ti n ṣe iwọde ni agbegbe Alausa ni Eko nibi to jẹ pe awọn ọdọ kan sun mọju niwaju ọfiisi gomina.

Àkọlé fídíò, Sotitobire: Ọkọ mi kò mọ̀ Jegede PDP rí, kódà kò fa ẹnikẹ́ni kalẹ̀ dípò Akeredolu- Bisola

Bi ẹ ko ba gbagbe, igba keji ree ti gomina Sanwoolu yoo yọju si awọn oluwọde koda o tun ba gbe patako soke.

Ati pe o tun diidi gbera lọ silu Abuja lati lọ jiṣẹ awọn ọdọ fun aarẹ to si gba esi bọ fun wọn.

Awọn oluwọde #ENDSARS

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian Army

Ẹ̀yin olùwọ́de, ẹ lọ kọwọ́ ọmọ yín bọṣọ, bí bẹ́ẹ̀ kọ́...- iléeṣẹ́ ológun kìlọ̀

Ẹ lọ ki ọwọ ọmọ bọ aṣọ, bii bẹẹ kọọ, ẹ o kan idin ninu iyọ. Bayii ni ileeṣẹ ọmọ-ogun ori ilẹ ṣe kilọ fawọn to n ṣe iwọde #EndSARS kaakiri Naijiria.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ologun ori ilẹ fi sita, wọn ni awọn sọja ṣetan lati lo gbogbo agbara wọn lati daabo bo ijọba awarawa orilẹede Naijiria.

Adele alukoro ile iṣẹ ologun Naijiria, Col Sagir Musa, to fi atẹjade ọhun sita ṣalaye pe ileeṣẹ ologun wa lojufo lati rii pe alaafia jọba ni Naijiria ni gbogbo igba.

O sọ ninu atẹjade ọhun to fi si oju opo Facebook ileeṣẹ ologun ori ilẹ pe Aarẹ Muhammadu le fi ọkan tan awọn ọmọ-ogun Naijiria lọjọkọjọ.

Col Musa sọ pe awọn omogun oriilẹ Naijiria duro gbọingbọin lẹyin Aarẹ Buhari ati iwe ofin orilẹede Naijiria bakan naa.

Ileeṣẹ ologun wa rọ ẹnikẹni to ba fẹ da rogbodiyan silẹ tabi ṣe ohun kohun to le dunkoko mọ ijọba awarawa Naijiria pe ki wọn semẹdọ.

Adele alukoro ile iṣẹ ologun Naijiria tun rọ awọn ọmọ-ogun pe ki wọn wa lojufo lai bikita ohun tawọn to n da rogbodiyan silẹ n ṣe.

Àkọlé fídíò, End SARS, End SWAT: Ó pé mi bí SARS kò ṣe sọ mí dolówọ́- Fulani Kwajafa

Bakan naa nileeṣẹ ọmogun sọ fawọn araalu pe ki wọn fọkan balẹ, wọn ni awọn ṣetan lati daabo bo wọn.

Amọ yii ko ba ọpọ eeyan lara mu lori ayelujara.

@peterparne ni tiẹ sọ pe awọn meji lo n tako alaafia ati iṣọkan orilẹede Naijiria lẹyin to kọkọ ki wọn ku iṣẹ.

O ni ijọba fun ra rẹ ati ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram lo n tako alaafia orilẹede Naijiria.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ọpọ awọn ọdọ ti wọn lara awọn to n ṣe iwọde ni wọn fesi pe alaafia lawọn n lepa, ati pe iwọde wọọrọwọ lawọn n ṣe.

Àkọlé fídíò, Eegunjobi Omotanbaje Ajobiewe- Èébú ní wọ́n kọ́kọ́ ń bù mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣà pípé ní

Wọn ni alaafia lawọn n lepa lo jẹ kawọn maa ṣe ifẹhọnuhan eyi ti ko lodi si ofin.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 5

Ẹ wo èrò bìbà níbi ìwọ́de #EndSARS ní ìlú Ibadan

Kaka ki ewe agbọn agbọn dẹ, niṣe lo n le koko si. Iwọde #EndSARS ti gberasọ niluu Ibadan naa lẹyin ti o ti mulẹ tan niluu Eko.

Opopona mọrosẹ agbegbe Iwo Road ni ilu Ibadan ti kun fọfọ fun ọgọrọ awọn ọdọ to n wọde tako ọlọpaa SARS.

Oluwode

Lilọbibọ ọkọ ti dawọ duro lati owurọ oni ọjọ kẹtala oṣu kẹwa ọdun 2020 yii.

BBC

Pupọ ninu awọn ero ọkọ lo n bọọlẹ ti wọn si n fi ẹsẹ wọn rin lọ si ibi ti ọkọ n gbewọn lọ.

Àkọlé fídíò, EndSars, EndSwat: Ọlọ́pàá ti fi ìbọn lù mí láyà rí torí mó ní 'extra tyre' méjì- afẹ́hònúh

Wọnyii ni awọn aworan bi iwọde #endSARS ṣe n lọ niluu Ibadan.

Oluwo jọgbọdọ Orunmila àti àwọn eeyan rẹ nibi iwọde #End Sars ati #Sarsmustend to n lọ lọwọ ni ilu Ibadan.

Awon oluwode
Awọn oluwọde #ENDSARS ni Ibadan
Àkọlé fídíò, coronavirus prevention badge update: Wo òótọ́ àti irọ́ tó wà nínú báàjì àyà náà
Awọn oluwọde #ENDSARS ni Ibadan
Oluwode
Awọn oluwọde #ENDSARS ni Ibadan

Oríṣun àwòrán, Empics

Àkọlé fídíò, EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde
Oluwode