EndSARS Protest: Àwọn olùwọ́de ní ''májèlè ni oúnjẹ tí MC Oluomo gbé wá fún wa, a ò jẹ''

Oríṣun àwòrán, Instagram/MC Oluomo
Awọn oluwọde fi ẹsun kan pe MC Oluomo lo ran awọn janduku to lọ ṣe ikọlu si awọn to n wọde ṣugbọn agbẹnusọ MC, Jimoh Buhari ni awọn ko mọ nkankan nipa ikọlu naa.
"A o lọwọ ninu ikọlu naa. Ki awọn eeyan yee naka ẹsun si wa lọna aitọ"
O ni "ṣe ẹwu NURTW lawọn janduku naa wọ ni? Ṣe MC Oluomo di ipo oṣelu kan mu ni? Ko lọwọ ninu iṣẹlẹ naa o".
- Ohun tí ojú ìyàwó mi rí lọ́wọ́ SARS kò ṣe é fẹnusọ- Poju Oyemade
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó fi ìyà jẹ àwọn olùwọ́de #EndSARS
- Ajínigbé tú ìyá àti ọmọ ọdún mẹ́ta sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ₦1.2 mílíọ́nù owó ìtanràn
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram
Ọsan ọjọ Ẹti ni wọn fi ọkọ ko ounjẹ naa lọ sibi iwọde Alausa.
Amọ, awọn oluwọde kan ti ko mọ ẹni to gbe ounjẹ ranṣẹ ti yara gba ounjẹ naa atohun mimu ti wọn si ti n da a si ọfun ki eeyan kan lara wọn to kigbe pe wọn lẹ orukọ mọ awọn abọ ounjẹ naa pe ọdọ MC Oluomo lo ti wa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ikede yii lo bi awọn oluwọde ninu ti wọn si n lẹ awọn abọ ati ike omi naa mọ ọkọ ti wọn fi gbe e wa pe majele ni ọga ẹgbẹ NURTW ko ranṣẹ si awọn.
O ti le lọsẹ kan ti awọn ọdọ jakejado ipinlẹ Eko ti awọn ọdọ ti n darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn kaakiri gbogbo ipinlẹ orilẹede Naijiria lati ja fun iwa ika latọdọ awọn ọlọpaa Naijiria ati fifopin si iṣekupani lọna aitọ to n ti ọwọ awọn ikọ agbofinro SARS wa.
.Lẹyin ti ijọba ni awọn ti gbọ ti wọn tu SARS ka, awọn ọdọ tun kọ lati dawọ iwọde duro.
Dipo bẹẹ wọn tun n tẹra mọ ọ sii ni paapaa bi ijọba ṣe fi ikọ SWAT dipo SARS.
Awọn oluwọde fi ẹsun kan pe MC Oluomo lo ran awọn janduku to lọ ṣe ikọlu si awọn to n wọde ṣugbọn agbẹnusọ MC, Jimoh Buhari ni awọn ko mọ nkankan nipa ikọlu naa.
"A o lọwọ ninu ikọlu naa. Ki awọn eeyan yee naka ẹsun si wa lọna aitọ"

Oríṣun àwòrán, @Govt of Nigeria
Mo kọ̀ láti kópa nínú ìpàdé orí ayélujára Nàìjíríà yìí- Falz
Lẹyin gbogbo iwọde lorisiirisi ati ọrọ #End Sars / End SWAT yii, Ileeṣẹ ijọba apapọ to n risi ọrọ awọn ọdọ pe ipade apero lori ayeluja.
Wọn kede pe Falana Folarin (Falz), Segalink, ati adari awọn ọlọpaa ni Naijiria, Adamu ati Joe Abbah.
Wọn ni ipade ori ayelujara naa yoo waye laago mẹta oni lori facebook.com/nigeriafmysd.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Bayii ni Folarin Falana, ọkan pataki lara awọn to n fọn rere ifopinsi #End Sars naa ti fesi pe oun ko ni kopa ninu eto naa.
- Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram
- Ẹ ṣọ́ra ní òpópónà AIT, ọkọ̀ agbépo kan ti yí dánù lọ́nà agbègbè Alagbado
- Wo àwọn ojúṣe àti èèwọ̀ fún ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ SARS
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó fi ìyà jẹ àwọn olùwọ́de #EndSARS
- Wo ìsọ̀rí àwọn tó jẹ́ kí ìwọ́de End SARS / end SWAT lárinrin àti ìtumọ̀
Falz ni irọ ni wọn fi bẹrẹ ijiroro lori ipade naa lati ibẹrẹ lori ohun ti wọn sọ fun oun.
O tun ni iru apero yii ko tilẹ nilo lasiko yii bikoṣe pe ki ijọba ṣe ohun ti awọn ọdọ Naijiria n ja fun.

Oríṣun àwòrán, PAstor Adeboye/twitter
Pásítọ̀ Enoch Adeboye darapọ̀ mọ̀ #ENDSARS, ó fún ìjọba Nàìjíríà ní ìmọ̀ràn ọ̀nà àbáyọ
Ìjọ RCCG nàá darapọ̀ mọ́ #ENDSARS
Ijọ The Redeemed Christian Church of God sọ pé bí àwọn ọlọ́pàá Nàìjíríà ṣe n tẹ ẹ́tọ́ ọmọnìyàn lójú kò dára.
Alufa Agba ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye naa ti darapọ mọ awọn ọdọ Naijiria to n polongo fun fifi opin si ọlọpaa SARS.

Oríṣun àwòrán, Falz àti ileeṣẹ ọlọpaa
Ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Twitter rẹ ati atẹjade to fi sita, Adeboye sọ pe ko si bi "awọn ọmọbinrin wa yoo sẹ maa sọ asọtẹlẹ, tabi awọn ọmọkunrin yoo ṣe ma a riran, ti a ko ba jẹ ki wọn o wa laaye"
- Háà, àṣé Pastor Adeboye kò léè dá èékánná ara rẹ̀ gé, àwọn ọmọ Nàìjíríà kan pariwo
- Wo bí àwọn jàndùkú ṣe yabò àwọn olùwọ́de #ENDSARS ní Alausa l'Eko àti Abuja
- Èèyàn 179 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní àrùn Coronavirus ní Nàìjíríà
- Nàìjíríà bá RCCG, ìyá Folu Adeboye yọ ayọ̀ 70
- RCCG: Pásítọ̀ Adeboye ṣáájú ìwọ́de àdúrà CAN lòdí sí ìpànìyàn ní Nàìjíríà
- Adeboye, ìmọ̀ràn rẹ láti dènà panṣágà tako àwọn obìnrin - Ọmọ Nàíjíríà
Bakan naa ni atẹjade ti ọkan lara awọn oluranlọwọ pataki rẹ, Pasitọ Johnson Odesola, fi sita lorukọ ijọ naa.
O ni RCCG da ara rẹ pọ mọ awọn ọmọ Naijiria to n ṣe iwọde lọwọlọwọ tako bi awọn ọlọpaa ṣe maa n fiya jẹ ni, ti wọn si n ṣi agbara wọn lo.

Oríṣun àwòrán, PAstor Adeboye/twitter
Pasitọ Odesola sọ pe o ṣe pataki fun ileeṣẹ ọlọpaa lati ma a ṣe atunto ojuṣe rẹ ni gbogbo igba ni ibamu pẹlu nkan ti ara ilu nilo.
O ni "ọpọ ẹmi alaiṣẹ lo ti ṣofo, nitori ọwọ lile ati ọna aitọ ti awọn ọlọpaa fi n ṣiṣẹ wọn.
O kesi ijọba pe kii ṣe atunto ileeṣẹ ọlọpaa nikan ni ko mojuto, o ni o pa dandan lati la oju awọn ọlọpaa si bo ṣe yẹ ki wọn o ma a ṣe iṣẹ wọn ni ilana igbalode.
"O ye ijọ wa daadaa, idi ti awọn eeyan fi yari, a si mọ riri ohun ti wọn n ṣe."
Odesola ni : "A faramọ titu ẹka ọlọpaa SARS ka, a si gba ẹka Special Weapons and Tactics, SWAT, ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ.
Ṣugbọn, a gbayin ni imọran pe ọrọ rẹ ko gbọdọ da bi igba ti a da ọti kikan, sinu igo tuntun."
Bakan naa lo rọ awọn ọdọ to n ṣe iwọde lati ṣe e ni ibamu pẹlu ofin Ọlọrun, ati ofin orilẹ-ede.
- Mo ṣèlérí láti ṣe ju ohun tí mo ti ṣe lọ fún ẹbí àwọn tó kú torí EndSARS - Seyi Makinde
- Bàbá ọlọ́mọ méjì fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin lò pọ̀; Adájọ́ rán an ní ẹ̀wọ̀n gbére
- Ọlọ́pàá mú afurasí 31 tó ń dúnkokò máwọn ọmọdé lórí ayélujára
- Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò NBA ti kéde pé àwọn yóò ṣojú awọn Olùwọ́de #EndSARS lọ́fẹ̀ẹ́ nílé ẹjọ́
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nibi ìwọ́de ENDSARS Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
'Mo jíṣẹ́ ẹ rán mi'! Sanwo-olu gbé ìwé ẹ̀dùn ọkàn olùwọ́de ENDSARS lé Buhari lọ́wọ́
Gẹgẹ bi ileri ti gomina ipinlẹ Eko ṣe fun awọn olufẹhonuhan nigba to lọ yọju siwọn, Babajide Sanwoolu ti mu iwe ẹdun ọkan awọn oluwde ti wọn fi ran an jiṣẹ fun aarẹ Buhari l'Abuja.
O fi sita loju opo Twitter pe aarẹ Buhari ti fọwọ si ṣiṣe agbekalẹ igbimọ awọn adari ilu lati maa bojuto gbogbo iṣẹlẹ iwa ipa tawọn ọlọpaa ba hu.
O sọ pe anfani iwọde to n waye yii yoo di ohun atipe oun yoo tẹsiwaju ninu iṣẹ lati daabo bo ẹtọ gbogbo awọn ara ipinlẹ Eko nigba kuugba ati lọjọkọjọ.
Bakan naa, gomina Sanwoolu ṣepade pẹlu ọga agba awọn ọlọpaa to si ni oun gbagbọ pe ipada de oun lati Abuja yoo so eso rere latu fopin si iwa ipa awọn ọlọpaa.

Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu
Kò sí Ààrẹ tàbí Gómìnà tó lè dá ìfẹ̀họ́núhàn àwọn Nàìjíríà lórí #EndSARS dúró- Monday Ubani
Agbẹjọro Agba lorilẹede Naijiria, Monday Ubani ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike to ni ki awọn eniyan ma fi ẹhọnuhan ni ipinlẹ naa.
Ubani lasiko to ba BBC sọrọ ni gomina Wike kuna patapata ninu ọrọ to sọ tako ifẹhọnuhan ti wọn n sọ.
O ni labẹ ofin, awọn ọmọ Naijiria ni aṣẹ lati fi ẹhọnuhan lai mu laisigbo dani.
- EndSARS protest in Nigeria: Mr Macaroni, Falz, Wizkid, Tiwa Savage àtàwọn míì ṣe ìwọde
- Owó oṣù tuntun fáwọn olùkọ́ tí Buhari kéde yóò dá aáwọ̀ sílẹ̀- Wike
- Àfikún owó epo, owó iná àti owó orí VAT ló jẹ́ ká fowó kún tàríìfù DSTV- Ọ̀gá MultiChoice
- Kò gbọdọ̀ sí ìfẹ̀họ́núhàn EndSARS ní ìpínlẹ̀ Rivers - Gomina Wike
Agbejọrọ agba Ubani salaye pe: ''Nitori eto iṣejọba tiwantiwa yii, eto awọn ọmọ Naijiria ni lati sọ wi pe awọn ko fẹ ohun ti ijọba n ṣe,
Etọ wọn ni lati sọ ohun ti wọn n fẹ, ki wọn si beere fun nkan tiwu wọn lọna to ba ofin mu.''
''Nitori naa ko si ijọba kankan lati ipo aarẹ to fi mọ gomina to le tako ẹtọ awọn eniyan lati beere fun ẹni ti wọn ba fẹ.''
Bakan naa, Agbẹjọro agba, Wahab Shittu fi lede pe gomina Wike n lo agbara ijọba ologun ni pẹlu bi o ṣe tako ifẹhọnu han awọn eniyan tako ipaniyan awọn ọlọpaa loore-koore.
''Agbẹjọro Shittu ni awọn ọdọ ni aṣẹ lati gba aṣẹ ni ileẹjọ tako ọrọ gomina Wike.''
''O ṣeni laanu wi pe Wike to jẹ agbẹjọro naa lo tun wa tako ofin to fun awọn eniyan laaye lati fi ẹhọnu wọn han ni Naijiria.''
Amọ, o rọ awọn eniyan lati maṣe jẹ ki ifẹhọnuhan naa da rogbodiyan, eleyii ti yoo wa mu ki ijọba paṣẹ pe wọn n da ilu ru.
- Mọ̀ sí i nípa díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí ikú wọn 'láti ọwọ́ ọlọ́pàá' milẹ̀ tìtì ní Nàìjíríà
- Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá
- Inú mi dùn sí iwọ́de EndSARS tàwọn ọdọ́ Nàìjíríà ń ṣè - Ooni Ogunwusi
- Àìbìkítà yíì gbọ́dọ̀ dópin, ìjọba gbọdọ̀ mú ẹ̀dùn ọkàn àwọn aráàlú lọ́kùnkúndùn- Agbẹjọ́rò Àgbà
Àìbìkítà yíì gbọ́dọ̀ dópin, ìjọba gbọdọ̀ mú ẹ̀dùn ọkàn àwọn aráàlú lọ́kùnkúndùn- Agbẹjọ́rò Àgbà
Agbẹjọro agba lorilẹ-ede Naijiria, Wahab Shittu ti kesi ijọba apapọ lati mu ibeere awọn ọmọ Naijiria lọkunkundun nitori awọn eeyan lo gbe wọn de ipo ti wọn wa loni.
Shittu sọ eyi lasiko to n sọrọ lori iyatọ to wa laarin ki ijọba kan kede pe awọn ti tu SARS ka, ati wi pe ki o di ofin lorilẹede Naijiria fun BBC.

Oríṣun àwòrán, YASUYOSHI CHIBA
O ni ijọba aarẹ Buhari kuna lati mu igbayegbadun ba awọn eniyan lasiko rẹ nitori wi pe ohun gbogbo lo nira fun wọn, paapaa pẹlu bii ikọ ọlọpaa SARS ṣe n dẹmi awọn ọdọ legbodo, ti ijọba ko si bikita.
- Abayọmi Aranmọlatẹ, Dr Laser: Vagino Plasty àti iṣẹ́ abẹ ẹwà Obìnrin ló jẹ mí lógún
- Wọ́n kò pa ẹnikẹ́ni sí ààfin Ṣọun Ogbomosọ, òkú tí àwọn ọdọ́ gbé wa ni ọlọ́pàá wọ́ jáde- Agbẹnusọ Ṣọ̀un
- Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- A máa ná N10.2 bílíọnù fi tún wáyà iná àti inú ilé Aso Rock ṣe- Buhari
Bakan naa lo fikun un wi pe ijọba gbọdọ ṣe ohun ti o tọ, ki awọn araalu ba lẹ ni igbẹkẹle ninu wọn, nitori awọn eniyan ko ni igbagbọ ninu ijọba Buhari mọ.
''Ikede yatọ si ki ijọba sọ da ofin nipa ki aarẹ Buhari buwọlu iwe ofin pe ko ni si ikọ ọlọpaa SARS mọ ni Niajiria.''
''Ti aarẹ Buhari ba buwọlu iwe ofin naa, eyi yoo mu ki awọn eniyan ni igbagbọ lori ijọba nipa ohun ti wọn sọ wi pe awọn yoo ṣe.''
- Ondo election 2020: Àwọn ara ìpínlẹ̀ Ondo ránṣẹ́ sí Akeredolu ohun ti wọ́n ń retí ní báyìí
- Tani Akeredolu tó wọlé láti tukọ̀ ìṣàkóso ípìnlẹ̀ Ondo lẹ́ẹ̀kejì yìí?
- Ààrẹ Buhari kí Akeredolu kú orííré bí ó ṣe jáwé olúborí nínú ìdìbò sípò gómínà
- Bí èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo se ń jáde rèé..
- Ìdí tí Gúúsù Akure, Owo àti ìwọ̀orun Ondo yóò fi sọ ẹni tí yóò jáwé olúborí nínú ìbò gómìnà Ondo
Agbẹjọro agba lorilẹ-ede Naijiria, Wahab Shittu naa wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati dẹwọ ifẹhọnu wọn, lati le fun ijọba laaye lati ṣe ohun to yẹ lori igbesẹ ti wọn kọkọ gbe lati tu ikọ SARS palẹ.
O ni: ''Ẹtọ awọn ọmọ Naijiria ni lati beere fun nkan ti wọn fẹ lọwọ ijọba, ki wọn si ṣe fun wọn.''
Gomina Kano tí ní kí olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ lọ rọ́kún nílé nítori o bu Ààrẹ Buhari lórí #EndSars
Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ti fi ọwọ osi juwe ile fun oluranlọwọ rẹ lori ọrọ iroyin, Salihu Yakassai lẹyin to bu aarẹ Buhari.

Oríṣun àwòrán, Google
Yakassai to fi lede loju opo Twitter rẹ pe aarẹ Buhari ko nifẹ araalu nitori naa ni ko ṣe sọrọ lori isekupani awọn eniyan lati ọwọ ọlọpaa.
Bi o tilẹ jẹpe aarẹ Buhari ti ba ọga ọlọpaa sọrọ, Yakassai nipe o yẹ ki aarẹ ba awọn araalu sọrọ loju koroju ni.
Yakassai ni '' N ko riru ijọba eleyii ri bi ti aarẹ Buhari ti ko ni oju aanu kankan fun awọn araalu
''Ni ọpọlọpọ igba ni awọn araalu n la iṣoro kọja, amọ aarẹ ko tilẹ ni ṣe bi ẹni wi pe oun ri wọn rara, eleyii buru jai.''
''Iwa aibikita aarẹ yii kọja bo ṣe yẹ lọ''
''Ki aarẹ sọrọ lori awọn iṣoro ti awọn araalu n la kọja ti ogun tabi oun ti awọn eniyan yoo ma bẹbẹ fun.''
''Lati igba de igba ni aarẹ Buhari kii le fi iṣẹju marun silẹ lati ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ ki ohun gbogbo si rọlẹ si, amọ nigba ti wọn fẹ ibo wọn, aarẹ Buhari kaakiri ipinlẹ mẹ̀rindinlogun to wa kaakiri orilẹede Naijiria.''

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dapo Abiodun
Ọlọ́pàá Ogun ti dá àwọn olùwọ́de #ENDSARS tí wọ́n mú lánàá sílẹ̀- Gómìnà Dapo Abiodun
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti mu awọn oluwọde #ENDSARS mẹtalelogun ni ilu Abeokuta tii ṣe olu ilu ipinlẹ naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Ogun, Abimbola Oyeyemi ṣalaye pe awọn agbofinro mu awọn oluwọde naa lẹyin ti ifẹhonuhan wọọrọwọ di afipa ṣe.
Oyeyemi sọ pe awọn oluwọde naa gbe ifẹhonuhan wọn debi ayẹyẹ Owu Day nibi ti wọn si ti fọ gilaasi ọkọ igbakeji gomina ipinlẹ Ogun, Amoju ẹrọ(Arabinrin)Noimot Salako -Oyedele.
- Gómìnà Seyi Makinde bá ẹbí Isiaq Jimoh tó kàgbákò ikú òjijì dárò
- Bí èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo se ń jáde rèé..
- Mọ̀ sí i nípa díẹ̀ lára àwọn èèyàn tí ikú wọn 'láti ọwọ́ ọlọ́pàá' milẹ̀ tìtì ní Nàìjíríà
- Ọ̀rẹ́ wa ni Lawrence jẹ́, àmọ́ ó gbẹ̀yìn dẹ́nu ìfẹ́ kọ abúrò wa - Joshua àti Damilola Bamiloye
- Ó sàn fún mi kí n máá tíì lọ́kọ báyìí ju kí n lọ́kọ ṣùgbọ́n...- Nkechi Blessing
Awọn to n fẹhonuhan ọhun yari pe awọn fẹ ri aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Oloye Olusegun Obasanjo to wa nibi ayẹyẹ Owu Day ti wọn n ṣe.
Awọn oluwọde naa kọkọ lọ si agbegbe Panseke niluu Abeokuta lati ibi ti wọn lọ kaakiri titi wọn fi de aafin Alake ti ilẹ Ẹgba, Oba Adedotun Gbadebo.
Awọn oluwọde ọhun tun gbe ifẹhonuhan wọn han de ọfiisi awọn ọlọpaa SARS to wa ni Magbọn nibi a gbọ wi pe awọn ọlọpaa ti yinbọn soke.
- Ẹni méjì kú, ọ̀pọ̀ dèrò ilé ìwòsàn níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní Okokomaiko nípínlẹ̀ Eko
- Duro Ladipọ, ìlúmọ̀ọ́ká òṣèré tíátà àti ọmọ àlúfà tí kò gbàgbé àṣà ìbílẹ̀
- Akeredolu ti mókè nínú ìbò gómìnà níjọba ìbílẹ̀ méjìlá l‘Ondo, PDP gba mẹ́ta
- Ìdí márùn ún tí agbára Covid 19 ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ kò fi tó tí àwọn ilẹ̀ àgbáyé míràn
- Ìdí tí ìjọba fi tú FSARS ká rèé!
Wo bí ìwọ́de #ENDSARS tí Toyin Abraham ṣe nípínlẹ̀ Oyo ṣe lọ
Gbajugbaja oṣere Nollywood, Toyin Abraham naa ti dari iwọde lati polongo pe ki ijọba orilẹ-ede Naijiria fi opin si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa SARS.
Eyi waye lẹyin ti awọn ọmọ Naijiria kan sọ oko eebu si Toyin lori ayelujara Twitter nitori bo sẹ polowo sinima rẹ, Fate of Alakada, lori Twitter lasiko ti iwọde #ENDSARS n gbona girigiri.

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham/instagram
Ninu fidio iwọde ti Toyin fi si ori ayelujara Instagram rẹ ni owurọ ọjọ Satide, o fojuhan pe ipinẹ Oyo ni iwọde naa ti waye.
Toyin Abraham àtàwọn ọ̀dọ́ sọ̀kò èèbú síra wọn torí ìwọ́de #EndSARS
"Ẹ dariji mi, mi o mọ tẹlẹ ni. Ẹ mọ pe mo nifẹ awọn ololufẹ mi, amọ ẹ le ba mi wi pẹlu ifẹ, lai ṣepe fun emi ati idile mi. Amọ, ko buru, ẹlẹran ara ni mi, mi o wà lai ni abuku."
Eyi ni esi ti gbajugbaja oṣere Nollywood, Toyin Abraham fọ, lẹyin ti awọn ololufẹ rẹ kan bu ẹnu atẹ lu bo ṣe polowo sinima rẹ, Fate of Alakada.
Lori ayelujara Twitter ni Toyin Abraham ti polowo sinima naa lowurọ ọjọ Ẹti, tawọn ọdọ si koro oju si igbesẹ naa tori iwọde a ko fẹ SARS mọ ti wọn n se.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Awọn eeyan naa sọ pe, kii ṣe lasiko ti iwọde n lọ kaakiri Naijiria, pe ki ijọba wọgile ẹka ileeṣẹ ọlọpaa, SARS, lo yẹ ki Toyin o polowo sinima naa.
- Toyin Abraham rèé, ọmọ ìpínlẹ̀ Edo tó di àràbà nínú tíátà Yorùbá
- Kemi Olunloyo dá sí ìjà Toyin Abraham àti Lizzy Anjorin
- Iyabo Ojo sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ abẹ tó ṣe, Nkechi Blessing ra ǹkan irinsẹ fún arọ
- Funke Akindele fún mi lówó tí mo fi gba ilé, kò ra ilé fún mi o - Ajirebi
- Tí òṣèré tíátà yóò fi kú, eré ni wọn yóò ló ń ṣe - Ibrahim Chatta
Diẹ lara ohun ti awọn eeyan naa sọ ni pe "ẹni to wa laye lo n wo sinima, ati pe o yẹ ki Toyin naa da si ọrọ #EndSars to n lọ lọwọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Bo tilẹ jẹ pe Toyin ti tuuba pe aimọkan lo faa, ati pe eeyan ẹlẹran ara ni oun, to si ti bẹrẹ si ni lo #EndSars loju opo Twitter rẹ, sibẹ eebu ni oun ati awọn ololufẹ rẹ kan ṣi n bu ara wọn lori ọrọ naa.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe agidi lo n fi n lo 'hashtag' naa, ni awọn kan n sọ pe, ko ti ọkan rẹ wa, pe ṣe karimi ni gbogbo rẹ.
Ṣugbọn oun naa si ti fesi pada pe, ki gan-an ni wọn fẹ ki oun ṣe? O ni "mi o lo #EndSars, ẹ bu mi, mo tun lo o, ẹ tun n kun sinu".
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Ko tan sibẹ o, bi awọn kan ṣe n sọ oko eebu ati epe lu Toyin, ni oun naa n fi ọrọ ranṣẹ si awọn obi wọn nile.
Mr Macaroni, Runtown darapọ̀ mọ́ ìfẹ̀hónúhàn ní Eko, Alausa lórí ìpolongo EndSARS
Lẹyin ti awọn ọdọ Naijiria kọwọ rin pẹlu gbajugbaja adẹrinpoṣonu, Debo Adebayo ti gbogbo eeyan mọ si Mr Macaroni sun soju titi mojumọ oni lori iwọde EndSARS, o tun ti fi ọrọ sita pe awọn ṣi wa nibẹ.
Àwọn ọmọ Naìjíríà yarí, wọn ni àfì dandan ki ìjọba gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ àwọn ọlọ́pàá SARS tó n fi ojoójómọ́ pa àwọn ọdọ́ ni orílẹ̀èdè yìí.
Láti ànà ti oníruurú àwọn ọ̀dọ́ ní ìpińlẹ̀ Eko àti jákèjádò àwọn ìpínlẹ̀ kan ni Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn, owúrọ òní ni àwọn míràn ṣẹ̀ṣẹ̀ lọ sí ilé wọ́n.
Lẹ́yìn ti ìwọ́de ti FALZ àti Runtown pè ti wọn sì fi àdàgbá ètò náà rọ síbì kan, tí olúkúlùkù sì gba ọ̀nà ilé wọ́n lọ láti fí orí lélẹ̀ ní gbájúgbajà adẹ́rìn pòsònú Debo Adebayo ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Mr Macaroni náà bẹ̀rẹ̀ tirẹ̀.
- Ọjọ́ ìdájọ́ déé! Wọ́n dájọ́ ikú nípa yíyẹgi fún David West tó ń pa àwọn obìnrin ní PortHarcourt lónìí
- Ẹ gbà mí o! Bí mo ṣe ń dàgbà ni ǹkan ọmọkùnrin mi ń tóbi síi àmọ́ obìnrin ni mi'
- Ó ti pẹ́ tí Fayose ti máa ń sọ̀sọkúsọ, ṣé ó mutí yó ni àbí ó mugbó? - Bode George
- Aya mi, dáríjìn mí fún bí n kò ṣe fi ìfẹ́ hàn sí ọ bó ṣe yẹ - Mike Bamiloye
- Wo owó tí Buhari bù fún ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan nínú ìṣúná ọdún 2021
- Kanu Ejike fipá bá ọmọ ọdún méje lò pọ̀ nínú sọ́ọ̀bù ìyàwó rẹ̀
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6
Macaroni dari àwọn ènìyàn míran láti wọde lọ sí Alausa tii ṣe ilé iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Eko.
Nínú àwọn fọ́nrán àti fọ́tò tó jẹyọ lojú òpó twitter rẹ̀, Mr Macaroni ni, ìròyìn tó tẹ òun lọ́wọ́ ni pé, àwọn ọlọ́pàá tún pa ẹnìkan ni ìpińlẹ̀ Delta níbí ti wọ́n ti ń ṣe ìwọ́de ENDSARS.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 7

End of X post, 8
Lẹ́yìn tí èyí wáye ní wọ́n ni àwọn ọdọ́ Delta náà yin ọlọ́pàá míràn níbọ̀n níbẹ̀ pẹ̀lú.
Mr Macaroni ní ìgbé ayé àlááfíà ni olúkúlùkù ń wá ti wọ́n fi jáde láti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de yìí, nítori náà kí gómìnà ìpińlẹ̀ Eko yọju si àwọn.
Nínú fọ́nrán tó jẹ́yọ lórí ayélujára ni ọgbẹni Debo Adebayọ, Mr Macaroni ti ń sọ̀rọ̀ pé bi Gómìnà ìpińlẹ̀ Eko, Babajide Sanwo-Olu ko ba le jáde, tí igbákeji rẹ̀ náà pẹ̀lú kò sí rí ààyè, ó di dandan ki abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣofin ìpílẹ̀ Eko yọju.
Ní ǹkan bi ago mẹ́rìn ìdáji òní ni àbẹnuga ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Mudashiru Obasa pada yọju sí wọ́n láti buwọ́lu ìwé ẹsùn ti wọ́n mú wá fún ìjọba.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 9

End of X post, 10

End of X post, 11
Lára àwọn gbájugbaja míràn ti kò sí ni ìlú gan náà to fi àtéjíṣẹ́ ránṣẹ́ ni Olamide, lórí twitter rẹ̀ ló ti ṣàlàyé pé gbágbágbá ni òun wà lẹ́yìn àwọn tó ń ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónú hàn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 12
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, Kayode Ogundamisi ní yàtọ si pé ìjọba kéde fífi òfin de ẹka SARS láti maa yẹ àwọn ènìyàn wò lójú pópó, àwọn ìgbésẹ míràn tí ó yẹ kí wọn gbé ni láti pé fún ìwádìí tó daju kí wọ́n sí pé gbogbo àwọn tí ọlọ́pàá yìí ti 'se ọṣẹ́ fún láti wa jẹri lóri amọ́hùmáwòràn ni ojú gbaara gbogbo aye.
O yẹ́ ki ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá san owó gbà mábínú fún ẹbi àti àwọn ènìyàn ti ọ̀rọ̀ náà kàn, bákan náà lo fi kun un pe o yẹ ki àwọn ọlọpàá bá awọn oluwọ́de sọ̀rọ̀ láti mọ ǹkan ti wọ́n ń fẹ́ kí orílẹ̀èdè le ni ìlọsíwájú.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 13
Ẹwẹ, awọn eniyan ko jẹ ki wọn ri ekuru ọrọ yii jẹ tan lawo o, ọpọ gbajugbaja naa lo ti n darapọ mọ ifẹhonuhan yii ti awọn mii naa si ti n gbero lati bẹrẹ.
Ilumọka olorin "Ọmọ Iya Tiṣa, Small Doctor" ti orukọ rẹ n jẹ Adekunle Temitope naa ti n gbaradi fun ifẹhonuhan to fẹ dari lonii, ọjọ Ẹti jọ kẹsan oṣu kẹwa ọdun 2020.