Amy Coney Barrett di adajọ́ àgbà nílé ẹjọ́ tó ga jùlọ l'Amẹrika

Oríṣun àwòrán, EPA
Ile igbimọ aṣofin agba ilẹ Amẹrika ti buwọlu iyansipo adajọ Amy Coney Barrett gẹgẹ bí adajọ àgbà nile ẹjọ gigajulọ ilẹ náà.
Igbesẹ yìí ni awọn eeyan kan ti ri gẹgẹ bi aṣeyọri nla fun ìṣèjọba ààrẹ Donald Trump ni báyìí ti idibo sipo ààrẹ orílẹ̀-èdè náà kù ọsẹ kan.
Ibo awọn ọmọ ẹgbẹ Republican ti Ààrẹ Trump wa pọ jù ti ẹgbẹ Democrat ti Joe Biden wa lọ pẹlu ida mejilelaadọta, eyii to gbe adajọ Barrett wọlé.
To n tumọ sí pé, awọn ọmọ ẹgbẹ Republican to wa loke tente ni ẹka eto ìdájọ́ ilẹ Amẹrika ni gbongbo ju ti Democrat lọ.
Oludije sipo ààrẹ ninu ẹgbẹ Democrat, Joe Biden to sọ pé, bi wọn ṣe fa ọwọ Barrett soke ati bi wọn ṣe yan an sipo ni ọwọ mọdaru ninu.
Olori ẹgbẹ Democrat nile igbimọ aṣofin, Chuck Schumer ni tirẹ ni bi eto idibo naa ṣe waye laarin ọjọ perete sí idibo ààrẹ n ṣafihan pe igbẹkẹle àwọn ará ìlú ninu ẹgbẹ Republican to jọ wọn lójú.
Adajọ agba tuntun yii ni ẹni kẹta ti ààrẹ Trump yoo fa kalẹ lẹyin Neil Gorsuch lọdun 2017 ati Brett Kavanaugh ni 2018.
Ààrẹ Trump ti bura wọlé fún adajọ náà ni White House, to wa ni ilu Washington DC.













