Oluwo Divorce: Olúwòó ilú Iwo: Èèwọ! Ọba aláde o gbọdọ kọ aya rẹ̀ sílẹ̀

Oluwo

Oríṣun àwòrán, Oluwo

Àkọlé àwòrán, Olúwòó ilú Iwo: Èèwọ! ọba aláde o gbọdọ kọ iyàwó rẹ̀ sílẹ̀
    • Author, Yemisi Oyedepo
    • Role, Broadcast Journalist

Láná òde yìí ní Oluwo ti ìlú Iwo nípínlẹ̀ Oṣun fi léde pé ìbásepọ̀ gẹ́gẹ́ bi lọ́kọláya tó wà láàrin òun àti ìyàwó rẹ̀ Chanel ti dé òpin nítori àwọn kùdìẹ̀-kudíẹ̀ kan ti ko ṣe pari Ọ̀rọ̀ èmi àti Olorì Chanel Chin kò yé ara wa mọ́ nínú ilé- Oluwo.

Chanel
Àkọlé àwòrán, Èèwọ! Ọba aláde o gbọdọ kọ iyàwó rẹ̀ sílẹ̀

Eyí ni Ọba aláde keji ti yóò kọ ìyàwo sílẹ̀ lori oye ní ilẹ̀ Yoruba.

BBC ṣewadìí àwọn ewu to rọ̀ mọ kí àwọn ba alade maa kọ ìyàwó silẹ̀ ni aafin.

Gẹ́gẹ́ bí Aarẹ àgò àṣà àti ìṣẹṣe Yoruba ní ìpínlẹ Osun àti Agbásàgà gbogbo ilẹ̀ Yoruba, Oloye Babatundre Bakare sàlàye pé èèwọ ni kí ba kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítori pé ní ilẹ̀ Yoruba gẹ́gẹ́ bi àṣà àti ìṣẹ̀ṣe Yoruba, kò si ẹni to gbọdọ gorí ìyàwó ti bá ba ti kọ sílẹ̀.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Oluwo ti Iwo Ọba AbdulRasheed Akanbi kí Aláàfin Ọyọ kú ọjọ́ ìbí

Ẹ̀wẹ̀, Iba àṣà wá fi kun un pé àwọn ǹkan to n ṣẹlẹ̀ láye òde òni ń ṣẹlẹ̀ nitori pé àwọn ènìyàn kò tèlé ìṣẹ̀ṣe Yoruba mọ, gbogbo ètùtu ti o yẹ ko wáye saaju ìgbéyawo ko wáye mọ, èyio sì ló mu kí olúkúlukù máa ṣ ǹkan to wù wọ́n.

Àkọlé fídíò, Silas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe

Bakare ní kò sí irú nkan ti o lé ṣẹlẹ̀ ti Ọba fi le kọ ìyàwó silẹ kóda ko ni àjẹ tabi kó tilẹ̀ ma ri ọmọ bi, Ọba ko ni ẹtọ láti kọ̀ọ́ silẹ̀.

Aarẹ aṣa: Ibeere nla ni pe ṣe Oluwo ṣe ohun gbogbo to yẹ ko too gori oye?

Sùgbọ́n ó ni gbogbo ètùtù ti wọ́n maa n ṣe láti so ìyàwó pọ mọ ẹmi àìrí ti yóò fi nira fun ẹnikẹni láti gun orí ìyawo Ọba (orisa).

Bakare ni gbogbo irú etutu bẹ́ẹ̀ kò si mọ, ti ọpọ awọn Ọba Alade isinyii ko ki n ṣe pe ni ọna to tọ ati ọna to yẹ, nítori náà o lé maa si ǹkan ti yóò tẹ̀yin ìgbésẹ̀ yìí jáde.

Ọba ti etutu rẹ ko ba ti pe, le kọ aya rẹ silẹ, ki ẹlomii si gori rẹ laisi ohunkohun ti yoo ṣẹlẹ, ṣugbọn ti o ba ṣe etutu pe, ko sọkunrun kankan to gbọdọ gori iyawo iru Ọba bẹẹ laijẹ iyan rẹ niṣu.

Iba aṣa Yoruba ṣalaye pe láye atijọ bi Ọba ba fẹ́ ọmọ ogun ọdun ti Ọba gbésẹ̀ kò si ẹnikẹni to láya láti fẹ́ ọmọbinrin náà, sùgbọ́n láye òde oni ọlaju ti de, eyi to ti pa ọ̀pọ àṣà rẹ́.

O ní lati igba ìwásẹ wọ́n maa n fi iyawo ta Ọba lọ́rẹ ni nítori náà o lé fẹ́ iye ìyàwó to ba wùú, nítori náà ìyàwo kò lẹ́tọ láti jowú nítori Ọba o jáde yóò si ṣaye.

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Oluwo Ìwo ṣ'àlàye lori oyé oba oni lawàni

Kíló de ti ìdílé fi ń daru nílẹ̀ Yoruba la'yé òde oní

Láye àtijọ, okùnrin kò lè dá obinrin fẹ́, bi kò ṣe larin òun àti àwọn ẹbi rẹ̀, tí o ba wá di pe ìjà fẹ́ wáye gbogbo àwọn àgbààgbà ni yóò dide láti dá síi.

Ati pe kò sí ǹkan to le de ba obinrin ti ọkọ yóò fi le e jáde, koda ko jẹ́ ajẹ tabi kó tilẹ̀ ya àgan kò le e kúrò nilé ọkọ rẹ̀ niwọn igba ti awọn ẹbi ba n fẹ tirẹ.

Bakare ni láye òdé oni iyáwo ti a ṣe ni ilé ẹjọ, ni ilé ijosin musulumi àti Kristeni ko ni ìgbàgbọ nínú ko si ǹkan ti yóò tẹyin rẹ̀ jáde ti tọkọtaya ba yẹ adehun ti wọ́n ṣe lọ́jọ́ ìgbéyawó.

Oloye Bakare ni ọ̀nà abayọ kan soso to wà ni pé ki ẹ̀yà Yoruba pada si ìdí ìṣèṣe nítori pé ninú ìṣẹ̀ṣe a ní adehun, ìbúra, ilérí, ìmùlẹ̀ àti majẹ̀mú

Awọn ǹkan wọ̀nyi ni kìí jẹ́ ki ìgbéyawó aye atijọ́ tú, ẹrù wà nínú àwọn ǹkan ìbúra bi wọ́n se n na Kurani àti Bibeli soke lai si iberu nibẹ, sùgbọ́n ninu iṣẹ̀ṣe ti wọ́n ti n fi omi àti ẹ̀jẹ̀ Bura kíàkíà si ni àwọn ọlọrun ǹkan wọ̀nyi ń pa ènìyàn nítori náà kò sí ẹni ti yóò fẹ́ taṣẹ̀ àgẹ̀rẹ̀

Láye òde oni kò si ẹni to lé ba ọkunrin tabi obinrin kankan mulẹ̀ mọ

Yatọ si eyi, ẹkọ ile, ifarada, amojukuro, ifẹ tootọ, ibọwọfun ara ẹni ati awọn iwa ọmọluwabi gbogbo laiyọ igbagbọ ninu iṣootọ nipasẹ oriṣa ti onikaluku n sin tun n jẹ ki igbeyawo awọn baba nla wa ko tọjọ ki wọn si jọ maa gbe ni alaafia.