Aláàfin ní tí kìí bá ṣe òṣèlú ni, Ìwó ló yẹ kó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, Oluwo's Palace
"Ogun ọdun akọkọ ti mo lo lori oye ko dẹrun rara, mo lee sọ pe ojumọ kan idamu kan ni".
Eyi ni ọro gbankọgbi ti Alaafin gbe kalẹ ni ilu Iwo lasiko to fi ṣe abẹwo si Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi nibẹ.
Alaafin, Ọba Lamidi Adeyẹmi III ni ojumọ kan wahala kan loun koju fun ogun ọdun akọkọ ti oun lo loye.
Alaafin Oyo, iku Baba Yeye, Ọba Lamidi Adeyẹmi III bẹ Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi wo ni aafin rẹ nilu Iwo.

Oríṣun àwòrán, Oluwo's palace

Oríṣun àwòrán, Oluwo's Palace
O ni asawọ oselu ninu aato ipo ọba ilẹ Yoruba kun ara ohun to n fa wahala ati edeaiyede laarin ilẹ Yoruba.
Ninu ọrọ rẹ, Alaafin ni kani ilana iṣẹṣe ati itan abalaye ni wọn tẹle ni, ilu Iwo lo yẹ ko jẹ olu ilu ipinlẹ Ọsun dipo Osogbo ti wọn fi ṣe olun ilu ipinlẹ Ọsun.
O ni idi ni pe, Baalẹ ni Ataọja ilu Oṣogbo ati Akirun ti ilu Ikirun nigba iwaṣẹ ki alaafin to wa gbe ade le wọn lori ati pe ni gbogbo asiko naa, Ọba alade ni Oluwo.
Ninu ọrọ rẹ, Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi kọminu lori aigbọraẹniye to n waye laarin awọn ọbalaye ni ilẹ Yoruba, pẹlu ipe si alaafin latinbẹrẹ igbesẹ iṣọkan awọn ọbalaye ki ilẹ Yoruba lee pada si ipo ọlanla rẹ lawujọ agbaye.
O sapejuwe Alaafin gẹgẹbi asiwaju ọbalaye ni ilẹ Yoruba ati lorilẹede Naijiria lapapọ, to si ni ọrọ ati iṣe rẹ ṣe pataki lasiko ti awujọ awọn lọbalọba n koju ipenija iṣọkan bayii.
Alaafin Adeyẹmi III, fi idi rẹ mulẹ pe lootọ iṣọkan ṣọwọn laarin awọn oriade atipe ko sohun meji to fa eyi ju wi pe awọn wọn ti ti oṣelu bọ gbigbe awọn ọba si akasọ to yẹ koowa wọn.
O fi da Oluwo loju pe oun yoo gbe igbesẹ lori ọrọ naa bi o ti tọ ati bi o ti yẹ.

Oríṣun àwòrán, Oluwo's Palace
Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti rọ ìjọba àpapọ ati awọn ìjọba ipinlẹ lati fi awọn Ọba alaye sinu igbimọ oluwadii ti wọn gbé kalẹ lori aṣemáṣe awọn ọlọpaa SARS.Oluwo lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan tó fi ṣọwọ́ sí BBC Yoruba.O ni yatọ sí Ileeṣẹ ọlọ́pàá, ààfin awọn ọba ti ori wọn pe, naa jẹ ọkan gbóògì lara ibi ti awọn èèyàn maa n fi ori pamọ́ sí ti wọn ba wa nínú ìṣòro, paapaa eyii to le la ẹmi lọ.Gẹgẹ bo ṣe sọ, òní "ṣiṣe eyii yóò mú kí àwọn Ọba alaye mọ ohun tó n lọ ati ohun ti awọn èèyàn n dojukọ, yóò sì tún gb'awọn láàyè lati ṣiṣẹ ipẹtu sí aawọ.
Ọba alaye naa sọ pé àwọn igbimọ ti wọn gbé kalẹ ni awọn ipinlẹ kan kò ni Ọba ninu, eyii ti ko yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.
- Báyìí ni 50 Kobo ṣe dá ìfẹ̀hónú "Ali Must go" sílẹ̀ tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ lọ
- Àṣírí tó ń bẹ láàrín Oluwo àtàwọn ọ̀dọ́ Iwo tí wọ́n fi fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ dáàbò bo ààfin rẹ̀
- N kò ni nkan kan sọ lórí fídíò to gba ayélujára kan pé mo ń we igbó, ẹ mú ẹnu kúrò nibẹ - Oluwo
- Èèwọ! Ọba aláde o gbọdọ kọ iyàwó rẹ̀ sílẹ̀- Bakare, Iba àṣà Yorùbá
- Àwọn afọbajẹ wọ́ Oluwo relé ẹjọ́, ìjọba Osun kò tíì fọùn
O ni ojúṣe ọba to mọ iṣẹ rẹ n'isẹ ni eto abo ilu to n jọba lé lórí.
Atẹjade ọhun tẹsiwaju pe, "ààfin ọba náà wà lára àwọn ibi tí wọn ṣe ikọlu sí nígbà rogbodiyan ifẹhonuhan EndSARS, nítorí náà ló ṣe ṣe pàtàkì kí àwọn Ọba lọwọ nínú ìgbìmọ̀ oluwadii ti ijọba gbe kalẹ."
Oluwo parí ọrọ rẹ pe, ki ijọba yan awọn Ọba sinu awọn igbimọ naa nitori iṣẹ ìlú láwọn n ṣe, ati pe awọn lọbalọba ṣetan lati gbé ìgbésẹ̀ ki àlàáfíà leè wa laarin ilu.
Àṣírí tó ń bẹ láàrín èmi àtàwọn ọ̀dọ́ Iwo tí wọ́n fi fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ dáàbò bo ààfin mi rèé
Ni ọjọ Satide ni iroyin kan pe awọn eeyan kan ti kọlu olu ileeṣẹ ijọba ibilẹ Iwo ti wọn si ba a jẹ kanlẹ.
Awọn eeyan wọnyi naa ni iroyin tun fi kun un pe wọn n gbero ati lọ kọlu aafin kabiyesi Oluwo eleyi ti wọn ni awọn araalu gbọ ti wọn si fariga pe ko ni ṣẹlẹ.
Lọgan ti awọn araalu hu ọrọ naa gbọ ni wọn ba sare bọ sita lọ di gbogbo ọna to de aafin ti wọn si duro ni igbaradi lati koju ẹnikẹni ti yoo ba loun yoo kọlu aafin naa ati kabiyesi wọn.
- Àwọn ọbá aláye ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún pẹ̀lú ọ̀pá àṣẹ wọn
- Eko, Kwara, Osun àtàwọn ìpínlẹ̀ míì tí àwọn èèyàn ti jí oúnjẹ ìrànwọ́ Covid-19 kó
- Wo ohun tí Fashola rí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate tó ń fa ariwo lórí ayélujara
- Ẹni tó jí ọ̀pá aṣẹ ń bọ̀ wá túbá fúnrarẹ̀, mo fi dáa yín lójú gẹ́gẹ́ bí ìyá - Erelu Kuti
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko tí kéde ìlànà ìséde tuntun fún ará ìlú
Ni gbogbo asiko yii, inu aafin ni Kabiyesi Oluwo wa ti o si ni, awọn 'ko mọ ohunkohun to n lọ nita'
Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Kabiyesi Oluwo ti ilu Iwo ṣalaye pe aṣiri to n bẹ laarin oun atawọn araalu Iwo ti wọn fi duro gba-gba-gba lati daabo bo ohun ko ju pe oun ti n sin wọn gẹgẹ bii baba ilu.
"Baba gbogbo ilu Iwo ni mo jẹ, Ẹẹmẹta lsẹ la n pin ounjẹ fawọn ti ko ni lati jẹ".
O ni awọn araalu Iwo fihan pe awọn mọ riri iṣẹ iranwọ, itọju ilu ati mimojuto igbayegbadun wọn ni wọn fi dide lati daabo bo oun ati aafin.
Kabiyesi, Ọba Akanbi Abdulrasheed ṣalaye pe iyatọ to wa laarin oun atawọn ọba alaye miran gbogbo ni pe oun ko ri ipo ọba gẹgẹ bi ipo lati jẹ gaaba le araalu lori tabi ko ọrọ ilu sabẹ, ṣugbọn oun ti lo asiko ti oun ti lo lori oye lati fi tan iṣoro araalu ati aini wọn.
Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn ọdọ ilu Eko ya bo aafin kabiyesi Ọba ilu Eko, Akiolu ti wọn si fọ aafin rẹ gbe awọn ohun iṣẹmbaye titi kan ọpa aṣẹ Ọba naa lọ.














