Àjọ FRSC, NYSC, kìlọ̀ fún àwọn àgùnbánirọ̀ lórí ìrìnàjò òpin ọdún.

Oríṣun àwòrán, @officialnyscng
Ọga agba ajọ alaabo loju popo ni Naijiria, Boboye Oyeyemi ti rọ awọn agunbanirọ lati ma wọ ọkọ sọọlẹ lasiko ọdun.
Bakan naa lo kilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ awakọ eero pe wọn ko gbọdọ gbe agunbanirọ kankan mọ lati aago mẹfa irọlẹ lasiko ọdun.
Boboye fi ikilọ naa sita nibi ipade opin ọdun ti ajọ naa ṣe pẹlu awọn olori ẹgbẹ awakọ eero nilu Abuja lọjọ Iṣẹgun.
Gẹgẹ bi ajọ akoroyin jọ orilẹ-ede Naijiria ṣe sọ, Boboye sọ pe awakọ ti ọwọ ba tẹ pe o fi ọkọ rẹ gbe agunbanirọ kankan lẹyin aago mẹfa irọlẹ yoo jẹ iya to pọ.
Boboye ni igbesẹ yi n waye nitori pe aabo ẹmi awọn agunbanirọ naa jẹ ajọ FRSC l'ogun, ati paapa lati dena awọn ijamba opin ọdun jakejado orilẹ-ede Naijiria.
Bakan naa ni Oludari-agba fun ajọ isinru ilu, NYSC, Ọgagun Shuaibu Ibrahim kilọ fun awọn agunbanirọ lati ma wọ ọkọ tabi rinrinajo l'alẹ nitori ọwọn owo ọkọ lasiko ọdun Keresi ati Ọdun titun.
Ẹwẹ, Akọwe Gbogboogbo fun ẹgbẹ awọn to n gba awakọ siṣẹ ni Naijiria, Ọgbẹni Yusuf Adeniyi, sọ pe wọn yoo fi to awọn awakọ leti lati din owo skọ ku fun awsn agunbanirọ to ba n rinrinajo lasiko ọdun.











