Falana: Mo ní ẹ́rì pé Ààrẹ Buhari fẹ́ lọ fún sáà kẹta

Aarẹ Buhari ati agbẹjọro agba, Falana

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán, Falana sọ fun BBC pe, oun ni ẹri pe Buhari n gbero ati ṣe saa kẹta

Ajafẹtọ ati agbẹjọro agba, Femi Falana ti sọ pe Aarẹ Muhammadu Buhari ni erongba lati dije sipo aarẹ fun igba kẹta.

Falana lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC.

Ṣaaju ni Aarẹ Buhari ti sọ loṣu kẹwa ọdun 2019 pe, oun ko ni ipinu lati du ipo Aarẹ lẹyin to ba pari saa keji to n ṣe lọwọ.

Garba Shehu, to jẹ oluranlọwọ pataki lori ọrọ iroyin ati igbohunsafẹfẹ fun Aarẹ Buhari ni, erongba Buhari ni lati pari saa keji to n ṣe lọwọ, ko si fẹyinti.

Ṣugbọn Falana sọ fun BBC pe, oun ni ẹri pe Buhari n gbero ati ṣe saa kẹta.

Lẹnu ọdun diẹ si asiko yii ni awọn Aarẹ ilẹ Africa kan ti n gbiyanju lati ṣejọba fun saa kẹta.

Loṣu kẹwa ọdun 2019 ni awọn ọmọ orilẹ-ede Guinea gunle ifẹhonuhan lodi si aba Aarẹ Alpha Conde lati dije sipo Aarẹ orilẹ-ede ọhun fun igba kẹta.

Àkọlé fídíò, Ìbànújẹ́ ló pọ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà tórí a ti lo Pásítọ̀, Wòlìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n