Oyo FCC Bill: Ìjọba Ọyọ ní ẹni tí kò bá lẹ́bọ lẹrù, kò yẹ kò bẹ̀rù àjọ FCC

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Ọjọ́ Ajé ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde buwọlu abadofin kan láti ṣe àgbékalẹ̀ àjọ tó ń gbógun ti ìwà jẹgúdújẹra ni ìpínlẹ̀ Oyo, FCC.
Nínú ọ̀rọ̀ Gomina, ó ni àgbékalẹ̀ àjọ náà kìí ṣe láti gbógun ti ẹnikẹni bikose lati ri daju pe awọn eeyan ko akoyawọ ni gbogbo ileesẹ́ ati ẹka isejọba.
Sùgbọ́n, ó dàbi ẹgbẹ́ alátakò ni ìpínlẹ̀ Oyo kò rìií bẹ́ẹ̀.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
- Ìgbà Marún-un ti Aisha Buhari ti tako ìjọba Buhari
- Àwọn èsì yín tó ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìyanṣẹ́lódì ilẹeṣẹ́ mọ̀nàmọ́ná rèé
- Ìlé ẹjọ́ rọ Obalufe ti Ile Ife lóyè, wọ́n pàṣẹ́ fún Ọọ̀ni Adeyeye
- Kìí ṣe ìwà ọ̀lẹ ni bàwọn obìnrin ayé òde òní kìí ṣe dàra pọ̀ mọ àwọn olobinrin ilé
Lásìkò tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lórí ìgbésẹ̀ Makinde náà, Ayodeji Abass Aleshinloye to jẹ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Oyo sàlàyé pé, kò sí ǹkan ti gómìnà ń ṣe ju láti gbogun ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátakò nípínlẹ̀ Oyo.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, o ní "kò sí ìjọba kankan to le dún koko mọ àwọn, nítori pé, ti ijọba ba gbìyànju irú ẹ, ilé ẹjọ wà láti gbé ẹjọ náà lọ."
O tún mẹnu ba pé, gomina Makinde to ni Ajimobi fí ìdá ààdọrun owó iṣẹ́ ti a n gbé jade se ẹbun fún àwọn ènìyàn, ló tún tún iṣẹ́ òde náà gbé sita pẹ̀lú Bíliọnu mẹsàn àti miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹwa naira, lẹ́yin to sọ pé Bílíọnu meje ti pọju fún irú iṣẹ́ ode náà.
Alẹshinlọyẹ ni, "ibúwọlù àbádofin náà kìí ṣe nítori ìfẹ́ ará ìlú, sùgbọ́n ọ̀nà láti dún koko mọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alátako ni àti pe, òṣèlú lásàn ni Makinde ń se."

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Amọ sa, Kọmisọna fétò ìròyìn ni ìpínlẹ̀ Oyo, Wasiu Olatunbosun naa salaye fun BBC Yoruba pe Makinde ti kede pé àgbékalẹ̀ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ naa, kìí ṣe láti kó ẹnikẹni láyà jẹ, ẹni ti kò bá si lẹ́bọ lẹ́ru kò nílò láti maa fòyà lóri irú ǹkan bẹ́ẹ̀.
Olatunbosun ni "kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé ti ìrú àjọ bàyìí yóò di gbígbé kalẹ̀, àwọn ìpínlẹ̀ míràn náà ti dá irú ẹ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀, pàápàá jùlọ, Kano àti Kaduna àti pé, gomina funra rẹ setan láti gbé òfin máfọwọ́ kànmi ti gomina maa ń ni ti sẹ́gbẹ̀ kan, to ba huwa aitọ tàbi kówó jẹ."
Ọlatunbọsun wa n beere pe"Kíló de to fi jẹ́ pé ìgbà ti Seyi Makinde bẹ̀rẹ̀ ni ariwo yóò wá bẹ̀rẹ̀? Ipínlẹ̀ Oyo kàn n fẹ́ láti mọ bi wọ́n ṣe ná gbogbo owó rẹ̀ ni, gbogbo ẹni to ba wà lori ijoba lásìkò kan gbọdọ mọ bi a ṣe n ná owó náà"

Oríṣun àwòrán, Makinde
"Ti ìjọba to kọja ko bá lẹ́bọ lẹru, kò yẹ kí wọ́n bẹ̀ru, kìí sì ṣe pé àjọ náà yóò kan jòkó síbì kan láti sọ pé lágbàjá kówó jẹ, bí kò ṣe pé ọ̀rọ̀ náà yóò dé ilé ẹjọ láti fun olúkùlùkù lànfàni.
Lóri ti òpópònà Mọniya si Iseyin, Olatunbosun ni Seyi Makinde koro oju si isẹ naa, lẹ́yin àgbéjade iṣe ode náà, to yẹ ki wọ́n ṣe fun ọdun kan, ti wọn si gba bílíọnu meji naira fun, ko ni ojuutu kankan fun osu meje, ti wọ́n ko si ṣe kilomita kan ninu kilomita mẹtadinlọgọta.
Olatunbọsun ni ǹkan ti Seyi Makinde n ṣe ni oju agbara, eyi ti ijọba ana ko fi kun nkan ti wọn fẹ́ ṣe, sùgbọ́n ni bayìí, agbasẹse gbọdọ pari isẹ rẹ̀ láàrin ọdun kan lai ni ànfani owo miran titi ti yóò fi ṣe iṣẹ́ idá ọgọta iṣẹ́ náà.













