Tunde Bakare: Àwọn ọ̀rọ̀ gbànkọgbì tó ti sọ

Òní ni ọjọ́ ìbi gbàjúgbajà olùsọ́àgùntan Tunde Bakare ti ìjọ Latter Rain Assembly, o pé ẹni ọdun márùnlélọ́gọ́ta ní òni, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn lo ti ń ṣe baba kẹ́ẹ pẹ́, to fi mọ ààrẹ Muhammadu Buhari.
Ààrẹ Buhari nínú àtẹjáde to búwọlù ṣàlàyé pe ìdùnù òun ló jẹ́ pe Bakara sì jẹ́ onígbàgbọ titi di asikò yìí àti olóòtọ́ si ìpè ọlọrún, fún ìgbìyànjú rẹ̀ láti maa nàka ọ̀nà ìjọba ọrún sí àwọn ènìyàn, ó n kọ wọn bi wọ́n o ṣe maa gbe bẹ ati bíbá ọlọrun gbé.
BBC Yorùbá wá sẹ àkójọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ gbànkọgbì tí o ti tẹnu Tunde Bakare jáde látẹyin wá.
Àwọ́n míràn tilẹ̀ ní ìgbàgbọ́ pé gbogbo ọ̀rọ̀ Tunde Bakare ló máa ń dá awuyewuye sílẹ̀ láàrin àwùjọ.
Ọmọ Nàíjíríà, ẹ gbáradì fún àgbékalẹ̀ Nàíjíríà tuntun-Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Bakare facebook
Olusọ̀ aguntan agba fun ijọ Latter rain Assembly, Pasitọ Tunde Bakare ti ke si awọn ọmọ Naijiria to fẹ agbekalẹ orilẹede Naijiria tuntun lati dara pọ mọ oun fun ijagudu fun agbekalẹ orilẹede Naijria tuntun.
Pasitọ agba fun ijọ Latter Rain naa ni laarin awọn ọdọ to fẹ se aarẹ lorilẹede yii, ko si eyi to ni ọgbọn agba to Oby Ezekwesili, tii se oludije ACPN.
Bakare ni ọrọ oun ko nii se pẹlu atilẹyin fun oludije kankan, amọ ohun ti Naijiria nilo ni ikọ oloselu ti yoo mu atunto ba ilẹ yii, ti ko ni jẹ alajẹbanu, ti yoo sisẹ pẹlu ẹka alasẹ ati asofin lati mu isọkan ba ilẹ yii.
Inú máa ń bí mí láti gbọ́ pé ẹ̀yà kan kò leè daríi Nàíjíríà -Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Bakare
Bakare ní kí Nàìjíríà tó le tẹ̀síwájú, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo ẹyà parapọ láti yan ẹni tó tọ, ki wọ́n yee funra si pé ẹyà kan lo le ṣe ìjọba tàbi ẹyà kan kọ́.
Bakare ní; "àsìkò ti to láti jọ jumọ jòkó pọ láti jíròrò, tóri èyí ni mo se sọ pé ènìyàn bi ààrẹ Muhammadu Buhari ní láti jígìrì kúrò lóri à ń fari apá kan dá ọ̀kan si pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà."
Bakare láìpẹ yìí ti kédé pe oun yóò di ààrẹ lẹ́yìn ààrẹ Muhammadu Buhari lọdun 2023, ṣàlàye pé ó jẹ ǹkan to maa ń ru òun nínú nígbà ti àwọn ẹ̀yà kan kò ṣe fí fọkan tan ti wọ́n ba jáde.
Irọ́ ni, mi ò sọ pé mọ fẹ di Ààrẹ ní 2023- Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Bakare
Pasitọ ati Olori Ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare ti ni irọ patapata ni iroyin ẹlẹjẹ wi pe oun lo maa gba ipo aarẹ ni ọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari.
Bakare sọ eyi lasiko to n ba awọn ara ijọ rẹ ni agbegbe Ọgba ni ipinlẹ Eko, sọrọ ni Ọjọ Isinmi.
O sọ wi pe fidio ti oun fi sita lati bi ọdun diẹ sẹyin ni awọn eniyan miran ṣẹṣẹ n gbe jade lati fi ba oun lorukọ jẹ.
Aago Nàìjíríà ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ - Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Bakare/Twitter
Gbajugbaja Agbẹjọro ati Pasito Ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare ni awọn adari orilẹ-ede Naijiria n se oselu pẹlu ẹmi awọn araalu ni Naijiria.
Bakare sọ eyi lasiko to n ba ẹbi ati ara Abileko Funke Olakunrin to jẹ ọmọ baba pa Reuben Fasọnranti, ti wọn ni awọn agbebọn pa ni opopona Ọrẹ si Benin.
Ninu ọrọ rẹ, o ni ijọba n ṣe aito lori bi wọn ṣe n koju ipaniyan ati ijinigbe nitori awọn eleto aabo maa n ṣa gbogbo agbara wọn lati ri i wi pe ki wọn má gba ẹmi awọn olowo lawujọ, ṣugbọn ẹmi awọn araalu ko jọ wọn loju.
Olóṣèlú tó nílé kiri, tó tún fẹ́ jẹ ààrẹ Nàíjíríà, ẹ kò ní lọ láì pọ ohun tí ẹ jí - Tunde Bakare

Oríṣun àwòrán, Bakarefacebook
Faabada! Ẹ ko nii lọ lai pọ ohun ti ẹ ji! Pasitọ ijọ Latter Rain Assembly, Tunde Bakare lo sọrọ yii nigba to n waasu lọjọ Aiku.
Pasitọ Bakare to ṣe agbatẹru ẹgbẹ Save Nigeria Group sọrọ lowelowe ninu iwaasu ọjọ Aiku ninu ijọ rẹ.
Bakare woye pe, ''aimọkan lo mu awọn eeyan maa ki ole to ji nnkan wọn ni mẹsan an mẹwaa, wọn ni oninure ni ati wi pe o lawọ.''
Pasitọ ijọ Latter Rain ni idi niyii ti oju titi fi kun fun koto ati gegele nitori wọn ti ko owo to yẹ ki wọn fi ṣatunṣe ọna jẹ, lati igba ti orilẹede Naijiria ti pada si ijọba awarawa.













