Emir Borno lé àwọn aṣẹ́wó léré, ó ní kò sáyè fún wọn nípìnlẹ̀ òun

Emir Bornu, Kyari Ibn Umar El-Kanemi

Oríṣun àwòrán, @UNICEF_Nigeria

Àkọlé àwòrán, Emir Borno lé àwọn aṣẹ́wó léré, ó ní kò sáyè fúnwọn nípìnlẹ̀ òun

Kyari Ibn Umar El-Kanemi, to jẹ Emir Borno ti paṣẹ pe ki awọn aṣẹwo yago fun agbegbe ti oun ti n ṣejọba nipinlẹ ọhun.

O ni eredi aṣẹ naa ni ọna lati fopin si iwa ibajẹ nipinlẹ naa.

Ninu ọrọ ti akọwe Emir ọhun, Abba Shehu-Umar fi lede lo ti paṣe naa lọjọ ọdun ayajọ ọjọ ibi Anọbi, ti o waye ni oni ọjọ kọkanla, oṣu kọkanla, ọdun 2019.

Emir naa fi aidunnu rẹ han lataari bi awọn aṣẹwo ṣe n di pupọ si i ni ipinlẹ ọhun.

O ni oun ko ni faaye gba iwa ibajẹ ti awọn aṣẹwo n hu ni Maiduguri.

Àkọlé fídíò, Òwò ẹrú ọmọdé àti obìnrin lórí ayélujára

El-Kanemi ni "Awọn obinrin wọnyi n ṣiṣẹ aṣẹwo ita gbangba, wọn n mu oogun oloro ati awọn iwa ibajẹ miran ni gbagede."

Emir tẹsiwaju pe, ijọba ti gbe igbimọ kan kalẹ to ti bẹrẹ iṣẹ lọna lati fopin si iwa ibajẹ nipinlẹ ọhun, idi eyi ni awọn ile itura kan fi di wiwo.

El-Kanemi pari ọrọ rẹ pe, ẹnikẹni ti wọn ba gbamu nidi iwa ibajẹ yoo foju bale ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Ìbànújẹ́ ló pọ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà tórí a ti lo Pásítọ̀, Wòlìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n