Wo nkan tí o le ṣe láti ní iná ọba fún ọ̀pọ̀ wákàtí

Oríṣun àwòrán, other
Ileeṣẹ ijọba Naijiria to wa fun ọrọ ina mọnamọna ti gbe eto kan sita, eti ti yoo mu ki awọn ileeṣẹ to n pese ina ọba maa na ọja wọn taara pẹlu awọn to n lo ina.
Ninu eto tuntun yii, ti wọn pe ni "willing seller, willing buyer", awọn araalu to ni owo wọn lapo lati san lẹkunrẹrẹ fun ina, le wọ ọọfisi to n pese ina ọba, GenCos lati ra ina fun'ra wọn.
Eto yii yatọ si titẹlẹ to jẹ pe, awọn ileeṣẹ to n pin ina (DisCos) nikan lo n ta ina fun awọn onibàára.
Minisita fun ina mọnamọna, Sale Mamman sọ pe eto tuntun naa wa lati le ri ina fi pa mọ, ati lati le ran ileeṣẹ GenCos lọwọ lati maa ri owo ina ti wọn n pese pa wọle lẹkunrẹrẹ.
Ipinlẹ meji pere ṣi ni wọn ti n dan eto yi wo lọwọlọwọ ni Naijiria.
"Eto tuntun yii tumọ si pe, onìbàárà to ba n fẹ ina mọnamọna to dara, le lọ si ileeṣẹ DisCos tabi GenCos lati ra ina ni owo gege. Awọn to si n lo eto yii n lo ina mọnamọna fun bi ogun wakati lojumọ.
Bakan naa ninu ọrọ rẹ, olori ẹka ibaralusọrọ nileeṣẹ amunawa Ikeja, Felix Ofulue, sọ pe, eniyan kan ṣoṣo ko le da lo eto tuntun yii. Adugbo, agbegbe, awọn olokoowo ati ileeṣẹ nlanla ni eto naa wa fun."
Awọn olugbe iru adugbo bẹẹ gbọdọ ri i daju pe gbogbo wọn lo ni ẹrọ onka ina 'prepaid', ki wọn o to o le lo eto tuntun yii.
Bakan naa ni wọn gbọdọ ni ẹgbẹ ti wọn fi orukọ rẹ silẹ labẹ ofin nitori pe wọn yoo tọwọ bọ awọn iwe adehun kan pẹlu ileeṣẹ DisCos.
Eto yii naa ni awọn ileeṣẹ to ba wa ni agbegbe ti wọn ya sọtọ fun awọn olokoowo tabi ileeṣẹ nlanla yoo tẹle. Ayafi ti ileesẹ naa ba tobi gan an, to si n lo ina to to megawatts meji soke.
Eto tuntun yii jẹ ajọṣepọ laarin DisCos ati GenCos lati maa pese ina fun awọn onibàára to ba le sanwo daada. Ipese ina yii yatọ si eyi ti gbogbo orilẹede Naijiria n lo.
Lori pe boya awọn to lowo ni eto naa wa fun, Ọgbẹni Felix sọ pe ko ri bẹ ẹ. O sọ pe bi ẹnu awọn ara adugbo kan ba ṣe kò si i, ati bi o ṣe rọrun si lati fa ina de adugbo naa lati orisun ti ina naa ti wa, ni yoo sọ boya wọn le lo eto naa.













