Punch Newspapaer: Ìjọba Nàìjíríà ní kò burú tí ẹ bá pe Ààrẹ Buhari ni 'Major General'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileesẹ Aarẹ orilẹ-ede Naijiria ti fesi pe ko si nkan to buru nibẹ ti ẹnikẹni ba pe aarẹ Buhari ni Ọgagun, nitori pe o ṣiṣẹ gba oye naa ni.
Ileeṣẹ aarẹ sọ eyi lẹyin ti ileeṣẹ iwe iroyin Punch kede sita pe lati asiko yi lọ, Ọgagun dipo aarẹ alagbada ni oun yoo maa pe aarẹ Buhari, gẹgẹ bi ọna lati fi ibinu han lori iru iṣejọba to n ṣe.
Olubadamọran pataki fun Aarẹ Muhammadu Buhari lori eto iroyin ati ipolongo, Femi Adesina lo sọ loju opo Twitter pe kii ṣe nkan to buru ni ti ẹnikẹni ba pinnu lati pe aarẹ ni Ọgagun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Iwe iroyin naa fi ikede yii sita ni oju ewe akọkọ iwe iroyin rẹ, nibi to ti tọka si awọn ọrọ bi fifi ti ijọba fi Omoyele Sowore si atimọle, ati awọn ọrọ miran.
Ninu ikede ti Adesina fi sita, o sọ pe:"Iwe iroyin kan sọ pe oun yoo bẹrẹ si ni i fi orukọ ipo ọgagun ti Buhari ni gẹgẹ bi ọmọ ogun pe e.
"Ko s'ohun to buru nibẹ. Iṣẹ takun-takun ni aarẹ ṣe ko to o gba oye Ọgagun ko to o fẹhinti.
Bakan naa si ni ofin orilẹ-ede Naijiria pe ipo aarẹ alagbada to wa gẹgẹ bi Apaṣẹ Agba fun awọn ọmọ ogun.
Adesina sọ pe "pipe aarẹ ni Ọgagun jẹ ẹri pe ijọba fi aaye silẹ fun ominira awọn oniroyin.
Bakan naa, amugbalẹgbẹ pataki fun aarẹ lori eto iroyin igbalode, Bashir Ahmed naa sọ lori Twitter pe "titi lai ni oye Ọgagun yoo maa wa lara orukọ aarẹ."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ati wi pe ara ọna lati pọn aarẹ le ni orukọ naa.
Koda, o fi kun un pe orukọ naa ko yi i pada pe Muhammadu Buhari ni aarẹ Naijiria titi di ọdun 2023.














