Online child abuse: Ọlọ́pàá mú afurasí 31 tó ń dúnkokò máwọn ọmọdé lórí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Twitter/Metropolitan Police
Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Gẹẹsi ti mu afurasi mọkanlelọgbọn lori ẹsun idunkoko mọ awọn ọmọde lori ayelujara.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣi ti gba foonu atawọn ẹrọ kọmputa pẹlu awọn nkan mii to le ni ọdunrun un fun bi ọsẹ kan bayii.
Laarin ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹsan an ọdun 2020 yii si ọjọ kẹta oṣu kẹwaa ni ileeṣẹ ọlọpaa mu awọn afurasi ọhun niluu London.
- Bàbá ọlọ́mọ méjì fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin lò pọ̀; Adájọ́ rán an ní ẹ̀wọ̀n gbére
- Ọlọ́pàá méjì dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Akure lẹ́yìn tí wọ́n kúrò níbi tí Akeredolu ti gba ìwé-ẹ̀ri moyege
- Mo fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ mi- Baba ọmọ ti SARS pa
- Kíni ìyàtọ̀ tí yóò wà láàrin SARS àti SWAT?
- Àjọ DSS tú gbogbo pátá mi wò pé wọ́n ń wa ọmọ- Bisola aya Woli Alfa
- Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá
Ileeṣẹ ọlọpaa Met sọ pe awọn si n ṣe iwadii ọpọlọpọ ẹsun lilo iwa ipa lori awọn ọmọde nipa ṣiṣe ayẹwo foonu atawọn ẹrọ kọmputa ti wọn n lo.
Ọga ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, Helen Flanagan sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko beṣu bẹgba lati rii wi pe awọn daabo bo awọn araalu.
O rọ awọn obi atawọn ọdọ lati wa lojufo lori awọn ọna tawọn ọdaran kan fi n ṣakoba fawọn araalu lori ayelujara.
- Wo ìdí tí Tẹni, ọ̀dọ́mọdé olórin obìnrin kìí fi ń ṣí ìhòhò rẹ silẹ̀
- 'Mo jíṣẹ́ ẹ rán mi'! Sanwo-olu gbé ìwé ẹ̀dùn ọkàn olùwọ́de ENDSARS lé Buhari lọ́wọ́
- Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- Ẹ lo ìfẹ̀họ̀núhàn #EndSARS lati fí tún gbogbo ohun tó bàjẹ́ ṣe ní Naijiria- Pásítọ̀ Sam Adeyemi











