Kíni Gómìnà Sanwo-Olu sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn Lekki tó ń mú awuyewuye wà lórí ayélujára?

Aworan Gomina Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Twitter/jidesanwoolu

Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ni ijọba apapọ ati ti ipinlẹ Eko yoo ṣapa lati ri pe ẹnikẹni to lọwọ si ipaniyan Lekki yoo foju wina ofin.

Sanwo-Olu fidi ọrọ yi mulẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin CNN lọjọ Aje.

O ṣalaye fun atọkun eto ''Connect the World'' iyẹn Becky Anderson pe awọn yoo fi fọnran fidio CCTV to ya iṣẹlẹ naa ṣọwọ si igbimọ iwadii.

Igba akọkọ ree ti Gomina Sanwo-Olu sọ ni pato pe lootọ lawọn ọmọ ogun yinbọn lu awọn oluwọde.

'' A o ri pe iwadii ẹkunrẹrẹ waye ta o si pe awọn to ba mọ nipa rẹ lẹjọ. Dajudaju, wọn yoo kawọ pọnyin rojọ. Gbogbo ipa la o ṣa lati rii pe wọn wa wi tẹnu wọn''

''Awọn eeyan sọ pe wọn pa ẹbi ati ọrẹ wọn. Nitori naa igbimọ iwadii yi yoo ko gbogbo ọrọ jọ ki a ba le ṣe atunṣe ati itanran to yẹ''

Bẹẹ naa lo ni oun ni igbagbọ pe iyipada rere ni yoo tẹle ohun to ṣẹlẹ lẹnu ọjọ mẹta yi.

''Mo nigbagbọ pe iyipada yoo waye fun idi meji.Akọkọ ni pe ohun to ṣẹlẹ paapa ni Eko kọja afẹnusọ.Ikeji ni pe o jẹ ipe fawa ijọba lati mọ ohun tawọn ọdọ fẹ kaṣe''

Loni ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwa ni igbimọ to n gbẹjọ ifiyajẹni lati ọdọ ikọ SARS yoo bẹrẹ ijoko wọn.

Yatọ si iwadii lori ọrọ SARS igbimọ naa yoo tọ pinipin iṣẹlẹ to waye ni Lekki ni ilu Eko nibi tawọn eeyan ti padanu ẹmi wọn.