Seyi Makinde: Èmi kò yẹsẹ̀ kúrò nínú àdéhùn àjùmọ̀ṣe láti pín ipò

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti sẹ lori ẹsun kan ti oludije fun ipo gomina to kọja, ninu ẹgbẹ oselu ADC, Sẹnetọ Olufẹmi Lanlẹyin, fi kan gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde pe, o n se aisododo lori adehun ti wọn fi ẹnu ko le lori nipa agbekalẹ ijọba alajumọse.

Olugbaninimọran fun gomina Seyi Makinde lori aato ati eto oselu, Asofin Babatunde Oduyọye lo kede eyi ninu atẹjade kan to fi sita, eyi to fi n fesi lori igbesẹ Lanlẹyin to ni oun yọwọ-yọsẹ kuro ninu adehun agbekalẹ ijọba alajumọse ti wọn fẹnu ko le lori saaju idibo gomina to kọja.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n kede ipinnu rẹ naa ni owurọ ọjọ Isẹgun, Lanlẹyin salaye pe, oun gbe igbesẹ naa nitori pe o ti n foju han bayi pe gomina Makinde ti n yẹsẹ lori iwe adehun ti wọn fẹnu ko le lori.

Lanlẹyin tun fikun pe, oun gẹgẹ bii ẹnikan ko ni nkan se pẹlu adehun ajumọse naa mọ, to ba si wu ẹgbẹ oselu oun, tii se ẹgbẹ ADC, o lee tẹsiwaju pẹlu adehun naa.

Nigba to n fesi, Oduyọye ni irọ to jinna sootọ ni ọrọ ti Lanlẹyin sọ yii, koda, o ni afomọ ni ọrọ naa, ko lẹsẹ nlẹ, ti ko si ba ohun to n waye lọwọlọwọ bayii mu, nitori Makinde ti sa ipa rẹ lati ko gbogbo ẹgbẹ oselu ti wọn jọ se adehun ajumọse mọra.

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Atẹjade naa fikun pe, wọn ti gbe ilana bi wọn yoo se pin ipo kalẹ lori adehun ajumọse naa, ti eto si ti de oju ọgbagade lati ri daju pe wọn se amusẹ adehun naa, ti gbogbo ẹgbẹ oselu to kan si ti fọwọsi ilana naa.

Àkọlé fídíò, Kunle Afolayan: èmi kò fẹ́ fi ogún sílẹ̀ fún ọmọ mi

Oduyọye wa kesi Sẹnetọ Lanlẹyin pe, ko mase wọ orukọ gomina Seyi Makinde sinu ijakulẹ to n koju ninu ẹgbẹ oselu ADC, nitori adehun ajumọse naa ko wa fun ifẹ ẹnikẹni, bikose fun ifẹ awọn olugbe ipinlẹ Ọyọ.