EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde

Àkọlé fídíò, EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde

" We are looking for answers" - Mr Macaroni

Iwọde ifẹhonuhan lori ọrọ ipaniyan ati ifiyajẹni awọn ọlọpaa Naijiria lọna aitọ lo bi iwọde to bẹrẹ ni Naijiria to ti n tan kaakiri awọn orilẹ-ede miran bayii

#End SARS ni wọn fi sọri iwọde naa.

Ni bayii ọpọ awọn gbajumọ lo ti darapọ mó awọn oluwọde pe o to gẹ.

Small doctor, Falz, Toyin Aimakhu, Wizkid, Tiwa Savage, Debo Macaroni atawọn miran gba Ibadan, Lekki, Ikeja, Agege ati bẹẹ bẹe lọ lati jẹ ki ijọba Naijiria mọ ohun to kan.

Aarẹ Buhari pada sọrọ pe ijọba oun ti fopin si awọn ọlọpaa kogberegbe SARS s\ugbon ko tẹ awọn eeyan lọrun.

Wọn ni igba karun un rẹ ti ijọba maa sọ bẹẹ ṣugbon ti ko mu ootọ dani.Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....

Awọn Obi ati ẹbi awọn ẹjẹ alaiṣẹ ti iku wọn ni ọwọ kan awọn ọlọpaa ninu naa n beere fun idajọ ododo lọwọ ijọba