Arsenal vs Man City: Arsenal rìn lọ́jọ́ ebi ń pọ̀nà bọ́ sọ́wọ́ kìníhún Manchester City

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ Manchester City gbo ewuro soju ikọ Arsenal pẹlu ami ayo mẹta si odo ni papa iṣere Emirates.
Igba meji ọtọtọ ni Kevin De Bryne sọ bọọlu sinu awọn ikọ Arsenal ninu ifẹsẹwọn naa.
Goolu rẹ akọkọ waye ni iṣeju keji ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun bẹrẹ.
- Kamaru Usman, Ọmọ Naijiria f'ẹ̀ṣẹ́ gba ìgbànú ẹ̀yẹ mọ́ Covington lọ́wọ́ ní ìdíje UFC
- Ìdí tí Oluwo fi kọ Olorì rẹ̀ sílẹ̀ rèé
- 'IBB tẹ ń pariwo pé ó kú, kò kú o, Ko ko ko lara ọta ń le! - Agbẹnusọ Kassim
- Ó pé mi kí n kú jù kí n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ APC - Fani-Kayode
- China o, Nàìjíríà o, kò s'áyè òwò mọ́ ní Ghana! - Ààrẹ Akufo-Addo
Lẹyin igba diẹ sii ni Raheem Sterlin sọ goolu tirẹ sinu awọn Arsenal pẹlu iranlọwọ De Bryne yii kan naa.
Ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ ọhun ni Kelvin De Bruyne sọ goolu keji rẹ sinu awọn, eyii to mu goolu ikọ rẹ pe mẹta.
Aṣeyọri ikọ Manchester City ninu ifẹsẹwọnsẹ yii ti mu ki wọn sun si ipo kẹta lori tabili, ti Chelsea ati Tottenham si n tẹlẹ wọn lẹyin.









