Tanker Accident: Awakọ̀ dèrò ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí ọkọ̀ agbépo dànù L’eko

Ọkọ akepo to danu

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Àkọlé àwòrán, Ọga agba LASEMA Olufemi Damilola, sọ fun BBC pe, ọkọ ọhun ṣubu lẹyin ti ọkan lara taya rẹ fọ lojiji lori irin

Ileeṣẹ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọkọ agbepo kan ṣubu lulẹ ni agbegbe Victoria Island l'Eko, ti pupọ ninu epo to gbe, si danu.

Ọkọ agbepo naa, ni atẹjade lati ọwọ ọga agba ajọ LASEMA, Olufemi Ọsanyintolu, sọ pe o gbe jala ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn epo diisu, ṣugbọn to ṣubu lulẹ lasiko ti ọkan lara awọn taya rẹ fọ, ni adugbo Ozumba Mbadiwe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajọ LASEMA fidi rẹ mulẹ pe ṣe ni àgbá epo to wa lara ọkọ naa yọ danu, to si f'ori dolẹ, ti ìdá meji ninu mẹta epo diisu to gbe si tu danu saarin ọna.

Ọpọ awọn adoola ẹmi lati ileeṣẹ LASEMA, ajọ panapana ati awọn ileeṣẹ mii lo yabo ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye, lati wa ojutu si sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ to ṣẹyọ lẹyin iṣẹlẹ naa.

Nibayii, wọn ti gbe ọkọ naa to di oju ọna kuro laarin ọna, ti awakọ rẹ si ti di ero ileewosan.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Yorùbá foríkorí gbé ìwé tó lè sọ ẹ̀yà ara yín lédè Yorùbá.