Ìjọba ológun ti yọ Bolivia Morales, Mugabe, Al-Bashir lẹ́yìn ìfẹ̀họ́nú hàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Orilẹ-ede Bolivia, Evo Morales ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ bi Aarẹ, lẹyin ti Adari Ikọ ọmọ ogun orilẹ-ede naa kọwe si i lati fipọ silẹ ki alaafia le jọba ni orilẹede naa Aàrẹ, igbákejì aàrẹ àti aàrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin kọ̀wé fipò sílẹ̀ lọ́jọ́ kan náà.
Ikọ ọmọ ogun Ile orilẹ-ede naa gbe igbesẹ ọhun lẹyin ti awọn eniyan ibẹ ṣe ifehonuhan tako idibo sipo rẹ lẹẹkan sii.
O ti wa n di lemọlemọ bayii ki ikọ ọmọ ogun ma a le Aarẹ kuro ni ipo lọna kan tabi omiran lẹyin ti awọn ara ilu ba ṣe ifẹhọnu han .
- "Ọkọ̀ aképo náà forí sọ òpó iná ló fi laná ní Gowon Estate l'Èkó"
- Makinde vs Adelabu: Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ní yóò yanjú ọ́rọ́ ìdìbò Gómìnà Oyo
- 9ice: Tí ẹ̀mí bá sọ fún ẹ pé kò sí ǹkankan nínú orin mọ́, kò ní wù ẹ kọ
- Ẹ̀yin mùsùlùmí, ẹ yé jẹ́ káwọn alákatakítí ẹ̀sìn b'ọmọ yín láyé jẹ́ - Buhari
Wo awọn aarẹ orilẹ-ede mii ti awọn ara ilu kọ̀ ti wọn si ti fipo sile:
Yatọ si Morales, awọn adari bi Robert Mugabe ti orilẹ-ede Zimbabwe, Omar-al-Bashir ti orile-ede Sudan wa lara awọn aarẹ to ti kowe fipo silẹ lẹyin ti ikọ ọmọ ogun wọn pada lẹyin wọn.
Evo Morales;
O le ni dun meẹtala ti Morales ti lo nipo ko to di pe awọn eniyan Bolivia fariga ti wọn si fẹhọnuhan kaakiri orilẹ-ede naa.
Lẹyin ti ẹmi ati ọpọ dukia sọnu sinu ifẹhonuhan yii ni ikọ ọmọ ogun ilẹ naa kẹyin sii lẹyin to tun bori ninu idibo ti wọn ṣẹṣẹ pari loṣu to kọja.
Morales ni oun kọwe fipo silẹ ki oun le doola ẹmi awọn eniyan oun lẹyin ti awọn to n fẹhọnu han jo ile wọn, ti adari ikọ ọmọogun ile naa, Ọgagun Williams Kaliman naa parọwa sii lati kowe fipo silẹ ki alaafia le jọba.

Robert Mugabe:
Ni Oṣu Kọkanla, ọdun 2017 ni Mugabe to ti wa lori oye fun ọdun mẹtadinlogoji, lẹyin ti orilẹ-ede naa ti gba ominira ni ọdun 1980, kowe fi ipo silẹ.
Lẹyin ti awọn ologun gba ijọba. amọ kii ṣe lẹsẹkẹsẹ ni Mugabe kuro.
O kọkọ yari, amọ nigba ti ifẹhọnu naa pọsi, ni o wa kowe fipo silẹ.
Omar al-Bashir:
Ọjọ Kokanla, Osu Kẹrin, ọdun yii ni Aarẹ Ilẹ Sudan,Omar al- Bashir fi ipo silẹ lẹyin ti awọn eniyan se ifẹhọnu han, ti ikọ ọmọ ogun naa dasi, ti wọn si le Aarẹ naa kuro lori oye.
Koda, o ni igba ti Poopu, olori ijọ aguda lagbaye nilati bẹ awọn adari ilẹ Sudan pe, o to gẹ!
Adari orilẹ-ede naa n jẹjọ ẹsun iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu.

Yahaya Jammeh:
Awọn ikọ ọmọ ogun lati Iwọ- oorun Ilẹ Afirika lọ parapọ se ikọlu si orilẹ-ede Senegal lati le Aarẹ Jammeh kuro lori oye, lẹyin ti o ti wa nibẹ ni ọdun mẹrindinlọgbọn.
O kuna ninu idibo gbogboogbo ni awọn eniyan fi bere ifẹhọnuhan, amọ Aarẹ naa kọ lati fi ipo silẹ.
Aarẹ orilẹ-ede Guninea ati Mauritania ni wọn pa jiroro pọ, ko to di pe o gba lati fi ipo silẹ.
Orile-ede Equitorial Guinea ni Aarẹ naa ti n ṣe atipo lọwọ, nigba ti Aarẹ ilẹ naa, Adama Barrow to jawe olubori ninu idibo naa si bo si ipo.
Idi Amin
Ọdun 1971 ni Adari ikọ ọmọ ogun Orilẹ-ede Uganda gba isejọba orileede naa.
Ọdun mẹjọ ni aarẹ naa fi wa ni ori oye, amọ ikọ ọmọ ogun ilẹ Tanzania ati awọn ọmọ ogun to tako Amin lo le e kuro ni isejọba lọdun 1979.
O ti tiraka lati pada si ipo, amọ gbogbo igbiyanju rẹ lo ja si pabo.
Ọdun 1978 ni o sa kuro lorilẹ-ede naa lo si Libya, ko to di wi pe o lọ si Saudi Arabia ti o kusi ni ọdun 2003.
- Toyin Abraham ní 'gbogbo wa loníbárà', Ijebu ta sí Odunlade
- Ààye wà fún àgunbanirọ láti wọ sòkòtò labúlabú- Ọ̀gá àgbà
- Àṣẹ àwọn gómìnà là ń retí, àwa ti ṣetán láti dáàbò bo ilè Yorùbá- Gani Adams
- Orílẹ̀-èdè Naijíríà pàdánú onímọ tí kò lẹ́gbẹ́- Ayo Adebanjo
- 'Ohun ẹ rí, ẹ wí, ẹ ò lè fipá mú wa fáwọn darandaran nílẹ̀ ní ìpínlè wa'
















