Aàrẹ, igbákejì aàrẹ àti aàrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kọ̀wé fipò sílẹ̀ lọ́jọ́ kan náà

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ Evo Morales to n tukọ orilẹ-ede Bolivia ti kọwe fipo silẹ.
Eyi waye lẹyin opọlọpọ ọsẹ ti awọn ọmọ orilẹ-ede yii ti n ṣe iwọde o tó gẹ́ẹ lẹyin eto idibo wọn to waye loṣu to kọja.
Odun mẹrinla ree ti Aarẹ Morales ti n tukọ ijọba orilẹ-ede naa.
O ṣe ikede ikọwefiposilẹ yii lẹyin ti awọn ọmọ ogun ilẹ ọhun ni awọn ko ni ṣatilẹyin fun un mọ.
Olori awọn ọmọ ogun ilẹ Bolivia sọ fun aarẹ naa pe asiko ti to ko fipo silẹ lẹyin iwọde ti awọn ara ilu fi n ṣe lodi si esi idibo oṣu to kọja to tun kede aarẹ Evo ni aarẹ lẹẹkan sii.
Opọlọpọ awọn onwoye lo ni kudiẹ-kudiẹ wa ninu idibo naa ṣugbọn Aarẹ Morales ni sabaabi ni oun ṣe koungẹ iditẹ naa.
Oun ti aarẹ naa sọ ni pe iditẹgbajọba lo ṣẹlẹ ati pe nitori wọn kọlu ile oun ni idi ti oun ṣe kọwe fipo silẹ bayii lati daabo bo ẹbi ati ara oun pẹlu awọn ọrẹ oun ninu iṣelu ni.
O ni oun mọ pe awọn jaguda lo lọ jo ile oun lẹyin idibo to kede oun gẹgẹ bii aarẹ lẹẹkan sii.
Ninu ọrọ Aarẹ Evo Morales lori amohunmaworan lo ti parọwa fawọn oluwọde pe ki wọn dẹkun kikọlu ara wọn.
O ni ki wọn fopin si didana sun ile ati dukia awọn eniyan ti wọn si n kọlu ara wọn.
Alvaro Garcia Linera to jẹ igbakeji aarẹ Morales ati Adriana Salvatierra to jẹ olori ile igbimọ aṣofin orilẹ-ede ọhun naa ti kọwe fipo wọn silẹ pẹlu aarẹ.
Kat Watson to jẹ akọroyin BBC to wa nibẹ ṣalaye pe ọpọ eniyan lo n fidunnu wọn han ni La Paz pe opin de ba iṣejọba aarẹ Evo.
Niṣe ni wọn fọnka si igboro ti wọn yọ ayọ pe wọn bọ lọwọ iṣejọba rẹ ti wọn n tan imọlẹ ọjọ tuntun ati igba ọtun ni Bolivia.
Koko ti ọpọ ninu wọn n sọ nipe aarẹ Morales ni pe kii ṣe adari to ṣamulo idagbasoke iṣejọba awa ara wa daadaa.
Nigba ti awọn mii n sọ pe ko fi tawọn ara ilu ṣe rara ni gbogbo o din diẹ lọdun mẹrinla to fi tukọ orilẹ-ede naa.
Nibo ni orilẹ-ede Bolivia ti bẹ̀rẹ̀ ko to di bayii?
Lalẹ ọjọ idibo ni wahala ti kọkọ bẹrẹ bi wọn ti ṣe n ka esi idibo ni eyi ti awọn eniyan ti kọkọ n pariwo pè madaru pọ ninu esi ti wọn n ka.
O kere tan awọn mẹta ni wọn ti jalaisi nigba ti ọrọ naa di nla mọ awọn agbofinro lọwọ.
Abajade esi idibo naa fihan pe aarẹ Morales ni ida mẹwaa ninu ọgọrun un idibo naa ju akẹgbẹ rẹ to sun mo ọ lọ.
Lọjọ Aiku ni Organisation of American Ststes to jẹ onwoye lasiko idibo naa ni awọn ni ẹri to fihan pe madaru wa ninu idibo naa ti ko le jẹ ki wọn bu ontẹ lu esi idibo naa.
Ogagun agba Williams Kaliman to jẹ adari awọn ọmọ ogun ilẹ naa gba aarẹ ni imọran lati kọwe fipo rẹ silẹ.
Ta ni Evo Morales?
Lọdun 2006 ni Evo Morales kọkọ gba ipo aarẹ ni orilẹ-ede Bolivia.
Loṣu kẹwaa ọdun yii lo tun dije lẹẹkẹrin lati dije dupo aarẹ ilẹ Bolivia lẹẹkan sii.

Oríṣun àwòrán, AFP
Eyi waye lẹyin ti wọn wọgile ipinnu ileẹjọ ilana ofin ilẹ Bolivia lati ṣatunṣe si odiwọn iye ọdun ti aarẹ orilẹ-ede naa le lo.
Lọdun 2016 ni ọpọ eeyan dibo lodi si gbendeke iye ọdun ti aarẹ le lo ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu aarẹ Morales gbe ọrọ naa pada sile ẹjọ ilana ofin to si fun un ni idajọ.


















