Eid Maulud: Ẹ̀yin mùsùlùmí, ẹ tẹ̀lé ẹ̀kọ́ Ànọ́bì, ẹ gbógun ti ìgbésùnmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad
Aarẹ Muhammadu Buhari ti rọ awọn musulumi lati maa tẹle awọn apẹrẹ ati ilana Anọbi Muhammad bi wọn ṣe n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.
Aarẹ Buhari sọrọ yii ninu iṣẹ ikini ku ọdun ọjọ ibi Anọbi to fi ranṣẹ sawọn ọmọ Naijiria bi wọn ṣe n ṣọdun.
Buhari rọ awọn obi musulumi lati ma jẹ kawọn alakatakiti ẹsin tan ọmọ wọn jẹ darapọ mọ ẹgbẹ igbesunmọmi.
- Mo bọ́ lọ́wọ́ igbó mímu ṣùgbọ́n ìnira ilé Aafa Ọlọrẹ ti pọ̀jù- ọ̀dọ́ kan
- Àṣẹ ilé-ẹjọ́ ilẹ̀ òkèrè nìkan ni ìjọba lè pamọ́ nígbà tó tàpá sí ti Nàìjíríà
- Àgbẹdọ̀! Má kọ̀wé fipò sílẹ̀, àwọn àgbààgbà Yorùbá sọ fún Osinbajo
- 'Ohun ẹ rí, ẹ wí, ẹ ò lè fipá mú wa fáwọn darandaran nílẹ̀ ní ìpínlè wa'
- Orílẹ̀-èdè Naijíríà pàdánú onímọ tí kò lẹ́gbẹ́- Ayo Adebanjo
- Toyin Abraham ní 'gbogbo wa loníbárà', Ijebu ta sí Odunlade
Aarẹ Buhari ni eleyi lewu pupọ nitori yoo ba wọn laye jẹ, yoo si tun ba ọjọ iwaju wọn jẹ.
Aarẹ tun rọ awọn musulunmi lati maa fifẹ han si ọmọlakeji wọn, ati pe ki wọn tun maa lepa alaafia ati isọkan orilẹede Naijiria.
Buhari sọ pe ''pipa alaiṣẹ, jiji awọn akẹkọọ gbe ati ṣise igbeyawo tipatipa fun wọn tako apẹrẹ rere ati ẹkọ Anọbi Muhammad.''
Aarẹ Buhari ni ''igbesunmọmi dabi aarun jẹjẹrẹ, ti eeyan ba kuna lati dẹkun rẹ nibẹrẹ pẹpẹ, yoo di nla.''
Buhari ni iyi ati ọla to ga ju lọ tawọn musulumi le fun Anọbi ni titẹle awọn apẹrẹ to fi lelẹ.













