Omoyele Sowore: Femi Falana ní òfin ilé-ẹjọ́ ilẹ̀ òkèrè nìkan ni ìjọba lè pamọ́

Omoyele Sowore

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omoyele Sowore

Yoruba ni ti ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ kii tan leekanna.

Ajafẹtọ, Deji Adeyanju lo sọ pe ko si awawi kankan mọ fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lati ma fi Omoyele Sowore silẹ lọjọ Iṣẹgun.

Deji to jẹ ọkan lara awọn ajijagbara atawọn agbẹjọro ti wọn lọ si ile iṣẹ ajọ DSS lọjọ Satide, ṣalaye pe bi wọn ba tun kọ lati fi Sowore silẹ lọjọ Iṣẹgun, awọn ko ni dẹkun lilọ si ọfiisi wọn.

Deji ni ''o jẹ iyalẹnu pe ajọ DSS sọ pe ko si ẹni to yoo gba Sowore mi ko jẹ kawọn fi silẹ lahamọ lọsẹ to kọja.''

Deji Adeyanju fikun ọrọ rẹ pe oun nigbagbọ pe ajọ DSS yoo fi Sowore silẹ lahamọ lọjọ Iṣẹgun.

O ni bi ijọba ti n ṣe Sowore jẹ ibanujẹ fun awọn ọmọ Naijiria, nitori ọrọ naa ko ye ẹnikan ohun to jẹ ki ijọba kọ lati paṣẹ ileẹjọ mọ.

Sowore ati Olawale Bakare lajọ DSS ti mọle lẹyin ti Sowore gbimọ lati ṣagbatẹru iwọde #RevolutionNow lati fẹhonu han bi nnkan ṣe ri lorilẹede Naijiria.

Àṣẹ ilé-ẹjọ́ ilẹ̀ òkèèrè nìkan ni ìjọba lè pamọ́ ṣùgbọ́n tàpá sí ti Nàìjíríà lórí Sowore

Gbajugbaja agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan, Femi Falana ti woye pe o rọrun fun ijọba apapọ lati bọwọ fun aṣẹ ti ileẹjọ ilẹ okere ba fun un.

Amọ, Falana ni o rọrun fun ijọba bakan naa lati tapa si aṣẹ ile ẹjọ lorilẹede Naijiria.

Muhammadu Buhari ati Femi Falana

Oríṣun àwòrán, Twitter/Presidency

Ọrọ ajafẹtọ, Omoyele Sowore ati Olawale Bakare ti ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS kọ lati fi silẹ lahamọ lẹyin ti ile ẹjọ paṣẹ pe ki ajọ naa fun wọn lominira lo fa sababi ọrọ yii.

Falana fi ọrọ ile iṣẹ P & ID ṣapejuwe ninu eyi ti ijọba ti tete sanwo miliọnu to le marun un laadọrun un naira lẹyin ti ile ẹjọ ilẹ Gẹeṣi kan paṣẹ pe ki ijọba Naijiria sanwo naa laarin ọjọ mẹrinla ṣapejuwe.

Agbẹjọro Falana ni kiakia ni ijọba sanwo naa gẹgẹ bi ile ẹjọ giga Her Majesty's High Court niluu London ti pa a laṣẹ.

Lọsẹ to lọ nile ẹjọ paṣẹ idasilẹ Sowore ati Bakare lahamọ ajọ DSS ṣugbọn wọn kọ lati fi wọn silẹ, ohun ti wọn sọ ni pe awọn ko ri ẹni ti yoo gba awọn mejeeji nigba tawọn fẹ fun wọn lominira.

Amọ, Falana fesi sọrọ naa pe wakati mẹrin lawọn agbẹjọro fi duro ni ọfiisi ajọ DSS ṣugbọn wọn ko fi wọn silẹ.

Bakan naa lawọn agbẹjọro, awọn ajijagbara atawọn alatilẹyin Sowore tun lọ si ile iṣẹ ajọ DSS lọjọ Abamẹta, ṣugbọn gbogbo akitiyan wọn lati gba Sowore ati Bakare, pabo lo ja si.

Àkọlé fídíò, Ìbànújẹ́ ló pọ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà tórí a ti lo Pásítọ̀, Wòlìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n