Katsina kidnap: Ìyá àti ọmọ ọdún mẹ́ta gba òmìnira lọ́wọ́ ajínigbé lẹ́yìn tí wọ́n san ₦1.2 mílíọ́nù owó ìtanràn

Ajinigbe

Oríṣun àwòrán, @IAMSPonline

Iyawo Alhaji Aliyu Mai-Yadi Charanchi ati ọmọ rẹ ọmọ ọdun mẹta ti gba ominira lọwọ awọn ajinigbe to ji wọn gbe ni ipinlẹ Katsina.

Iṣelẹ naa waye ni ijọba ibilẹ Charanchi, ni ipinlẹ ọhun, ni aarọ ọjọ Iṣẹgun.

Awọn eeyan naa gba ominira lọwọ awọn ajinigbe naa lẹyin ti awọn ẹbi wọn san owo itanran ti ko din ni miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba naira.

Àkọlé fídíò, Sotitobire: Ọkọ mi kò mọ̀ Jegede PDP rí, kódà kò fa ẹnikẹ́ni kalẹ̀ dípò Akeredolu- Bisola

Gẹgẹ bi iwe iroyin abẹle Punch ṣe fidi ẹ mulẹ .

Ọkan lara awọn ẹbi wọn ti ko fẹ fi orukẹ rẹ lede sọ pe "₦1.2 miliọnu owo itanran ni a gbe lọ fun awọn ajinigbe naa lẹyin ti a ba wọn duna dura tan, ko pẹ si asiko naa ti wọn tu wọn silẹ."

Àkọlé fídíò, End SARS, End SWAT: Ó pé mi bí SARS kò ṣe sọ mí dolówọ́- Fulani Kwajafa

Bo tilẹ jẹ pe gbogbo akitiyan lati ba awọn ti ọrọ naa ṣelẹ si ati agbẹnusọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina sọrọ lo ja si pabo, awọn eeyan to n gbe ni agbegbe naa sọ pe isẹlẹ ọhun waye ni nnkan bii aago mejila abọ oru ọjọ Iṣẹgun.

Ṣugbọn awọn eeyan to n gbe ni agbegbe naa sọ pe isẹlẹ naa waye ni nnkan bii aago mejila abọ oru ọjọ Iṣẹgun.

Àkọlé fídíò, 'Owó tí mo ń rí lórí Garri ni mo fi ń ran ọkọ lọ́wọ́'

Iroyin ni ṣe awọn ajinigbe ọhun di ihamọra bi ẹni n lọ oju ogun ki wọn kọlu ile Alhaji naa, ti wọn si gbe iyawo ati ọmọ rẹ lọ.