Coptic Christianity bẹ̀rẹ̀ l'órílẹ̀èdè Egypt

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ẹlẹsin Coptic jẹ irufẹ ẹya kristẹni kan to gbalẹ ni iha Ila Oorun ilẹ Afrika, paapa ni orilẹede Egypt.
Orukọ wọn 'Coptic' tumọ si 'ọmọ Egipti', awọn kritiẹni to wa ni orilẹede Egypt si n pe ara wọn ni ẹlẹsin kristiẹni Coptic.
Ilu Alexandria ni wọn ti bẹrẹ lasiko awọn aposteli. Wọn si maa n fi idi rẹ mulẹ pe John Mark to kọ iwe ihinrere Maaku ninu Bibeli ni oludasilẹ wọn, to si tun jẹ Biṣọọbu akọkọ.
Itan sọ pe irinajo ihinrere lo gbe John Mark lọ si orilẹede Egypt, ti awọn to ti n ṣe ẹsin yii si tẹwọ gbaa.
Labẹ ijọba Romu, ẹya Giriki, Juu ati Egipti lo korajọ pọ n jẹ ẹlẹsin kristẹni Coptic.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lonii, iwadii sọ pe awọn to jẹ ẹlẹsin Coptic lagbaye wa laarin miliọnu mẹwa si ọgọta miliọnu.
Wọn si wa ni awọn orilẹede bii Egypt, Sudan, Libya, Amẹrika, Canada, Australia, Italy, United Arab Emirates, Jordan, ati Kenya.








