Ibrahim Babangida: Buhari ní Nàìjíríà kò lè gbàgbé iṣẹ́ ribiribi tí IBB ṣe láéláé bí ó ti pé ẹni ọdún 79 lónìí

Ibrahim Babangida

Oríṣun àwòrán, Twitter/Presidency

Àkọlé àwòrán, Ọrọ lori orilẹede Naijiria

Aarẹ Muhammadu Buhari ti ki olori orilẹede Naijiria nigba kan ri, ajagun fẹyinti Ibrahim Badamosi Babangida ku ọjọ ibi ọdun kọkandinlọgọrin lonii ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹjọ.

Ninu atẹjade kan ti oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin, Femi Adesina fi sita loju opo Facebook rẹ, Buhari ni titi laelae ni orilẹede Naijiria yoo maa ṣe iranti iṣẹ ribiribi ti Babangida ṣe, nigba to fi wa lori aleefa.

Aarẹ Buhari wa gbadura pe ki Eleduwa tubọ fi okun, ilera to peye ati ẹmi gigun jinki olori orilẹede Naijiria tẹlẹ ri.

Bakan naa ni aarẹ ana orilẹede Naijiria, Gooluck Jonathan ṣe ṣadankata IBB, bi o ti pe ọdun mọkadinlọgọrin loke eepẹ.

Àkọlé fídíò, Blind DJ: Etu Omotayo kò ríran àmọ́ ó le to irinṣẹ́ eléré pọ̀ láti kọrin láì sí ìrànwọ́

Jonathan ni lai ṣe ani ani, Babangida ko ipa ribiribi ninu idagbasoke orilẹede Naijiria.

Jonathan wa gboṣuba rabandẹ fun IBB fun ifẹ nla to ni si Naijiria ati ipa rẹ lati rii pe orilẹede yii wa ni iṣọkan.

Jonathan tun gbadura ilera, alaafia ati ayọ fun Babangida bi o ti n sun mọ bebe ọgọrin ọdun.

Ibrahim Badamosi Babangida

Oríṣun àwòrán, Others

Ajagun fẹyinti Babangida jẹ aarẹ ologun orilẹede Naijiria laarin ọdun 1985 si 1993.

IBB tẹ ń pariwo pé ó kú, kò kú o, Ko ko lara ọta ń le- Agbẹnusọ Kassim

Bi ẹ ba ri bi Ọgagun Ibrahim Babangida ṣe n ṣe kébékébé pẹlu okun ara to dara lonii.

Ọpọlọpọ iroyin lo bẹrẹ si ni tan an kalẹ lonii wi pe IBB ti dagbere faye lowurọ oni ko da titi dori oju opo aṣewadi iroyin lagbaaye Wikipedia gan.

Aworan Ọgagun Ibrahim Babangida

Oríṣun àwòrán, Getty Images, Wikipedia

Àkọlé àwòrán, IBB tẹ ń pariwo pé ó kú, kò kú o, Ko ko lara ọta ń le- Agbẹnusọ Kassim

Ẹwẹ, agbẹnusọ ọgagun Babangida, Ọmọba Kassim Sule sọ fun BBC Yoruba wi pe bẹẹ naa lawọn ṣe ji lowurọ yii ti awọn n gbọ iroyin ẹlẹjẹ ọhun kaakiri.

O ni gbigbọ iroyin naa pa awọn lẹrin gidi gan, "o ya ni lẹnu ko si si ibọwọ fun ni kankan ninu iroyin naa".

Kassim ni ki awọn oniroyin ma baa ṣi awọn eniyan lọkan, oun ni lati fi ọrọ sita lati bu nu atẹ lu iroyin ofege yii pe irọ gbaa ni ohun ti wn n gbe kiri tori Babangida ko tii ku.

Ọrọ agbẹnusọ Ọgagun Babangida

"Kẹẹ si maa wo o, ni nkan bii ago mejila ọsan kọja iṣẹju mẹwaa ni IBB jade wa lati wa bẹrẹ si ni yọju si awọn alejo rẹ.

Ipo wo gan ni ilera Gbadamọsi Babangida wa lọwọlọwọ?

Nigba ti akọroyin BBC bere pe bawo gan an ni ilera ọgagun Babangida ṣe wa ni lọọlọ yii, agbẹnusọ rẹ fesi pe "ko ko ko lara ọta baba n le".

O ṣalaye pe ẹsẹ ti ọgagun Ibrahim Babangida fi pa lasiko ogun abẹle Naijiria nikan lo ṣi n dun un ṣugbọn eyi kan kun ọjọ ogbo lasan ni".

Àkọlé fídíò, Bi ìyàwọ mi ṣe n jábọ́ sí kọ́tà ló jẹ́ kí n kọ́ka fura pé kò ríran mọ́- ọkọ Dorcas

Kassim ni yatọ si eleyi, o ṣi n gun ori akasọ lọ sun si yara rẹ o si n sọkalẹ wa funrarẹ.

O ni o yani lẹnu iru iroyin ti awọn ileeṣẹ iroyin Naijiria maa n gbe kiri.

"Ko sohun to n jẹ pe o sun ko ji mọ o, ko sohun to n jẹ o sun o rẹ ara. Ojoojumọ lo n jade wa yọju si awọn eeyan".

"Bi ẹyin naa ba wa pẹlu rẹ bi a ṣe n sọrọ yii, yoo ya yin lẹnu bi ara rẹ ṣe le ko ko ko".

Àkọlé fídíò, Silas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe