Gowon Estate: Ọkọ̀ aképo laná l'ẹ́yìn tó fara kan òpó iná mọ̀nàmọ́ná l'Èkó

Oríṣun àwòrán, @essenceloaded
Ajọ to n risi iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA ti sọ pe, epo bẹntiro ti awọn kan ji ninu ọpa epo lo wa ninu ọkọ akepo to gbana nipinlẹ naa laarọ oni.
Wọn ni, lẹyin ti ọkọ akepo ọhun fara kan opo ina mọnamọna ni ina ọhun ṣeyọ.
Epo ọhun ni awọn eeyan kan ji ninu ọpa epo lẹyin illeewe Honeyland, to wa ni Abesan, ni agbegbe Ipaja, nipinlẹ naa.
Ajọ LASEMA ni ẹmi ẹnikẹni ko ba iṣẹlẹ naa lọ, bẹẹ si ni ko si ẹni to ṣeṣe.
Bẹẹ naa ni ajọ ọhun ni ohun ti bẹrẹ iwaadi kikun lori iṣẹlẹ ọhun.
Ki lo ti ṣẹlẹ séyin?
Lagos Fire: Ọkọ̀ aképo dàwó iná ṣẹ́ ní Gowon Estate

Oríṣun àwòrán, @Stanley
Iroyin to n tẹ wa lọwọ lowurọ kutu oni ni wi pe ọkọ akepo kan dawo ni agbegbe Gowon Estate, Ipaja Road, Alimosho to si ti fa ina to burẹkẹ.
Ohun taa gbọ ni wi pe ọkọ naa kun bamu pẹlu epo ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn lita.
Nigba ti BBC Yoruba kan si ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni ipinlẹ Eko, alukoro ajọ LASEMA, Nosar Okunbor fi aridaju iṣẹlẹ naa han.
Nosar jẹ ko di mimọ pe ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ ina yii lawọn ti gbe awọn oṣiṣẹ pajawiri dide ti wọn si ti wa lọna ibẹ bayii.

Oríṣun àwòrán, @Stanley
O fi kun un wi pe ko sohun kankan ti ẹnikẹni tii ṣe si ina to n jo nibẹ ṣugbọn ni kete ti awọn ba ti de ibẹ, iṣẹ yoo bẹrẹ lati dawọ rẹ duro.
A ko tii ni aridaju kankan boya ẹnikẹni fara pa tabi pe o la ẹmi lọ lasiko ti a ko iroyin yii jọ.













