ENDSARS, End SWAT: Gomina Obiano yọ ọ̀gá ikọ̀ SARS nípò

Oríṣun àwòrán, facebook Chief Willie Obiano
Gomina ipinle Anambra, Willie Obiano ti gba iṣẹ lọwọ James Nwafor to jẹ ọga awọn ọlọpaa SARS ni ipinlẹ naa to si ṣe ileri fun un pe yoo fimu ko ata ofin.
Gomina Obiano kede eyi lasiko to darapọ mọ awọn ọdọ to n ṣewọde tako iwa buruku awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Anambra.
O ni iyi nla lo jẹ fun oun layyi farapọ mọ awọn ọdọ yii lọna ati fi erongba wọn han ati pe oun yoo rii daju pe James Nwafor jẹjọ lẹyin to gba iṣẹ lọwọ rẹ.
Gomina Obiano ni oun ni lati gbaruku ti awọn ọdo naa nítori pe awọn gan ni igi leyin ọgba aṣeyọri oun nibi ibo.
- Ohun tí ojú ìyàwó mi rí lọ́wọ́ SARS kò ṣe é fẹnusọ- Poju Oyemade
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó fi ìyà jẹ àwọn olùwọ́de #EndSARS
- Wo ìsọ̀rí àwọn tó jẹ́ kí ìwọ́de End SARS / end SWAT lárinrin àti ìtumọ̀
- Ajínigbé tú ìyá àti ọmọ ọdún mẹ́ta sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ₦1.2 mílíọ́nù owó ìtanràn

Oríṣun àwòrán, @WillieObiano
Bakan naa lo kede ohun mẹta ti oun fẹ gbe ṣe lati ran awọn ọdọ ni ipinlẹ naa lọwọ ninu eyi to ni fifi James Nwafor jofin wa.
Akọkọ, ijọ apapọ ti tu ikọ SARS ka, ṣugbọn emi funra mi yo ṣe abẹwo sawọn ọfiisi SARS gnogbo to wa ni ipinlẹ Anambra lati rii daju pe wọn tu ẹnikẹni ti wọn ba fi sinu ahamọ silẹ.
"Ekejii, iṣẹ ti bọ lọwọ James Nwafor to jẹ olori iko SARS tẹlẹ ni Anambra, yoo si jẹjọ;
"Ẹkẹta, Nrii daju pe.ijọba apapọ gbe igbesẹ gnogbo to ba yẹ lati rii pe igbe aye idẹrun de ba awọn ọdọ ni ipinlẹ Anambra."
Abajade ipade Obiano pelu awọn ọdọ:
Lati gbe igbe aye idẹrun kalẹ ni ipinlẹ Anambra, Gomina Obano pinnu lati gbe igbimọ alakoyawọ kan kalẹ lati gbe awọn iwa kotọ to waye labẹ ikọ SARS ni ipinlẹ naa yewo.
Adajófẹyinti V.N. Umehi ni yoo jẹ alaga fun igbimọ naa ti yoo pari iṣẹ laarin ọgbọn ọjọ
Igbimọ naa yoo ni:
Aṣoju kan latodo egbe awon akekoọ.
Awon olori ọdọ lati eka idibo apapọ,
Agunbaniro kan,
Alaga ajọ ajafẹto araalu kan, alaga ehbe ọdọ ni ipinlẹ Anam ra
Aṣoju ẹka ọdọ lẹgbẹ Ohaneze,
Alaga ẹka ọdọ lẹgbẹ ilu gbogbo ni Anambra
Alaga egbe ọmọlẹyin Kristi, CAN ni ipinlẹ Anambra
Asoju biṣọọbu agba ijọ Anglican
Asoju Biṣọọbu agba ijọ Aguda,
Asoju ẹgbẹ ijọ emi mimọ PFN,
Asoju alaga igbimọ awọn lobaloba ni Anambra,
Agbejoro agba ni Anambra,
Kọmiṣonna fun ọrọ ọdọ awon meji to jere julọ ni igbimọ iṣejọba ipinlẹ naa.
Amugbalẹgbẹ fun gomina lori ọrọ aabo.














