Duncan Mighty: Ọlọ́pàá fi pampẹ́ mú olórín tàkasúfèé lórí ẹ̀sùn jíbítí mílíọ̀nù mọ́kànlá

Oríṣun àwòrán, @klassiQ2AT
Ajọ ọlọpaa ipinlẹ Imo ti fi pampẹ ofin mu gbajugbaja olorin takasufe Duncan Mighty, nipinlẹ ọhun lori ẹsun jibiti.
Alokoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Ikeokwu Godson Orland fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC.
O ni, kii ṣe pe wọn ji olorin ọhun gbe gẹgẹ bi iroyin ẹlẹjẹ ti awọn kan n gbe kiri lori itakun agbaye, ṣugbọn ahamọ ọlọpaa lo wa.
Ikeokwu ṣalaye pe wọn ko ṣẹkẹṣẹkẹ si Duncan Mighty lọwọ lẹyin to gba miliọnu mọkanla lọwọ ipinlẹ Imo fun iṣẹ orin ati awọn nnkan mii, ti ko si ṣe iṣe ọhun.
O ṣalaye pe olorin kan to ṣẹṣẹ n bọ, M2 lọ kọwe ẹsun ti wọn fi gbe e.
Ikeokwu tẹsiwaju pe wọn ti gbe Duncan Mighty ṣaaju akoko yii, to si jẹwọ pe lootọ ni oun gba owo naa.
Ọlọpaa sọ pe olorin ọhun ni oun ko lee da owo iṣẹ naa pada ayafi ti ijọba ipinlẹ Imo ba fagile adehun iṣẹ ọhun.
Agbẹmusọ ajọ ọlọpaa pari ọrọ rẹ pe, ijọba ti wọgile adehun iṣe naa ṣugbọn Duncan Mighty kọ lati da owo pada.
Eredi ree ti wọn ṣe fi ofin mu.













