Àwọn abiyamọ fẹ́ kí gómìnà Ondo dásí ọ̀rọ̀ ọmọ ọdún kan tó di àwátì l'Akure

Aworan iya Gold Kolawole

O ti le ni oṣu kan bayii ti ọmọ kekere jojolo kan ,Gold Kolawole, dédé di awati ni ile ijọsin kan ti a mọ si Sotitobire prayer centre, ni ilu Akure.

Gbogbo igbiyanju obi ọmọ naa lati ri lo jasi pabo ti awọn agbofinro ko si ti sọ nkankna bayi nipa ibi ti ọmọ naa wọlẹ si.

Idi eyi lo mu ki agbarijọpọ awọn obinrin kan ni ilu Akure ṣe iwọde lọjọ Iṣẹgun tii ṣe ọjọ Kẹwa oṣu Kejila ọdun 2019.

Awọn obinrin naa ni awọn fi ẹhonu han latari ai kara maasiki awọn Ọlọpa lori ọrọ naa.

Wọn benu ate lu ileeṣẹ ọlọpaa lori bi won ṣe fọwọ yẹpẹrẹ mu ọrọ naa ti ko si ẹni kan pato ti wọn fi panpe ọba mu lati bi Oṣu kan sẹyin.Jumoke Aborode to je adari àti alaga Àjọ National Council of women Society of Nigeria, tí ẹka Ondo ni o lewaju awọn obinrin naa.

Aworan awon obinrin to n fehonu han lori Gold Kolawole

Ninu ọrọ rẹ pẹlu awọn oniroyin, o sọ pe ara abiyamọ lo ta awọn ti o mu ki awọn jade pẹlu iya ọmọ naa ki awọn agbofinro bvaa le wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ yi.

Ohun to de ba iya Gold, o de ba gbogbo abiyamọ tootọ. Ẹ jọwọ ibikibi ti Kolawole Gold ba wa, ẹ bawa wa sita''

O rọ Gomina ipinlẹ Ondo ati awọn lọbalọba lati da si ọrọ ọmọọdun kan to sọnu yi.