Oyo Governorship Appeal: Ìdájọ́ Ilé ẹjọ kò sọ pàtó ẹní tó jáwé olúborí láàrín Makinde àti Adelabu

Oríṣun àwòrán, Google
Bi ọrọ ba ru eeyan loju labẹ ofin, ṣebi ile ẹjọ laa gba lọ?
Ti ile ẹjọ kan ko ba wa fidi ọrọ mulẹ ni pato nipa idajọ ohun ta gbe lọ si iwaju rẹ, kini o yẹ ka ṣe?
Bẹẹ lọrọ ri pẹlu ohun to ṣẹlẹ nile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Ibadan to n gbẹjọ laarin Gomina Seyi Makinde ati akẹgbẹ rẹ ti wọn jọ du ipo Gomina, Adebayo Adelabu ti ẹgbẹ oṣelu APC.
Koko ọrọ to jade nipa idajọ ti adajọ ẹlẹni mẹta ile ẹjọ naa fi lelẹ ni pe awọn fọwọ rọ idajọ ile ẹjọ igbimọ to n gbẹjọ idibo sẹgbẹ kan ṣugbọn ile ẹjọ ko sọ oju abẹ niko boya Makinde tabi Adelabu lo jawe olubori.
Ni ti Adelabu, niṣe ni o n sọ pe ki ile ẹjọ wọgile esi idibo to gbe Makinde wọle ki o si kede oun gẹgẹ bi Gomina.
Amọ bayi ti ile ẹjọ naa ko ti sọ boya oun ni Gomina tabi Makinde ṣi ni, ohun to kan fawọn mejeeji ni ki wọn gba ile ẹjọ to ga julọ lorile-ede Naijiria lọ lati yananan ọrọ lori idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.
Loju opo Twitter, ohun ti ile ẹjọ yi sọ ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa tawọn eeyan si n gbiyanju lati tu ohun ti ile ẹjọ sọ bo ṣe ye wọn mọ
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1

End of X post, 2

End of X post, 3
Koda awọn kan ti n fi ohùn ranṣẹ si aarẹ Buhari ati ẹgbẹ APC pe ki won ma ṣe dasi ọrọ naa ti wọn o ba fẹ kan abuku.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Bi ọrọ naa ti ṣe wa bayi,ohun to daju ni pe ile ẹjọ ko sọ ẹni to jawe olubori bẹẹ si ni ko kede pe wọn yoo tun ibo miran di.
Bi a ba ni ka tẹle ọrọ tawọn agbẹjọrọ oludije mejeeji yi sọ bayi, aye ṣi wa nilẹ fawọn lati kọri si ile ẹjọ to ga julọ lati sọ bi iṣu ṣe ku, bọbẹ si ti ṣe pa.
Koko kan ṣoṣo to hande lori ọrọ ẹjọ yii ni pe Ile ẹjọ giga lo maa yanjuẹ.