Border Closure: Ilé aṣòfin àpapọ̀ pàṣẹ fáwọn àṣọbodè láti fààyè gba èpo lẹ́nu bodè

Awọn eeyan to sile epo tori ọwọn gogo epo

Oríṣun àwòrán, @anaedoonline

Yoruba ni agba kii wa lọja, ki ori ọmọ tuntun wọ, eyi lo mu kile asofin apapọ ilẹ wa tete dasi ọwọn gogo epo pẹtirolu to n waye lawọn eti bode Naijiria.

Nibi ijoko wọn to waye loni, awsn asoju-sofin ti pasẹ fun ileesẹ asọbode ilẹ wa pe ko gbẹsẹ kuro lori ofin to fi de gbigbe eroja epo rọbi lọ si awsn ilu to wa leti bode orilẹede yii.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin ti iroyin gbalẹ kan pe awọn ilu to wa leti bode ilẹ wa lo ti n jẹrora ọwọn gogo epo pẹtirolu atatawọn eroja epo rọbi miran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n gbarata lori isẹlẹ yii, Alaga ajọ to wa fun akoso eto ibaraẹnisọrọ ni Naijiria, NCC, Umar Danbatta kede pe ofin naa ti n ni ipa ti ko dara lori awọn ọmọ Naijiria to n gbe lawọn ẹnu bode.

Eti bode Naijiria

Oríṣun àwòrán, @anaedoonline

Lero ti Asofin Sada Soli lati ipinlẹ Katsina, o ni asẹ ti ileesẹ asọbode pa ọhun kọja agbara ti ofin gbe le wọn lọwọ, to si kesi ile alti pasẹ fun ileesẹ assbode pe ko wọgile ofin to se naa.

Awọn asofin yoku to da si ọrọ naa ni o yẹ ki wọn maa fi oju aanu sisẹ wọn, ti wọn si sapejuwe ofin to de epo gbigbe lọ sẹnu bode bii ofin onikumọ.

Awọn asobode leti bode Naijiria

Oríṣun àwòrán, @anaedoonline

A gbọ pe aye nira fun wọn nibẹ to bẹẹ ti wọn fi n ra lita epo pẹtirolu kan ni ẹgbẹta naira.

Koda, awọn ileesẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ naa si ti n pariwo pe idakureku eto ibaraẹnisọrọ yoo wa lawọn agbegbe ọhun, ti ko ba si eroja epo ni arọwọto wsn lawọn agbegbe naa.

Jálà epo bẹntiróò di N600 nítorí ibodè títìpa

Ọwọn gogo epo bẹntiro ti gbode kan bayii lawọn awujọ to sun mọ ibode orilẹede Naijiria sawọn orilẹede miiran nitori ibode Naijiria to ṣi wa ni titi pa.

Ọwọn gogo epo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Niṣe lawọn olugbe awọn ilu to wa leti bọda n ke lẹyin ti jala epo kan di ẹgbẹta naira dipo naira marundinlaadọjọ, eleyi waye nitori bi ijọpa apapọ ṣe fi ofin de gbigbe epo lọ si awọn agbegbe ti ko ju ogun kilomita lọ si ibode Naijiria sawọn orilẹede mii.

Awọn ilu to n foju wina ọwọn gogo epo yii wa ni ipinlẹ Ogun, Eko, Adamawa, Katsina ati ipinlẹ Sokoto.

Àkọlé fídíò, Wo Bullet, ọmọ ọdun mẹjọ tó fẹ́ lùwẹ̀ wọ Olympics

Ọjọbọ ọsẹ to lọ ni ọga ile iṣẹ aṣọbode, Hameed Ali kede igbesẹ ijọba to fi ofin de gbigbe epo lọ si awọn agbegbe ti ko ju ogun kilomita lọ si ibode Naijiria si awọn orilẹede mii.

Ihunbo, Ilase, ajegunle, Idiroko ati Agosasa nijọba ibilẹ Ipokia lawọn ilu ti ọwọn gogo epo ti gbode kan nipinlẹ Ogun.

Bakan naa la gbọ pe ọwọn gogo epo mu awọn awakọ to lawọn ile epo ni Seme ''border'' nipinlẹ Eko lọjọ Aje.

Ohun ti a gbọ ni pe ile epo meji pere lo n ta epo ninu awọn ile epo to ju meje lọ nibode Seme.

Iwadii tun fihan pe ọpọ ile epo ni ijọba ti ti pa lagbegbe Ipokia nitori ko ju ogun kilomita lọ si orilẹede Benin Republic lẹyin ti ijọba ti ibode Naijiria.

Awọn ọkọ agbepo to le ẹgbẹrun un kan to fẹ gbepo kọja ni ibode Naijiria sawọn orilẹede to wa layika ni a gbọ pe awọn ile iṣẹ aṣọbode ti gbẹsẹ le ti wọn ko si jẹ ki wọn kọja.