EndSARS School Resumption: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè padà sílé ìwé láti ọjọ́ Ajé - Ìjọba ìpińlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Lagos state Govt/twitter
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde pé àwọn àkẹ́kọ̀ọ́ nílé ẹ̀ka ìjọba àti àládàni lé wọle pada sẹ́nu ékọ́ wọ́n láti ọja Aje, ọjọ́ keji, Osu kọkanla, ọdún 2020.
Kọmísọ́nà ètò ẹ̀kọ́ arábìnrin Folasade Adefisayo ló sọ èyí di mímọ̀ nínú àtẹ̀jáde kan to fọ́wọ́si lọ́jọ́bọ̀.
Àtéjáde náà to ka báyìí pé, " Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti buwọ́lu ki àwọn akẹ́kọ̀ọ́ padà sí ilé ìwé yálà nilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni tàbi aládàni jákèjádò ìpińlẹ̀ Eko lọ́jọ́ keji, Osu kọkanla, sùgbọn àwọn tó ń gbe ilé ìwé le wọle ni ọjọ́ Aiku, ọjọ kini oṣu Kọkanla.

Oríṣun àwòrán, Lagos state
- Mi ò ṣẹ̀ máa pín ǹkan lọ́wọ́ ara mi fún aráàlù, ilé mi gangan kọ́ ni wọ́n ti jí "Palliative" kó - Họ́nọ́rébù Agunbiade
- Báyìí ni 50 Kobo ṣe dá ìfẹ̀hónú "Ali Must go" sílẹ̀ tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ lọ
- Amy Coney Barrett di adajọ́ àgbà nílé ẹjọ́ tó ga jùlọ l'Amẹrika
- Àsìá tó ní àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ ọmọ wa la fẹ́ fún ìran tó ń bọ̀ - Tunde Bakare
- Ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ déé fáwọn ọmọ Ọlọ́pàá tó kú lásìkò EndSARS, Gómìnà Sanwo-Olu kéde
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti iléèwé pa nítorí ìwọ́de #EndSARS

Oríṣun àwòrán, @Sanwo Olu
Ijọba ipinlẹ Eko ti ti ileewe pa ti o si ti paṣẹ ki gbogbo awọn akẹkọọ ileewe ijọba ati ti aladani o fi idi mọle nitori wahala iwọde #ENDSARS to n lọ lọwọ.
Kọmiṣọna feto Ẹkọ, arabinrin Fọlaṣade Adefisayọ to kede eyi ni nitori abo ẹmi ati dukia awọn akẹkọọ , obi atawọn olukọ wọn ni wọn fi gbe igbesẹ yii.
O wa rọ awọn obi ati alagbatọ lati mojuto awọn ọmọ wọn ki wọn maa baa di ohun elo fawọn to lee fẹ sa asawọ wọ inu iwọde naa lati sọọ di ọna ati da rugudu silẹ lawujọ.
Bakan naa lo tun rọ awọn ileewe lati lo awọn ọna ikẹkọ ori ayelujara fi maa kọ awọn akẹkọọ wọn naa titi di igba ti wọn yoo fi kede ọjọ iwọle tuntun.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti kéde orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó fi ìyà jẹ àwọn olùwọ́de #EndSARS

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/twitter
Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti kede pe ọwọ ijọba ti tẹ diẹ lara awọn ọlọpaa to mu awọn oluwọde #EndSARS nipinlẹ Eko.
Awọn ọlọpaa naa ni Isipẹkitọ Bagou Michael, Isipẹkitọ Ekpoudom Etop, Sajẹnti Nnamdi Majura, ati Sajẹnti Akinyemi Benson.
Gomina sọ pe awọn ọlọpaa naa ti n koju igbimọ olubawi nileeṣẹ ọlọpaa ni kiakia., ati pe ijọba yoo mojuto igbẹjọ wọn.
- #EndSARS: Àwọn olùwọ́de kọ etí ikún sí àṣẹ ijọba, wọ́n tẹ̀sìwájú ìwọ́de l'Abuja
- Pásítọ̀ Enoch Adeboye darapọ̀ mọ̀ #ENDSARS, ó fún ìjọba Nàìjíríà ní ìmọ̀ràn ọ̀nà àbáyọ
- MC Oluọmọ gbé ara rẹ̀ ṣépè nítorí ìwọ́de #ENDSARS
- Wo àwọn ojúṣe àti èèwọ̀ fún ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tó gba iṣẹ́ lọ́wọ́ SARS
- Toyin Abraham tú àṣírí ohun tí ọlọ́pàá Náìjíríà sọ mọ́lẹ́bí rẹ̀ kan dà

Oríṣun àwòrán, @Sanwo Olu
Yatọ si eyi, Sanwo-Olu tun kede pe ijọba ti ṣeto miliọnu lọna igba Naira, lati fi tu awọn eeyan to kagbako ifiyajẹni lọwọ ọlọpaa, ati igbimọ oluwadii ti yoo ṣe amojuto rẹ.
Bakan naa lo sọ pe ijọba ti ṣiṣẹ lori awọn fidio ati aworan to jade sori ayelujara ni Ọjọbọ, eyi to safihan bi awọn janduku to kọlu awọn oluwọde kan ni Alausa, ṣe n sọkalẹ ninu ọkọ BRT to jẹ ti ijọba.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ọgbẹni Sanwo-Olu sọ pe awọn ri diẹ lara wọn tọka si, ti ileeṣẹ ọlọpaa yoo si tọpasẹ wọn de ibuba wọn lati ri i pe wọn jẹ iya ẹṣẹ wọn.
- Mọ̀ nípa iPhone 12, fóònù ológo 5G tí kìí lo "Charger” tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde
- Mi ò mọ̀ nípa àwọn tọ́ọ̀gì tó da ìwọ́de EndSARS Alausa rú, mo ṣì wà lẹ́yìn yín digbí! - Sanwoolu
- Àṣé àṣírí wà nínú Hijabu tí Aisha Yesufu ń wọ̀ lọ ìwọ́de
- Ṣé Èdùà dá ààtàn isó ni? Ọkùnrin kan tó yasó nínú ọkọ̀ Uber rí ẹ̀wọn he
- Kí ló ń ṣẹlẹ̀ láàfin Oyo táwọn èèyàn fi ń ki Alaafin ní mẹ́sàn án mẹ́wàá?

Oríṣun àwòrán, @Apata
Ẹgbẹ́ Agbẹjọ́rò NBA ti kéde pé àwọn yóò ṣojú awọn Olùwọ́de #EndSARS lọ́fẹ̀ẹ́ nílé ẹjọ́
Ẹgbẹ awọn agbẹjọrọ ni Naijiria ti a mọ si Nigerian Bar Association (NBA) ti kede pe awọn ṣetan lati pese iranl\woọ fun gbogbo oluwọde ti awọn agbofinro sọ si gbaga nitori iwọde #EndSARS.
Olumide Apata to jẹ Aarẹ ẹgbẹ naa lapapọ ni Naijiria lo kọkọ fi ikede yii sori ikanni ayelujara twitter rẹ ki ọpọ awọn agbẹjọrọ miran to maa tun ṣe ikede kan naa loju opo ibararẹnisọrọ wọn kaakiri.
O ni ọrọ iwa tani-o-mumi ti awọn ọlọpaa kogberegbe FSARS ti ijọba ṣẹṣẹ tuka yii kọja bẹẹ lori awọn iroyin to lu ayelujara pa lasiko yii.
Apata ni awọn ọlọpaa kogberegbe naa kii bọwọ fun ofin ibọwọ fun aabo awọn ara ilu.
- Ìwọ́de 'End SARS' lè tan àjàkálẹ̀ arùn coronavirus lẹ́ẹ̀kejì ní Nàìjíríà- Ọjọ̀gbọ́n Faduyile
- Owó oṣù tuntun fáwọn olùkọ́ tí Buhari kéde yóò dá aáwọ̀ sílẹ̀- Wike
- Wo ìgbà mẹ́rin tí ìjọba ti tú ikọ̀ ọlọ́pàá SARS ká sẹ̀yín ṣùgbọ́n....
- 'Mo jíṣẹ́ ẹ rán mi'! Sanwo-olu gbé ìwé ẹ̀dùn ọkàn olùwọ́de ENDSARS lé Buhari lọ́wọ́
Ni eyi to bi awọn iwọde ninu ojo ati ninu oorun yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Apata fidi ẹ mulẹ pe ẹgbẹ awọn agbẹjọro ti ṣetan lati ṣatilẹyin fun iwọde alaafia to n lọ lọwọ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Apata ni koda, ẹgbẹ NBA ti gbe igbesẹ pẹlu agbẹjọrọ agba awọn ipinlẹ bii Ogun, Eko ati Edo.
Apata ni NBA ṣetan lati ṣiṣẹ papọ fun idagbasoke Naijiria ati pe ki awọn eeyan le bọwọ fun ofin ati ẹtọ awọn ọmọ Naijiria.
- Wo ìdí tí Tẹni, ọ̀dọ́mọdé olórin obìnrin kìí fi ń ṣí ìhòhò rẹ silẹ̀
- Ẹ lo ìfẹ̀họ̀núhàn #EndSARS lati fí tún gbogbo ohun tó bàjẹ́ ṣe ní Naijiria- Pásítọ̀ Sam Adeyemi
- Ẹ wo èrò bìbà níbi ìwọ́de #EndSARS ní ìlú Ibadan
- Ẹfunsetan Aniwura, ọmọ Ẹ̀gbá tó di akíkanjú obìnrin nílẹ̀ Ibadan
- Kíni ìyàtọ̀ tí yóò wà láàrin SARS àti SWAT?















