Ondo Kidnap: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní òun ń ṣa ipá láti rí ọmọ tó sọnù náà

Awọn olujọsin nile ijọ̀sin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ìyá ọmọ náà ni àwọn lọ sí ilé ìjọsìn ní òun fi ọmọ sí ibi tí àwọn ọmọdé ń wà, ní ọmọ bá di àwátì.

Ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori bi ọmọ ọdun kan se di awati ni ipinlẹ Ondo.

Iroyin naa ni pe ile ijọsin kan ni ilu Akure ni ipinlẹ Ondo ni isẹlẹ naa ti waye.

Iya ọmọ naa, Abilekọ Modupe Kolawole, ni oun mu ọmọ oun lọ si ile ijọsin 'So Titobi Re Praising Chapel,' naa ni aarọ ọjọ isinmi, amọ ti ọmọ naa si di awati.

Kolawole ni ẹka ibi ti awọn ọmọde ma n duro si ni oun fi ọmọ oun si, amọ lasiko isere, oun lọ sibẹ, oun si ri ọmọ naa to n jẹ pọfu-pọọfu, ti oun si beere ibi ti o ti ri, amọ lara awọn olukọ wọn sọ wi pe, ile ijọsin naa lo fun wọn ni ipanu ọhun.

Awọn ọlpa to n rin lọ

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Iya ọmọ naa ni lẹyin ẹsin ni oun wa pada lọ si ibẹ lati lọ mu ọmọ oun, amọ ti wọn ko ri mọ.

Alukoro ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Femi Joseph to fi idi ọrọ naa mulẹ, ti ni awọn ti bẹrẹ igbiyanju lati ri wi pe ọmọ naa di awari.

Alukoro Ọlọpaa ni pasitọ ijọ naa lo wa fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa, lẹyin ti baba ọmọ ati awọn onijagidijagan yawọ ijọ naa, ti wọn si bẹrẹ si ni ba nkan jẹ.

Ile isẹ ọlọpaa naa fikun wi pe iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lati ri wi pe ọmọ naa di awari, ti awọn yoo si mu tọ iya ati baba rẹ lọ.