Ogoni 9 execution anniversary: Ta ni Ken Saro-Wiwa tí ìjọba ológun sekúpa?

Ken Saro-Wiwa àtí àwọn mẹ́jọ míràn tó jẹ́ adarí àwọn Ogoni ní ìjọba ológun yẹgi fún ní ọdún 1995.

Oríṣun àwòrán, TIM LAMBONI/GREENPEACE

Àkọlé àwòrán, Ken Saro-Wiwa àtí àwọn mẹ́jọ míràn tó jẹ́ adarí àwọn Ogoni ní ìjọba ológun yẹgi fún ní ọdún 1995.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjo Kẹwa, Osu Kọkanla, ọdun 1995 ni ijọba ologun Naijiria se oun to bi ọpọlọpọ eniyan ninu lagbaye lẹyin ti wọn pa awọn ajafẹtọ mẹsan lati ilẹ Ogoni.

Ọgagun Sani Abacha lo ra Ken Saro-Wiwa ati awọn mẹjọ miran lọ si ẹwọn ni Ọjọ Kokandinlogbo, oṣu Kẹwaa, ọdun 1995 lori ẹsun pe o kopa ninu isekupani awọn oloye mẹrin lati ilẹ Ogoni.

Lẹyin ọdun mẹrinlelogun ti wọn sekupa Ken Saro-Wiwa, awọn ọmọ Naijiria ti n sọrọ nipa rẹ, ti wọn si n beere fun idajọ otitọ lori isekupani naa.

Ta ni Ken Saro-Wiwa tí ìjọba ológun sekúpa?

Kenule Beeson 'Ken' Saro-Wiwa jẹ onkowe, adari ere ori amohunmaworan, ajijangbara fun agbegbe lati ilẹ Ogoni, lorilẹ-ede Naijiria.

Ken Saro-Wiwa wa lati ẹya Ogoni to pẹlu awọn ẹya to kere julo lorilẹ-ede Naijiria, amọ ti wọn ni epo rọbi lati ọdun 1950, ti o si n se ipalara fun awọn eniyan ati ohun ọgbin wọn.

Ẹgbẹ ajijangbara ti Ken Saro-Wiwa naa bu ẹnu atẹ lu ijọba Sani Abacha fun ipa ti wọn nko pẹlu awọn ile isẹ iwa epo lati ilẹ okeere ti wọn ko fi ofin de wọn.

Awọn miran to jẹ ajijangbara bii Ken Saro Wiwa ti Orukọ ẹgbẹ wọn n jẹ Ogoni Nine ti ijọba da ẹjọ iku fun ni Saturday Dobee, Nordu Eawo, Daniel Gbooko, Paul Levera, Felix Nuate, Baribor Bera, Barinem Kiobel, ati John Kpuine.

Àkọlé fídíò, Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Kilode ti wọn fi pa Ken Saro Wiwa?

Ken Saro-Wiwa n sọrọ tako ijọba ologun ti Ọgagun Abacha ati ile isẹ iwako epo lati ilẹ okeere, Anglo-Dutch petroleum company, Royal/Dutch/Shell fun bi wọn be se n ṣe akoba fun agbegbe naa ti wọn ti n wa epo rọbi.

Ọjọ kọkanlelogun, ọdun 1994 ni awọn iku ajijagbara fun idagbasoke ilẹ Ogoni, MOSOP pa oloye mẹrin to wa lẹyin ijọba.

Bi o tilẹ jẹ wi pe Ken Saro-Wiwa ko mọ nkankan nipa rẹ, ijọba da ẹbi le e lori wi pe o mọ nipa isekupani naa.

Ijọba ologun ti i mọle fun ọdun kan, ki ijọba to gbe e lọ si ile ẹjọ ti wọn si dajọ iku fun wọn nipa yiyẹgi fun awọn mẹsan an naa.

Kini awọn ọmọ Naijirria n sọ nipa Ken Saro-Wiwa?

Lẹyin ọdun mẹrindinlogun, ọpọlọpọ awọn eniyan lo ṣi n bu ẹnu atẹ lu idajo to ni wi pe ki wọn yẹgi fun wọn.

Lori opo ikansiraẹni Twitter ni onkowe kan ti sọ itan Ken Saro-Wiwa, to si pe fun idajọ otitọ lori isekupani naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Àkọlé fídíò, Òwò ẹrú ọmọdé àti obìnrin lórí ayélujára
Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Ọmọ Ken Saro-Wiwa bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba lati bẹrẹ iwapo ni agbegbe naa, ti o si ni wi pe awọn eniyan gbodo dide lati ja fun ẹtọ agbegbe naa.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Àkọlé fídíò, Ìbànújẹ́ ló pọ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà tórí a ti lo Pásítọ̀, Wòlìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n