Otedola bridge fire: Ọkọ̀ akẹ́rù rí ìjánu rẹ̀ já ló kọlù ọkọ̀ agbépo tó fa ìjàmbá iná ní Otedola lópópónà Lagos-Ibadan- LASEMA

Oríṣun àwòrán, @LASEMA
Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri loju popo ni ipinlẹ Eko, LASEMA ti sọrọ lori ohun to ṣẹlẹ ninu ijmaba ina afara Ọtẹdọla.
Alaga ajọ naa, ọmọwe Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu lo fi soju opo ayelujara bi ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
O ni laago meji oru oni ni LASEMA gba ipe nipa ijamba ina naa lopopona Eko si Ibadan.
Leyin naa lo ni awọn Osise LASEMA dide si didẹwọ ina naa.
- Ẹ foríjìn wá ọmọ Nàìjíríà, mó mọ̀ pé ẹ̀ ń bínú tórí a kò tètè gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ EndSARS- Osinbajo
- Àwọn olùwọ́de ṣetán láti bá mínísítà FCT Abuja wọ̀ ṣòkòtò kan lórí àṣẹ má ṣe ìwọ̀de
- Tola Oyediran ọmọ Obafemi Awolowo ti jáde láyé
- Wo ìsọ̀rí àwọn tó jẹ́ kí ìwọ́de End SARS / end SWAT lárinrin àti ìtumọ̀
- Ohun tí ojú ìyàwó mi rí lọ́wọ́ SARS kò ṣe é fẹnusọ- Poju Oyemade
- Wo nọ́mbà tí o le è pè láti gba owó gbà-má-bínú tí ọlọ́pàá bá fìyà jẹ ọ́ lọ́nà àìtọ́ l'Eko
Ki lo fa ijamba ina naa?
Alaga ajọ LASEMA ṣalaye pe kete ti wọn de sibẹ ni wọn ri i pe ọkó akẹru to tobi to iwọn ogoji ẹsẹ bata to kun fun aṣọ oriṣiriṣi to n gbe lọ ni ijanu ọkọ rẹ ja.
Wọn ni eyi ṣẹlẹ lasiko ti ọkọ naa morile agbegbe Berger ni ijanu rẹ naa ja.

Oríṣun àwòrán, @LASEMA
Ọkọ akẹru yii lo wa lọ kọlu ọkọ agbepo bẹntiroo oni lita ẹlẹgbẹrun metalelọgbọn.
Bi wọn ṣe kọlura wọn yii lo jẹ ki ina sọ ti o si di ijamba naa.
Ajọ LASEMA, ẹṣọ oju popo, FRSC, ati LNSC naa ti tete de ibẹ lati mojuto iṣẹlẹ naa ko ma pọ ju bẹẹ lọ.
LASEMA ni ko si ẹni to ku ninu iṣẹlẹ naa ninu eyi ti wọn ti n dari awọn ọkọ ki wọn gba ọna Ọjọta tabi 7 Up lati din sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ku.
Wọn ni awọn ti gbe ajoku awọn ọkọ mejeeji kuro nibẹ.
Igbokegbodo ọkọ si ti n lọ bi o ti yẹ loju opopona Eko si Ibadan bayii
- Ajínigbé tú ìyá àti ọmọ ọdún mẹ́ta sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ₦1.2 mílíọ́nù owó ìtanràn
- Ìjọba Nàìjíríà ti gbà láti san N30b owó àjẹmọ́nú fún ASUU
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Cardi B ṣàlàyé ohun tó gbé fọ́tò ìhòhò rẹ̀ d'órí ayélujára Instagram
- Ìdí táwọn olùwọ́de EndSARS fi kọ oúnjẹ àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí MC Oluomo gbé wá rèé
- Wo ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí Gómìnà Obiano gbé lórí ọ̀rọ̀ SARS ní Anambra
Saaju laarọ oni ọjọ Satide:
Ọkọ̀ agbépo méjì gbiná ní orí afárá Otedola ní ìpínlẹ̀ Eko!
Tanker explosion on Otedola bridge: Ọkọ̀ agbépo gbiná ní orí afárá Otedola!
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe ko sẹni to tii le mọ iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa rin bayii

Oríṣun àwòrán, others
Ọkọ agbepo meji ti gbina lori afara Otedola ni agbegbe Berger ni ipinlẹ Eko ni idaji oni.
Laarọ kutu oni, ọjọ abamẹta, ọjọ ketadinlogun, oṣu kẹwaa ni iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ.
Ọpọlọpọ lo ti fi si oju opo twitter wọn ohun to n ṣẹlẹ ni afara Otedola bayii
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Wọn ni ọkọ agbepo mejeeji naa ni epo rọbi wa ninu wọn.
Titi di asiko yii, a ko tii le só ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ naa ati iye awọn ti iṣẹlẹ naa kan.
A o maa mu wa fun yin ohun to ba selẹ nibẹ......
Ki lo ti kọkọ ṣẹlẹ sẹyin?
A ti yanjú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ agbépo tó dànù lágbègbè AIT, Alagbado - LASEMA
Alagbado tanker overturned: Àjọ LASEMA láwọn ti yanjú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ agbépo tó dànù lágbègbè AIT, Alagbado
Oludari agba ajọ LASEMA ni awọn ti di gbogbo ibi ti iṣẹlẹ yii ti waye pẹluu kiki foomu ki iṣẹlẹ naa ma tun lọ bi omii.

Oríṣun àwòrán, Twitter/LASEMA
Iṣẹlẹ ọkọ agbepo to dawo ni agbegbe ibi ti ileeṣẹ amohunmaworan AIT wa ni Alagbado, ipinlẹ Eko ti ni iyanju bayii.Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA lo fi atẹjade sita pe awọn ti gbe ọkọ naa to gun to iwọn ẹsẹ bata ogun le awọn ọlọpaa lọwọ ki wọn maa ba iṣẹ lorii rẹ.Oludari agba ajọ LASEMA, Ọmọwe Olufemi Oke-Osayintolu ni awọn ti di gbogbo ibi ti iṣẹlẹ yii ti waye pẹluu kiki foomu ki iṣẹlẹ naa ma tun lọ bi omii.
- Ìdí táwọn olùwọ́de EndSARS fi kọ oúnjẹ àti ọtí ẹlẹ́rìndòdò tí MC Oluomo gbé wá rèé
- Ohun tí ojú ìyàwó mi rí lọ́wọ́ SARS kò ṣe é fẹnusọ- Poju Oyemade
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó fi ìyà jẹ àwọn olùwọ́de #EndSARS
- Ajínigbé tú ìyá àti ọmọ ọdún mẹ́ta sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ₦1.2 mílíọ́nù owó ìtanràn
Awọn ileeṣẹ mii to pawọpọ pẹlu ajọ LASEMA fun aṣeyọri iṣẹ naa ko ma baa pa awọn olugbe agbegbe naa lara ni ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko atawọn ọlọpaa.Nibayii, ohun gbogbo ti pada bọ sipo ti igbokegbodo ọkọ si ti bẹrẹ pada.
Ẹ ṣọ́ra ní òpópónà AIT, ọkọ̀ agbépo kan ti yí dánù lọ́nà agbègbè Alagbado
Ileeṣe to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA, ti kede pe ọkọ agbepo kan ti yi danu lagbegbe Alagbado ni Eko.
Wọn ni nọmba ọkọ agbepo to yi danu naa ni: LSROIXX.

Oríṣun àwòrán, @LASEMA
Ọkọ agbepo naa ni wọn ni o jẹ toni iwọn ogun ẹsẹ bata.
Ọmọwe Femi Damilola Oke-Osanyitolu to jẹ adari ajọ naa lo fi soju opo wọn.
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Wo àwọn ojúṣe àti èèwọ̀ fún ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ SARS
- Mi ò mọ̀ nípa àwọn tọ́ọ̀gì tó da ìwọ́de EndSARS Alausa rú, mo ṣì wà lẹ́yìn yín digbí! - Sanwoolu
- Ṣé Èdùà dá ààtàn isó ni? Ọkùnrin kan tó yasó nínú ọkọ̀ Uber rí ẹ̀wọn he
- Toyin Abraham tú àṣírí ohun tí ọlọ́pàá Náìjíríà sọ mọ́lẹ́bí rẹ̀ kan dà
Ajọ LASEMA ni o dabi pe awakọ agbepo naa n sare ni ko to ṣubo.
Titi di asiko ti iroyin yii n jade, epo inu rẹ ko tii maa danu si oju titi ṣugbọn LASEMA n kilọ fawọn eniyan agbegbe opopona AIT ni alagbado pe ki wọn ṣọra ṣe nibẹ.
Ati pe ki énikẹni ma ṣe da ina kankan lasiko yii nibẹ.

Oríṣun àwòrán, @LASEMA
- Ìjọba kéde ọjọ́ ìwọlé àwọn àgùnbánirọ̀ sí ìpàgọ́ lẹ́yìn Covid 19- Sunday Dare
- Àjọ elétò ìdìbò kéde ọjọ́ tí ìdìbò aàrẹ Nàìjíríà 2023 yóò wáyé
- Àbádòfin ìṣúná 2021 ré kọjá ìpele ìkejì nílé aṣòfin àgbà
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó fi ìyà jẹ àwọn olùwọ́de End Sars
- Wo ìsọ̀rí àwọn tó jẹ́ kí ìwọ́de End SARS / end SWAT lárinrin àti ìtumọ̀
Ṣaaju nibẹrẹ ọsẹ yii:
Ìjàmbá ọkọ̀ akérò àti tírélà pa èèyàn mẹ́rin lọ́nà mọ́rosẹ̀ Ore sí Benin
Ore-Benin Road accident: Ìjàmbá ọkọ̀ pa èèyàn mẹ́rin lọ́nà mọ́rosẹ̀ Ore sí Benin
Ọkọ akero ẹlẹni mẹrinla to n rinrin ajo lati ilu Eko lọ si Enugu ni a gbọ pe o lọ fori sọ ọkọ tirela laarọ ọjọ Iṣẹgun.

Oríṣun àwòrán, Faceboo/Frscedo Edo SEctor Command
Eeyan mẹrin lo dero ọrun ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lopopona Ọrẹ si ilu Benin ninu eyi ti awọn mẹrin miiran ti farapa.
Ọkọ akero ẹlẹni mẹrinla to n rinrin ajo lati ilu Eko lọ si Enugu ni a gbọ pe o lọ fori sọ ọkọ tirela laarọ ọjọ Iṣẹgun.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe tirela naa n lọri lọwọ ni ọkọ akero ọhun lọ kọ lu u lati ẹyin.
- Ọlọ́pàá méjì dèrò ọ̀run nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Akure lẹ́yìn tí wọ́n kúrò níbi tí Akeredolu ti gba ìwé-ẹ̀ri moyege
- Mo fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú tó pa ọmọ mi- Baba ọmọ ti SARS pa
- Kíni ìyàtọ̀ tí yóò wà láàrin SARS àti SWAT?
- Àjọ DSS tú gbogbo pátá mi wò pé wọ́n ń wa ọmọ- Bisola aya Woli Alfa
- Àwọn aṣòfín ní ìpínlẹ̀ Edo ti yọ Abẹnugan Ilé, Francis Okiye bí jìgá
- Inú mi dùn sí iwọ́de EndSARS tàwọn ọdọ́ Nàìjíríà ń ṣè - Ooni Ogunwusi
Oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC kan ṣalaye ere a-sa-ju ọkọ akero naa lo ṣokunfa ijamba ọkọ naa.
O ni ti ere rẹ ko ba pọju ni, o ṣeeṣe ki ijamba ọhun ma ṣẹlẹ.
Awọn mẹwaa lo mori bọ ninu ijamba naa nigba tawọn to farapa si n gba itọju nile iwosan.
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nibi ìwọ́de ENDSARS Nàìjíríà
- Ọlọ́pàá mú afurasí 31 tó ń dúnkokò máwọn ọmọdé lórí ayélujára
- Bàbá ọlọ́mọ méjì fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin lò pọ̀; Adájọ́ rán an ní ẹ̀wọ̀n gbére
- Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò NBA ti kéde pé àwọn yóò ṣojú awọn Olùwọ́de #EndSARS lọ́fẹ̀ẹ́ nílé ẹjọ́
- Ìwọ́de 'End SARS' lè tan àjàkálẹ̀ arùn coronavirus lẹ́ẹ̀kejì ní Nàìjíríà- Ọjọ̀gbọ́n Faduyile




















